Eeyan marun un wa ni gbaga ọlọpaa, ṣugbọn iwadii ṣi n lọ lọwọ - Ileeṣẹ ọlọpaa

Aworan Gomina Gboyega Oyetọla, iyawo rẹ Kafayat ati Sẹnetọ Ademọla Adeleke

Oríṣun àwòrán, Taofeek adejare/ ademola adelek/twitter

Iroyin kan bọ si igboro aye laṣalẹ ọjọ Ẹti, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹjọ ọdun 2022 pe awọn eeyan kan ti wọn furasi gẹgẹ bi janduku kọlu awọn ọkọ to kọwọrin pẹlu iyawo gomina ipinlẹ Ọṣun, Alaaja Kafayat Oyetọla.

Iṣẹlẹ naa, gẹgẹ bi a ṣe gbọ waye lagbegbe Owo Ẹdẹ ni ipinlẹ Ọṣun.

Ta ló kọlu ìyàwó gómìnà, tó fi di gbódónróṣọ láàrín ìjọba àti ẹgbẹ́ òṣèlú PDP l'Osun

Ikọlu yii n waye lẹyin nnkan bii oṣu kan ti idibo si ipo gomina ni ipinlẹ Ọṣun waye ninu eyi ti oludije fun ẹgbẹ oṣelu PDP, Sẹnetọ Ademọla Adeleke ti jawe olubori.

Ọmọ bibi ilu Ẹdẹ ni Sẹnetọ Adeleke, eyi to n mu ki ọpọ woye pe o ṣeeṣe ko jẹ awọn janduku to n gbe lẹyin rẹ lo ṣiṣẹ ọhun.

Bawo ni iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ?

Oniruru alaye lo ti n waye latẹnu awọn eeyan kan to pe awọn wa nibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.

Amọṣa, ohun kan to n jẹyọ ninu alaye gbogbo awọn to sọrọ pe iṣẹlẹ ikọlu naa ṣoju awọn ni pe awọn ọkọ akọwọrin pẹlu iyawo gomina ipinlẹ Ọṣun, Alaaja Kafayat Oyetọla n bọ lati irinajo kan ni

Eyi to gbe wa gba ilu Owode Ẹdẹ. Ọkọ akẹrun kan taku si oju popo lagbegbe ọja owode Ẹdẹ.

Ọkọ to di oju ọna yii ni dẹrẹba rẹ n tu ṣe to si mu ki awọn ọkọ to kọwọrin pẹlu aya gomina naa o duro. Lasiko yii ni awọn nnkankan ṣẹlẹ ninu eyi ti ikọlu yii fi waye.

Iryoin sọ pe lara awọn oṣiṣẹ alaabo to kọwọrin pẹlu iyawo gomina ipinlẹ Ọṣun ọhun fara ṣeṣe ti wọn si ba lara awọn ọkọ wọn jẹ.

Awọn janduku ẹgbẹ oṣelu PDP lo kọlu ọkọ iyawo gomina ni Ẹdẹ -Agbẹnusọ fun iyawo gomina ipinlẹ Ọṣun

Aworan afọku gilasi ọkọ

Oríṣun àwòrán, other

Nigba ti BBC News Yoruba kan si agbẹnusọ fun iyawo gomina ipinlẹ Ọṣun, Arabinrin Oluwatunmiṣe Iluyọmade lori iṣẹlẹ naa, o ṣalaye pe oun ti fi atẹjade iroyin kan sita fun awọn akọroyin lati lo.

Ninu atẹjade naa lo ti sọ pe awọn janduku oṣelu ti wọn n ṣiṣẹ fun ẹgbẹ oṣelu PDP lo wa nidi ikọlu naa.

O fi kun un pe “ikọlu naa n waye lẹyin ọsẹ meji ti iwe orukọ kan jade sori ayelujara ninu eyi ti wọn kọ orukọ awọn ti awọn ẹgbẹ alatako PDP ti foju si lara lati kọlu.”

“Wahala naa bẹrẹ nigba ti awọn ẹṣọ alaabo to wa pẹlu iyawo gomina gbiyanju lati ṣeto ki irinna ọkọ o gun rege lagbegbe Owode Ẹdẹ.

Laimọ pe awọn janduku ẹgbẹ oṣelu PDP kan ti fi ara pamọ sibẹ, ti wọn si bẹrẹ si ni ju okuta atawọn nnkan miran lu awọn ọkọ to kọwọrin pẹlu aya gomina ninu eyi ti wọn ti ba awọn ọkọ jẹ ti wọn si tun ṣe awọn ẹṣọ alaabo kan leṣe.”

Lilu ti awọn ẹṣọ alaabo iyawo gomina ọṣun lu dẹrẹba ọkọ kan lo mu karaalu kọ oju oro si wọn ni Owode Ẹdẹ - PDP

Aworan ademola adeleke, gomina ti wọn ṣẹṣẹ yan

Oríṣun àwòrán, adeleke/twitter

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ ṣun ti fesi si ẹsun ti iyawo gomina ipinlẹ Ọṣun atawọn ololufẹ APC nipinlẹ naa fi nkan an pe oun lo ran awọn janduku kọlu ikọ akọ̀wọrin pẹlu iyawo gomina Kafayat Oyetọla.

Ninu atẹjade ti wọn fi sita, ẹgbẹ oṣelu PDP ni nṣe ni ọfiisi iyawo gomina ipinlẹ Ọṣun fẹ fi ewe rabata bo imi iwa ibajẹ ati aṣemaṣe ti awọn ẹṣọ alaabo to kọwọ rin pẹlu rẹ hu lagbegbe ọja Owode ẹdẹ ni ipinlẹ Ọṣun.

Atẹjade naa ti adari ipolongo ni PDP, Ọladele Bamiji fi sita ṣalaye pe lootọ ni ikọlu waye

ṣugbọn awọn araalu ni wọn fariga fun iwa ailaanu ti awọn ẹṣọ alaabo to wa pẹlu Alaaja Kafayat Oyetọla hu si dẹrẹba ọkọ akẹru kan to taku si oju opopona lagbegbe ọja nilu Owode Ẹdẹ.

“...dẹrẹba ọkọ naa n gbiyanju lati tun ọkọ naa ṣe ko ṣiṣẹ. Igba yii gan ni iyawo gomina ipinlẹ Ọṣun atawọn to baa kọwọrin rode de si agbegbe naa,

dipo ki wọn si ṣeranwọ pẹlu amojuto sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ to waye nitori ọkọ to bajẹ si aarin popo naa, n ṣe ni wọn ya bo dẹrẹba ọkọ naa ti wọn si lu u bi ẹni lu bara.

“eyi gan lo mu ki awọn eeyan to wa lagbegbe ọja naa o fariga ti wọn fi ju okuta atawọn nnkan miran lu wọn”

O fi kun un pe lasiko yii awọn eeyan ti inu n bi naa ko tilẹ mọ eeyan to wa ninu ọkọ naa.

Eeyan marun un wa ni gbaga ọlọpaa, ṣugbọn iwadii ṣi n lọ lọwọ - Ileeṣẹ ọlọpaa

Aworan ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, other

Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ọlọpaa fi sita, ọwọ ti tẹ eeyan marun lori ikọlu naa.

Bakan naa lo ṣalaye pe lootọ ni dẹrẹba ọkọ akẹru to wa laarin awuyewuye ikọlu naa, to pe orukọ rẹ ni Ọmọlọla Ọpẹyẹmi lati ilu Ijẹbu Ode fi ara gbọgbẹ ni iwaju ori rẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ peoṣiṣẹ alaabo DSS kan ṣoṣo lo fi ara ṣeṣe lasiko iṣẹlẹ naa ati pe iwadii ti n lọ lori ikọlu hun.