Ṣé lóòótọ́ ni eégún Ìpọ̀nríkú gé orí eégún Olóòlù sí Gẹ́gẹ́ ní Ibadan?

Eégún Olóòlù àtàwọn tó ń tẹ̀le
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Àṣà àti ìṣẹ̀ṣe jẹ́ ohun tó pàtàkì ní ilẹ̀ Yorùbá, tí àwọn àgbààgbà àti ọmọdé kìí fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú rárá.

Ọ̀kan pàtàkì sì ni eégún gbígbé jẹ́ nínú àṣà àti ìṣẹ̀ṣe ilẹ̀ Yorùbá nitori ọpọ anfaani to wa ninu rẹ.

Àwọn eégún kìí ṣàdédé jade nílẹ̀ Yorùbá, wọ́n ní ìgbà àti àkókò tí wọ́n máa ń jáde láàárín ọdún.

Lọ́pọ̀ ìgbà, lásìkò ayẹyẹ tàbí ọdún kan ni eégún máa ń jáde.

Àwọn eégún wà tó jẹ́ pé wọn kìí jáde ní ọdọọdún àmọ́ tó jẹ́ pé lẹ́yìn ọdún méjì tàbí ọdún mẹ́ta ni wọ́n máa ń jáde.

Oríṣiríṣi eégún ló wà, bí a ṣe ní eégún aláré, eégún onídán, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn eégún alárìnjó àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ wà.

Eégún kìí ṣe ohun tí èèyàn kan lè ṣàdédé gbé, ó ní àwọn ìdílé tó máa ń gbé eégún nílẹ̀ Yorùbá, tó sì máa ń tọ ìran láti ìrandíran.

Kódà, bí èèyàn kan yóò bá gbé egúngún tàbí tí ìdílé kan yóò gbá mú kí egúngún rẹ̀ jáde, ó ní ọ̀pọ̀ ètùtù tí wọn yóò ṣe èyí tó sọ bí egúngún ti ṣe pàtàkì tó.

Àwọn eégún wà ní ìpele ìpele, a ní àwọn ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ́, bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn eégún ńlá wà tó jẹ́ pé wọn kìí ṣàdédé jáde.

Lásìkò tí eégún bá ń jáde pàápàá tó bá jẹ́ àwọn eégún ńlá, onírúurú àwọn ayẹyẹ ló máa ń wáyé láti fi ṣàmì rẹ̀ bíi idán pípa, ijó jíjó, orin kíkọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ọ̀pọ̀ àwọn eégún yìí ló máa ń fẹ́ fi han ara wọn pé àwọn làgbà àti pé àwọn mọ orúkọ tí ewé àti egbò ń jẹ́ ju ara àwọn lọ.

Kò sí àníàní wí pé ilẹ̀ Yorùbá ní àwọn egúngún tó lágbára gidi gan tí orípa wọn kò sì le parẹ́ láéláé.

Lára àwọn àgbà eégún tó gbájumọ̀ nílẹ̀ Yorùbá ni eégún Olólù àti Ìpọ̀nríkú ní ìlú Ibadan

Eégún Olóòlù àti eégún Ìpọ̀nríkú jẹ́ àwọn eégún ńlá ní ìlú Ibadan tó gbajúmọ̀ fún agbára tí wọ́n ní àtàwọn àrà tí wọ́n máa ń pa tí wan bá jáde.

Eégún Olóòlù àtàwọn tó ń tẹ̀le

Kí ló fa aáwọ̀ láàárín Ìpọ̀nríkú àti eégún Olóòlù lọ́dún 1928?

Gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ nípa ìtàn ní ìlẹ̀ Ibadan, tó tún jẹ́ Maye Olúbàdán tí ilẹ̀ Ibadan, Olóyè Lekan Alabi sọ fún BBC News Yorùbá eégún Olóòlù ló pe Ìpọ̀nríkú níjà lọ́dún kan lọ́hùn-ún, eyiun ọdún 1928 pé tí Ìpọ̀nríkú bá tó gbangba sùn lọ́yẹ́ kó jáde sí òun láti wá fi àgbà han òun.

“Olóòlù ìgbà náà ló wá sí ìta ilé baba Ìpọ̀nríkú, tó sì ń pariwo fún àwọn ọmọ ilé àti obìnrin ilé pé, kí wọ́n sọ fún Ìpọ̀nríkú pé tí wọ́n bá bíi da, kó yọjú sí òun.

“Ó ní ó sọ fún Ìpọ̀nríkú pé òun fẹ́ fi hàn-án pé òun kìí ṣe ẹgbẹ́ rẹ̀ àti pé òun jùlọ.

“Ẹni tó ń gbé Ìpọ̀nríkú nígbà náà wá sọ fún Olóòlù pé, kó wá pàdé òun ní Gẹ́gẹ́, pé ibẹ̀ ni àwọn ti máa fi àgbà han ara àwọn.”

Ó ṣàlàyé pé nígbà tí àwọn méjéèjì pàdé ní Gẹ́gẹ́ níbẹ̀ ni wọ́n ti fìjà pẹ́ẹ́ta láti fàgbà han ara wọn.

Ó ní bí àwọn méjéèjì ṣe ń dán ara wọn wò ni Ìpọ̀nríkú ló agbára àfọ̀ṣẹ tó ní láti fi pàṣẹ fún Olólù láti dúró sí ojú kan títí tí òun fi máa yíde ká dé.

Eégún Olóòlù àtàwọn tó ń tẹ̀le

Ṣé lóòótọ́ ni Ìpọ̀nríkú gé orí Olóòlù?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Àwọn kan máa sọ pé nígbà tí Ìpọ̀nríkú àti Olóòlù pàdé ní Gẹ́gẹ́, níṣe ni Ìpọ̀nríkú gé orí rẹ̀ lọ.

Kódà wọ́n tún máa ń fi kun pé lẹ́yìn tó gé orí rẹ̀, ó tún gba ẹ̀kú lọ́rùn rẹ̀ tó sì ko lọ.

Àmọ́ Olóyè Lekan Alabi sọ àfọ̀mọ̀ rẹ̀ pé, lòdì sí ìtàn tí àwọn kan máa ń sọ pé Ìpọ̀nríkú gé orí Olólù sí Gẹ́gẹ́, ó ní Ìpọ̀nríkú kò gé orí Olóòlù, ó kàn fi oògùn àti agbára àfọ̀ṣẹ so ó mọ́lẹ̀ sí ibí odò Gẹ́gẹ́ di ìrọ̀lẹ́ tó yíde de.

Ó ní ó fi àfọ̀ṣẹ rẹ̀ pa iye Olóòlù rẹ̀, tó sì fi oògùn rẹ̀ dè é mọ́lẹ̀ sí odò Gẹ́gẹ́.

Ó sọ pé nígbà tó fi máa di ìrọ́lẹ́ ọjọ́ náà òkìkí ti tàn káàkiri gbogbo ìlú Ibadan pé Ìpọ̀nríkú so Olólù mọ́lẹ̀ tí gbogbo wọn sì ń bẹ Ìpọ̀nríkú láti tu sílẹ̀

“Olúbàdàn ìgbà náà àtàwọn olóyè ránṣẹ́ sí mọ́gàjí Ìpọ̀nríkú láti foríji Olóòlù pé kó tu sílẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti kọjá ààyè rẹ̀ fún bó ṣe wá ta á láyà.

“Ìpọ̀nríkú wá dáríjì í Olóòlù, tó sì tu sílẹ̀ láti máa lọ sílé rẹ̀.”

Bákan náà ni olóyè Lekan Alabi tún sọ pé orin tí àwọn èèyàn máa ń kọ nípa ìtàn náà tí wọ́n ti máa ń sọ pé Ìpọ̀nríkú gé orí Olóòlù ní Gẹ́gẹ́ kìí ṣe bó ṣe wáyé ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ nìyẹn.Ó ní bí orin náà ṣe lọ gangan ni:

  • Ìpọ̀nríkú de Olóòlù mọ́ Gẹ́gẹ́
  • Ó de Olóòlù
  • Ìpọ̀nríkú de Olóòlù mọ́ Gẹ́gẹ́
  • Ó de Olóòlù

Ta ni Eégún Ìpọ̀nríkú?

Olóyé Lekan Alabi, tó tún jẹ́ ọmọ bíbí agboolé Ilé Ẹ̀kẹrin Àjẹ́ǹgbẹ̀ tó ni eégún Ìpọ̀nríkú ní pé eégún Ìpọ̀nríkú jẹ́ eégún tó lágbára gan nílẹ̀ Ibadan.

Ó ní láti ogun tí àwọn babańlá rẹ̀ lọ jà ní ìlú Ekiti ni wọ́n ti gbé eégún náà wọ Ibadan.

Ó ní ọdún mẹ́ta mẹ́ta ni ìpọ̀nríkú máa ń jáde lò máa ń jáde nítorí eégún tó lágbára gan ni.

Ó sọ pé tí Ìpọ̀nríkú bá jáde, wọ́n gbọ́dọ̀ máa da omi si lórí nítorí ẹ̀kú rẹ̀ kò gbọdọ̀ gbẹ gẹ́gẹ́ bí àṣà wọn, ó gbọ́dọ̀ máa ri.

“Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù, ní aago márùn-ún ni Ìpọ̀nríkú máa ń jáde tó sì máa ń lọ káàkiri gbogbo ilé láti lọ ṣàdúrá fún àwọn ará ilé, kí mọ̀gájì àtàwọn olórí ilé.

“Lẹ́yìn náà ló máa lọ síbi odò Gẹ́gẹ́ láti lọ rúbọ̀ kó tó máa yíde káàkiri ilé àwọn olóyè ilẹ̀ Ibadan kó tó padà sílé ní aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́”

Lòdì sí ìròyìn pé ìjọba ti fòfin de eégún Ìpọ̀nríkú ní Ibadan, Olóyè Lekan Alabi ní kò sí ìgbà kankan tí wọ́n fi òfin de eégún Ìpọ̀nríkú.

Ó sọ pé àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ọdún eégún ní Ibadan ni àti pé eégún Ìpọ̀nríkú jáde lọ́dún yìí.

Ta ni Eégún Olóòlù?

Òdú ni egúngún Oloolu fún àwọn ọmọ bíbí àti olùgbé ìlú Ibadan kódà àwọn ènìyàn tó wà ní ìlú mìíràn mọ̀ nípa eégún Oloolu.

Ní kété tí ènìyàn bá ti dárúkọ eégún Oloolu ní Ibadan ni kálukú ti ma máa forí gbárí, tí wọ́n máa sá àsálà fún ẹ̀mí ara wọn nítorí ẹ̀rù àti agbára tó wà lára rẹ̀.

Àwọn obìnrin kìí ti ẹ̀ sọsẹ̀ rárá nígbà tí wọ́n bá ti gbọ́hùn wí pé eégún Oloolu fẹ́ jáde.

Èèwọ̀ ni fún obìnrin láti ṣíjú wo eégún Oloolu nítorí egungun agbárí obìnrin tí eégún náà máa ń gbé sórí.

Ìgbàgbọ́ sì wà wí pé obìnrin kóbìnrin tó bá ṣíjú wo eégún Oloolu kò ní rí nǹkan oṣù rẹ̀ mọ́ títí tó ma fi jáde láyé.

Kódà ìgbàgbọ́ tún wà wí pé obìnrin bẹ́ẹ̀ le pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lọ́jọ́ àìpé.

Onírúurú àwọn ìgbàgbọ́ ló rọ̀ mọ́ eégún Oloolu lára rẹ̀ náà tún ni wí pé ẹnikẹ́ni tó bá kọ́kọ́ ṣíjú wo eégún Oloolu nígbà tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde, onítọ̀hún ma ṣe àárẹ̀, tí wọn kò bá sì tètè ṣe etùtù ẹni náà le jáde láyé.