Bí ìjọba bá tẹ̀síwájú láti máa yan ọba, ìlú kò lè tòrò láíláí - Àwọn oníṣẹ̀se

Ki i ṣe iroyin tuntun mọ pe kaakiri ilẹ Yoruba ni wọn ti n ṣayẹyẹ ayajọ ọdun iṣẹṣe, eyi ti wọn fi n gbe aṣa ati ẹsin ibilẹ Yoruba larugẹ.
Bẹẹ si ree, ọkan pataki lara awọn ẹsin ni ẹsin iṣẹṣe jẹ, koda, to tun jẹ ẹsin abalaye fun iran Yoruba kaakiri agbaye, ko to di pe awọn ẹsin miran bii Kristẹni ati Musulumi wọle de.
Lonii, gbogbo awọn ẹlẹsin ibilẹ lọkan-o-jọkan ni wọn ti jade l’ọpọ yanturu lati ṣayẹyẹ ayajọ ọdun Iṣẹṣe, ti awọn ẹlẹsin naa n’ipinlẹ Ogun, paapaa niluu Abẹokuta to jẹ olu-ilu ipinlẹ naa ko gbẹyin.
Nibẹ ni wọn ti fi oriṣiriṣi ohun aṣa ati iṣẹṣe han sita gbangba fun gbogbo agbaye ri, lara wọn ni Egungun, Gẹlẹdẹ, Igunnuko ati bẹẹbẹẹlọ.
N’igba to n sọrọ lorukọ awọn agbaagba ẹsin ibilẹ naa n’ipinlẹ Ogun, Ojubọna ilu Ẹgba, Oloye Ifakayọde Akanbi jẹ ko di mimọ pe kii ṣe ahẹsọ, bi ko ṣe ohun to ṣoju-ṣaara wi pe ijọba ẹlẹyamẹya lo n ṣakoso orileede yii, to fi mọ awọn ipinlẹ kaakiri.
Oloye Ifakayọde sọ pe awọn oloṣelu ni iṣoro ti a ni lorileede Naijiria lo n fa pupọ awọn iṣoro to n dojukọ araalu.
Nigba to n sọrọ nibi Omi Adura ti wọn tun n bọ lati fi ṣadura, eyi ti wọn n pe ni Oke Abọla, to wa lagbegbe Kugba niluu Abẹokuta, ọkunrin naa tẹsiwaju pe o ṣenilaanu wi pe ninu ẹsin mẹta ti ijọba gba wi pe o wa ni orileede yii, meji ninu wọn lo lẹtọọ labẹ ofin.
“Ijọba ko ri ẹsin ibilẹ rara ninu gbogbo ẹka iṣejọba. Gbogbo eeyan lorileede yii ni wọn n dibo lati yan olori, ṣugbọn ẹsin meji ni wọn fi n bura fun wọn, sibẹ, wọn n sọ pe ẹsin mẹta la ni lorileede yii. Ki lo de ti wọn fi yọ wa kuro ninu eto ibura f’awọn adari wa? Eyi ti n waye lati ọjọ to ti pẹ sẹyin, ti a si n fẹ ki ijọba fi ẹsin ibilẹ sinu eto ibura f’awọn adari wa.
“Gbogbo ẹka eto iṣejọba to wa lorileede yii lo jẹ pe gbogbo ẹlẹsin patapata lo n dibo gbe wọn sibẹ. Ni gbogbo ọdun ni awọn gomina maa n ya ọjọ sọtọ lati ba awọn ẹlẹsin meji to ku yọ, ki lo de ti wọn yọ wa s’ọtọ? A fẹ ki wọn ya ọjọ kan ṣoṣo sọtọ lati maa ba wa ṣajọyọ pẹlu, ki wọn si gbe eyi yẹwo.”
Latigba iṣẹmbaye l’awọn afọbajẹ ti n yan ọba
Bakan naa, o tẹsiwaju pe “Ninu eto ifọbajẹ, Ifa ati Ọpẹlẹ ni wọn fi n yan ọba s’ipo, ki i ṣe nitori ifẹkufẹ ara-ẹni, ki alaafia le toro laarin ilu, ṣugbọn lasiko ti a wa yii, ijọba lo n yan awọn ọba, ti wọn si n gbe ade le wọn lori, eyi to le fa oriburuku saarin ilu.
“Ṣe lo yẹ ki awọn ọba jẹ agbẹnusọ fun wa, ṣugbọn lasiko yii, ijọba ti jẹ gaba le wọn lori lati maa paṣẹ fun wọn, ti awọn olori wa si f’ọwọ lẹran lati maa woran, lai gbe igbesẹ lee lori.
“Aṣa wa kii ṣe aṣa mọ, Ifa ati Ọpẹlẹ la fi n yan ọba, kii ṣe nipa ifẹkufẹ ẹnikankan. Gbigbe ade le ọba lori yẹ ko jẹ iṣẹ awọn afọbajẹ, kii ṣe nipa ijọba. Eto isinku awọn ọba gbọdọ pada si bo ṣe yẹ ko wa, kii ṣe ni ilana ẹsin. A fẹ k’awọn ọba alaye wa dide kuro loju orun wọn, ki wọn si mọ ohun to tọ si wọn.”
A n bẹ ijọba lati fun wa ni ọlude
Nigba to n kadi ọrọ rẹ nilẹ, Ojubọna ilu Ẹgba, Oloye Ifakayọde Akanbi rawọ ẹbẹ s’ijọba ipinlẹ Ogun labẹ Gomina Dapọ Abiọdun lati dide iranwọ fun ọlude ti wọn n beere fun lati ọdun diẹ sẹyin.
O ni awọn ẹlẹsin Kristẹni ati Musulumi gbadun ọlude wọn, awọn naa si n fẹ ohun to jẹ ti wọn , nitori pe awọn fẹ ki gbogbo agbaye mọ pe awọn wa.
Bẹẹ lo dupẹ lọwọ ijọba ipinlẹ Ọṣun ati Eko fun ti ọlude ti wọn bu ọwọ lu f’awọn oniṣẹṣe, to si n rọ awọn ipinlẹ yooku lati tẹle awọn ipinlẹ meji naa gẹgẹ bi awokọṣe.
Ki lo ti sẹlẹ sẹyin?
Ọdún Ìsẹ̀ṣẹ gbérasọ ní Osun, Oyo, Ondo, Ekiti àtàwọn ilẹ̀ míì káàkiri àgbàyé

Ọdún Iṣẹṣe ti ọdún yii jẹ ti ẹlẹẹkẹrindilogun ti awọn Ẹlẹsin Ibilẹ, Traditional Religion Worshipers Association, ipinlẹ Osun ti bẹrẹ.
Ọdún Iṣẹṣe jọ ọjọ àkọkọ tí àwọn ẹlẹṣin ibilẹ ni gbogbo àgbáyé ma nṣe ọdún àfihàn gbogbo àwọn òòsà wọn ti wọn sì ma n bọ ilẹ fún ọdún tuntun lati mọ ohun ti ifá sọ.
Ogunjọ, oṣù Kẹjọ, ọdọdun ni gbogbo awọn oniṣẹ maa n ṣe ọdún "Iṣẹṣe" náà ni gbogbo àgbáyé.

Odun Iṣẹṣe ti ọdún yii ni ipinle Osun je ẹlẹẹkẹrindilogun iru rẹ pẹlu Àkòrí "Esin Abalaye Adúláwọ̀ àti Ipaniyan ṣowò, Nje Ajosepo wa bi?"
Awọn ẹlẹṣin ibilẹ ni igbagbọ pe Ogun ní o ṣaju àwọn òòṣà ti o kú wà ile ayé.
Idi niyii ti wọn fi n ṣe odun naa ni oṣu oògùn lati fi ṣe afihan awọn òòsà ti o kú ní ọjọ Ọdun iṣẹṣe.
Awọn ẹlẹṣin ibilẹ ni wọn ní ìgbàgbọ láti má ke pe Ọlọrun ní ìlànà ibilẹ ti wọn kìí sì faramọ lati ma ko awọn papọ mo awon Oníṣègùn.
Eyii lo fa lọpọ igab ti wọn fi maa n sọ pe iyatọ wa laarin awọn ẹlẹsin atrawọn Onisegun.
Yatọ si ipinlẹ osun ti ọdu yii ti n waye lonii, ọdun Isese tun n lọ lọwọ lawọn ilẹ Yoruba kaakiri Naijiria, bii ipinlẹ Oyo, Ondo, Ekiti, ati bẹẹ bẹẹ lọ.












