Ṣé lóòótọ́ ni ìjọba fẹ́ lé pásítọ̀ Tobi Adegboyega kúrò ní UK lórí ẹ̀sùn jìbìtì £1.87m?

Oríṣun àwòrán, tobiadegboyega/Instagram
Iroyin kan to ti n ja ran-in ran-in lori ayelujara lo sọ pe ijọba Uk ti fẹ le pasitọ ati oludasilẹ ijọ SPAC Nations kuro nilẹ Gẹẹsi lori ẹsun jibiti £1.87m.
Iwe iroyin The Telegraph lo kọkọ fi iroyin ọhun lede wi pe igbimọ igbẹjọ lori bawọn eeyan ṣe n wọ UK ati bi wọn ṣe n jade dajọ pe Pasitọ Adegboyega ni lati fi ilu silẹ.
Iwe iroyin naa sọ pe idajọ yii waye lẹyin ti iwadii fihan pe Pasitọ Adegboyega ṣe owo ijọ rẹ kumọ kumọ.
Iwe iroyin The Telegraph tun sọ pe alufaa Adegboyega ti n gbe ni UK lọna ti ko ba ofin mu lati ọdun 2005 ti o ti gba iwe igbelu gẹgẹ bi alejo ni orilẹede naa.
Ni ọdun 2019 ni iroyin sọ pe Pasitọ Adegboyega gbaye lọwọ ijọba labẹ ajọ ECHR pe ki wọn foun lanfaani lati maa gbe UK lọ lẹyin to ṣe igbeyawo pẹlu ọmọbinrin to jẹ ọmọbibi ilẹ Gẹẹsi.
A gbọ wi pe ajọ naa kọkọ yi ẹbẹ rẹ danu, ṣugbọn o pẹjọ kotẹmilọrun.
Igbimọ igbẹjọ tun sọ pe awọn ọmọ ijọ alufaa Adegboyega fẹsun kan an wi pe o n dari ijọ naa gẹgẹ bi ẹgbẹ okunkun.
Gẹgẹ bi iroyin ti The Telegraph gbe sita, awọn ọmọ ijọ naa tẹlẹ naa jẹri wi pe ni ṣe ni ijọ ọhun dabi ẹgbẹ okunkun.
Wọn ni pasitọ naa maa n gbawọn ọdọ ti ko rọwọ họri ni imọran lati ṣe ohunkohun ti wọn le ṣe lati rowo ki wọn le dawo ni ṣọọṣi.
Koda, wọn ni awọn ọmọ ijọ mii maa n ya owo tabi lu jibiti to fi mọ tita ẹjẹ wọn ki wọn le rowo.
‘’Ijọba o le Pasitọ Tobi Adegboyega kuro ni UK o’’
Nigba ti o n fesi si iroyin to ti lu ori ayelujara pa lori ọrọ Pasitọ Tobi Adegboyega, agbẹjọro pasitọ naa, Dele Olawanle, sọ loju opo X rẹ pe awada kẹrikẹri ni iroyin ọhun.
Amofin Olawanle ni lati ana ọjọ Iṣẹgun lawọn eeyan ti n pe oun lori foonu tawọn mii si n fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si oun lori ọrọ naa.
Ọgbẹni Olawanle ni ‘’ni ṣe ni mo bu sẹrin-in nigba ti mo gbọ iroyin to ni ijọba ti fẹ le Pasitọ Adegboyega kuro ni UK.
Alaimọkan ni iwe iroyin to gbe iroyin yii sita tori ọrọ ko ri bẹẹ rara.
Emi ni agbẹjọro rẹ ati ti ijọ rẹ pẹlu, ko si ohun to jọ pe ijọba fẹ le e kuro ni UK.
Awọn to ba huwa ọdaran ni ijọba maa n le kuro lorilẹede UK, amọ, pasitọ Agbegboyega kii ṣe ọdaran.’’
Amofin Olawanle ni loootọ ni pe ẹjọ ijọ SPAC Nations wa niwaju ile ẹjọ ati ajọ to n ri si ṣiṣe aanu fawọn alaini.
Amọ, amofin Olawanle sọ pe Alufaa Adegboyega ko jẹbi ẹsun kankan.
‘’Tobi ti n gbe ni UK fun bii ogun ọdun lai ni akọsilẹ iwa ọdaran kankan.
O si ti ṣiṣẹ takun takun fun idasoke awujọ rẹ nibi to n gbe ni UK.
Tobi ti koju oriṣiiriṣi ipenija, ṣugbọn o ti bori gbogbo wọn, ọpọ awọn to jẹ ọta rẹ lo wa lati awujọ awọn ọmó ilẹ Afirika to n gbe ni UK.
Iyalẹnu lo jẹ fun mi pe ọpọ eeyan n wa iṣubu ẹlomiran to fi mọ awọn eeyan ti wọn n pe ara wọn ojiṣẹ Ọlọrun.’’
Olawanle ni oun ti sọ pe irọ nla ni iroyin to ni ijọba fẹ le Pasitọ Tobi kuro ni UK, oun ko si ni sọ nkan kan mọ lori ọrọ naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















