Wo ohun tó fa iná tó jó apá kan 'Queen Elizabeth Hall' ní fásítì UI

Ọpọ dukia lo ṣofo lẹyin ti ina jo apa kan ilegbee awọn akẹkọọbinrin 'Queen Elizabeth Hall' ni ile ẹkọ giga faṣiti UI niluu Ibadan.
Iroyin kan to jade laarọ Ọjọbọ lo fidi rẹ mulẹ pe apa kan ilegbee awọn akẹkọọbinrin na jona raurau.
Ohun ti a gbọ ni pe ina ọhun bẹrẹ ni bii aago meje aabọ owurọ Ọjọbọ ti o si ba ọpọ dukia jẹ.
Agbenuso ile ẹkọ giga naa, Arabinrin Akinpelu, to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe ina ẹlẹtiriki ti wọn ṣadeedee mu wa lo ṣokunfa iṣẹlẹ naa,
O tun fidi rẹ mulẹ pe ina ọhun jo yara ti wọn fi n ṣe ọfiisi fun awọn to n ṣe amojuto awọn akẹkọọ to wa ni buloku( B) ibugbe Queen Elizabeth Hall to wa ninu ọgba ile ẹkọ naa.
Arabinrin Akinpelu ko ṣai fikun ọrọ rẹ wi pe ẹnikẹni ko farapa ninu iṣẹlẹ ina naa.
O ni awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ pana-pana faṣiti UI lo pa ina ọhun ti ko fi ran de awọn ibomiran lara ilegbee awọn akẹkọọ naa.
Nigba ti BBC Yoruba ṣe abẹwo si apa ibugbe awọn akẹkọọ Queen Elizabeth ti ina jo ọhun ni a ri wi pe gbogbo nnkan to wa nibi ti ina ti sọ ọhun lo jona di eeru.
Awọn akẹkọọbinrin oniwe akọkọ nikan lo n gbe ilegbee awọn akẹkọọ Queen Elizabeth yii lọgba fasiti UI niluu Ibadan.
Iroyin kan tiẹ sọ pe ilegbee awọn akẹkọbinrin Queen Elizabeth Hall yii ni ibugbe awọn akẹkọọ to kọkọ wa ninu ọgba ile ẹkọ naa.















