Arsenal da àlejò ọ̀ràn fún Bournemouth, 3:0 ni wọ́n fi dá bàntẹ́ ìyà fún wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ti fagba han ẹgbẹ agbabọọlu Bournemouth ninu ifẹsẹwọnsẹ Premier League to waye lọjọ Abamẹta.
Ami ayo mẹta ọtọtọ ni Arsenal fi da bantẹ fun Bournemouth eyii to mu ki orin ọpẹ gba ẹnu awọn ololufẹ ikọ naa.
Igba ti ifẹsẹwọnsẹ ọhun wọ iṣẹju marun un ni Martin Ødegaard kọkọ ṣi oju awọn Bournemouth wo.
Nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa gbẹnule iṣẹju mọkanla gerege lo tun dan ẹnu awọn Bournemouth wo lẹẹkansi, ti bọọlu naa si ri ẹyin awọn naa.
Ẹwẹ, nigba ti yoo fi di iṣẹju marunlelaadọta ti ifẹwọnsẹ ọhun bẹrẹ ni William Saliba sọ pe aisinibẹ ni ai ba wọn da si, eyii to mu ko ṣọ ami ayo Arsenal do aro mẹta ti ko gbọdọ da omi ọbẹ nu.
Wayi, bo tilẹ jẹ awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Bournemouth naa gbiyanju lati ṣe bii ọkunrin, amọ o jọ bi ẹni pe diẹ ọmọkunrin wọn ko to.
Tottenham vs Wolves
Ẹwẹ, ninu ifẹsẹwọnsẹ to kọkọ waye, Tottenham ja fitafita ki wọn to ri goolu kan fi ṣagba Wolves.
Nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kẹrinlelọgọta ni Harry Kane sọ ami kan sọsọ wọle.
Pẹlu goolu naa, Harry Kane ti lewaju bayii gẹgẹbii agbabọọlu to gba goolu sinu awọn julọ ninu ẹgbẹ agbabọọlu kan naa lati igba ti Premier league ilẹ Gẹẹsi ti bẹrẹ ni nnkan bii ọgbọn ọdun sẹyin.
Goolu marundinlaadọwa, (185 goals) ni Harry kane ti gba sinu awọn bayii.












