Ṣé lóòtọ́ ni àwọn ọmọ ogun Naijiria àti Niger gba ogúnlọ́gọ̀ ìbọn lọ́wọ́ àwọn jàndùkú?

army seize AK 47 rifles meant for bandits

Oríṣun àwòrán, @5thSu

Ẹka ileeṣẹ iroyin BBC to maa n tu aṣiri awọn iroyin ofege ti sọ pe irọ ni iroyin kan to sọ pe awọn ọmọ ogun Naijiria ati Niger ṣawari ogunlọgọ ibọn Ak-47 ni Ariwa.

Ileeṣẹ iroyin kan to jẹ ti ede Hausa, Zinariya lo kọkọ gbe iroyin naa jade loju opo Facebook rẹ.

Iroyin naa ni “Ikọ ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ati Niger ti gbẹsẹle awọn ibọn kan ni iha Ariwa.”

Ni kete ti ileeṣẹ iroyin naa gbe iroyin yii sita ni ọpọ eeyan ti bẹrẹ si n pin iroyin ẹlẹjẹ naa kaakiri ori ayelujara, paapaa lori ikanni atẹjiṣẹ WhatsApp.

Eyii to mu ki ọpọ eeyan maa gboriyin fun ileeṣẹ ọmọ Ogun Naijiria fun akitiyan wọn, bẹẹ naa ni iroyin ọhun tun da ipaya sọkan awọn araalu mii.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ijọba Naiiiria ti sọ pe agbesumọmi lawọn agbebọn to n da alaafia ilu ru.

Nibo ni awọn ibọn naa ti wa?

Ẹwẹ, iwadii ileeṣẹ iroyin BBC ti fi han pe awọn ibọn ti awọn eeyan n pin kiri yii kii ṣe lati Naijiria tabi orilẹ-ede Niger.

Ṣaaju akoko yii, lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2022 yii ni ileeṣẹ iroyin kan, Olympia ti kọkọ fi aworan awọn ibọn naa han.

Gẹgẹ bii ohun ti Olympia sọ, awọn ọmọ ogun Russia lo gbẹsẹle awọn ibọn naa ninu ile nla kan to jẹ ti awọn ọmọ ogun Ukraine, niluu Zaporizhia.

Orukọ awọn ibọn naa si ni wọn npe ni Kalashnikov, tako Ak-47 ti iroyin n sọ ṣaaju.