Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Àkójọpọ̀ àwọn ìròyìn káàkiri Nàìjíríà tí kò ṣe é má gbọ̀ ọ́.
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

A o ni rogun ina o

Amin o, amọ ki lo o ri to fi n ṣadura bayii?

Nile gbajumọ oṣere Mercy Aigbe ni ina ma ti sọ lalẹ Ọjọru to si jo dukia olowo iyebiye kanlẹ

Aje o! Ṣe ko ṣa mu ẹmi eeyan lọ?

Rara o, lọ ka ẹkunrẹrẹ iroyin naa loju opo BBC.Com/Yoruba

'''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''

Ki gan an lẹṣẹ ti ajafẹtọọ Dele Farotimi ṣẹ tile ẹjọ fi ju u sẹwọn l'Ekiti?

Bẹẹ laa bi ni o, awọn iwe ile ẹjọ ti BBC ri ṣafihan pe agba ọjẹ agbẹjọro, Afe Babalola, lo fi ọrọ Farotimi sun awọn ọlọpaa lori ẹsun ibanilorukọjẹ

Ajafẹtọọ naa yoo si wa lẹwọn titi di ọjọ kẹwaa oṣu yii ti igbẹjọ naa yo tẹsiwaju.

''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''

Njẹ o ranti olukọ kan niluu Ilorin, Hamzat Fatimoh Nike to faṣọ ya mọ agunbanirọ kan lọrun.

Mo kuku ranti, nibo lọrọ naa de duro bayii?

Lẹyin ti iwadii fidi rẹ mulẹ pe ihuwasi olukọ naa tako ofin iṣẹ ijọba

Ijọba ipinlẹ Kwara ti ja irawọ rẹ lẹnu iṣẹ

Fun ẹkunrẹrẹ iroyin naa