Iná sọ nílé gbájúmọ́ òṣèré, Mercy Aigbe, ó jó àwọn dúkìá olówó iyebíye kanlẹ̀

Oríṣun àwòrán, Mercy Aigbe/Instagram
Awọn ọrẹ, ololufẹ ati awọn akẹẹgbẹ gbajumọ oserebinrin, Mercy Aigbe Adeoti, ti n ba daro, ti wọn si n tu u ninu lẹyin ti ina jo ile rẹ.
Alẹ Ọjọru, ọjọ kẹrin, oṣu Kejila, ni Arabinrin Aigbe fi ikede sita lori ayelujara Instagram rẹ pe, ina jo dukia naa.
Mercy fi fidio kan sibẹ ninu eyi to ti ṣafihan bi ina ṣe jo ile naa ati awọn nnkan to wa ninu rẹ lati oke de isalẹ.
Labẹ fidio naa lo kọ ọrọ si pe, loootọ ni oun wa ninu ibanujẹ to kọja aala, amọ oun dupẹ lọwọ Ọlọrun pe, ẹmi ẹnikẹni ko sọnu.
Titi di akoko ti a fi ko iroyin yii jọ, a ko le sọ pato nnkan to fa iṣẹlẹ ina ọhun.
Ohun to yẹ ki o mọ nipa Mercy Aigbe
Wọn bi Arabinrin Mercy Aigbe Adeoti ni ọdun 1978. Ọmọ ilu Benin, nipinlẹ Edo ni gbajumọ oṣere ọhun.
Ile ẹkọ gbogboniṣe Plytechnic Ibadan ni Aigbe ti kọkọ gba iwe ẹri OND ninu imọ nipa iṣiro owo. Lẹyin naa lo gba iwe ẹri ninu imọ ere tiata ṣiṣe lati Fasiti ilu Eko.
Inu ere oniṣe ọlọsọọsẹ, Papa Ajasco, ni Mercy Aigbe ti bẹrẹ ere ṣiṣe, to fi mọ iru awọn ere mii bẹẹ.
Ọdun 2006 lo bẹrẹ si ni fi tiata ṣe iṣẹ aje, to si kopa ninu fiimu ‘Ara’, to gbe e jade si gbangba.
Diẹ lara awọn ere to ti sẹ ni:
- Afefe Ife
- Okanjua
- Atunida Leyi
- Igberaga
- Ìpèsè
- Iró funfun
- Mafisere
- Oju ife
- Edaa
- Osas: Omoge Benin
- Gucci Girls
- Ile Oko Mii
Arabinrin Mercy Aigbe gbajumọ pupọ fun oge ṣiṣe ati aṣọ wiwọ, eyi to ti fi gba ami ẹyẹ.
Lọdun 2013 ni Aigbe ṣe igbeyawo pẹlu oniṣowo, Lanre Gentry, amọ igbeyawo naa tuka lọdun 2017, lori ẹsun ‘iwa ipa’.
Ni 2022, o ṣe igbeyawo mii pẹlu olooru sinima, Kazim Adeoti, to si yi pada si ẹlẹsin Islam lọdun 2023. Ọdun naa bakan naa lo tun pa orukọ rẹ da si Hajiya Meena.
Ki lo le fa ijamba ina lasiko ẹrun ati igbesẹ ti o le gbe?
Asiko ẹrun ni ijamba ina wọpọ ju l. Nnkan mẹta si lo ma n ṣe agbaru rẹ - nnkan to le gbana, afẹfẹ ati ooru. Eyi si ni yoo sọ bi ina to n jo yoo ṣe tete ran mọ awọn nnkan miran ni ayika.
Ọjọ diẹ sẹyin ni ina jo idile ẹlẹni marun un kan pa ni agbegbe Ajah, nipinl Eko, ti omiran tun ṣẹlẹ niluu Ede nipinlẹ Osun. Idile ẹlẹni mẹfa lo ba a lọ.
Nigbakugba ti o ba ba ara rẹ ninu ijamba ina, gbe awọn igbesẹ yii:
Sa kuro ni ayika ibi ti ina ti n jo
Kigbe fun iranlọwọ
Ti gbogbo ferese ati ilẹkun lati dena ki ina naa tan kaakiri
To ba jẹ ina ti ko tii pọ, lo ẹrọ panapana, ‘fire extinguisher
Fun ẹni ti ina ba ti ran ni ara, ẹ fi omi to tutu tabi lọwọọr si oju rẹ fun ogun iṣẹju. Amọ, ẹ ma ṣe fi ohunkohun si oju ọgbẹ naa titi ti awọn eleto ilera yoo fi de tabi lọ sileewosan.












