Kí gan-an ni ẹ̀ṣẹ̀ ti ajàfẹ́tọ̀ọ́, Dele Farotimi ṣẹ Afe Babalola, tí adájọ́ fi fi sí ẹ̀wọ̀n?

Dele Farotimi

Oríṣun àwòrán, dele farotimi/facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ile ẹjọ kan nipinlẹ Ekiti ti paṣẹ ki wọn fi ajafẹtọ ọmọniyan, Dele Farotimi si ẹwọn titi di igba ti igbẹjọ ẹsun ti wọn fi kan an yoo tẹsiwaju.

Agbẹjọro naa yoo wa ni ọgba ẹwọn titi di ọjọ kẹwaa, oṣu Kejila ti a wa yii ti igbẹjọ naa yo tẹsiwaju lori ẹsun ibanilorukọjẹ ti wọn fi kan an.

Inu oọfisi rẹ to wa niluu Eko ni ọlọpaa ti mu, ti ẹnikẹni ko si mọ eredi mimu rẹ.

Awọn iwe ile ẹjọ ti BBC ri ṣafihan pe agba ọjẹ agbẹjọro, Afe Babalola, lo fi ọrọ Farotimi sun awọn ọlọpaa nipinlẹ Ekiti.

Ki lo wa ninu iwe ẹsun ti wọn fi kan Farotimi?

Ohun ti a gbọ ni pe Afe Babalola kọ iwe ẹsun alawẹ mẹtalelọgbọn tako Farotimi, ninu eyii to ti fẹsun kan an pe o ba oun lorukọ jẹ ati pẹlu erongba lati da ipaya si ọkan araalu ati lati da ilu ru.

Lẹyin naa ni ọlọpaa mu Farotmi niluu Eko, ti wọn si gbe lọ si Ekiti lati le lọ koju ẹsun mẹrindinlogun ti wọn fi kan an.

Iwe ile ẹjọ ṣafihan pe aarin Farotimi ati kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Samson Osun, ni ẹjọ naa wa.

Ẹsun akọkọ ti wọn fi kan Farotimi ni pe o kọ iwe kan, ‘Nigeria and its Criminal Justice System’, ninu eyii to ti fẹsun kan Babalola pe oun lo ba eto idajọ Naijiria jẹ lọna ati gba idajọ to n fẹ fun awọn onibara rẹ.

Iwe ẹjọ naa sọ pe afurasi ọhun mọ pe irọ ni oun to wa ninu iwe to kọ amọ o mọọmọ gbe iwe ọhun jade.

Ẹsun mii ti wọn fi kan Farotimi ni pe o kọ ohun to le ba orukọ Afe Babalola jẹ ninu iwe rẹ ọhun.

Iwe ẹsun naa ni Farotimi tapa si abala ofin 373 iwa ọdaran Naijiria ti ijiya rẹ wa ni abala 375 iwe ofin kan naa.

Ẹwẹ, ṣaaju ni Farotimi ti kọkọ ba awọn akọroyin sọrọ, nibi to ti sọ pe awọn kan n wa oun kiri lati ji oun gbe, ati pe ti ẹnikẹni ba gbagbọ pe oun ṣẹ wọn, ki irufẹ ẹni bẹẹ gba ile ẹjọ lọ nitori araalu to n tẹle ofin ni oun.

Ki lo wa ninu iwe ti Farotimi kọ?

Nigeria and its Criminal Justice System

Oríṣun àwòrán, Dele Farotimi

Inu oṣu Kọkanla, ọdun 2024 ni Farotimi gbe iwe naa, ‘Nigeria and its Criminal Justice System’ jade.

Ninu iwe naa lo ti sọrọ nipa ọrọ ilẹ kan to wa lagbegbe Eti Osa, niluu Eko, eyii ti awọn oṣiṣẹ Afe Babala ṣe ẹjọ rẹ ti wọn si bori.

Iwe naa tun sọ nipa awọn ẹjọ kan ti Farotimi gbagbọ pe ẹka eto idajọ Naijiria ko ṣe daadaa.

Ta ni Dele Farotimi?

Dele Farotimi

Oríṣun àwòrán, Dele Farotimi/facebook

Agbẹjọro ni Farotimi, onkọwe ati ajafẹtọ ọmọniyan ni pẹlu.

Ọdun 1999 ni wọn fun ni aṣẹ lati maa ṣiṣẹ gẹgẹ bii agbẹjọroni Naijiria, amọ o fẹyinti lọdun 2018.

Lati igba to ti wa ni fasiti LASU, niluu Eko lo ti n ja fitafita fun atunṣe Naijiria ati igbayegbadun araalu.

Lara awọn iwe mii to ti kọ ni ‘Do Not Die In Their War'.

Lọdun 2023, o wa lara awọn to n ṣatilẹyin fun oludije fun ipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi.

Ta ni Afe Babalola?

Agba ọjẹ agbẹjoro ni Afe Babalola.

Oun lo ni fasiti Afe Babalola to kalẹ si ilu Ado Ekiti ati Afe Babalola Chambers.

O le ni ọdunrun agbẹjọro to ti gba abẹ itọni rẹ kọja ni Naijiria.

Ẹni ọdun marundinlọgọrun ni ọkunrin ọhun