Netumbo Nandi-Ndaitwah di Ààrẹ obìnrin àkọ́kọ́ tí wọ́n dìbò yàn ní Namibia

Oríṣun àwòrán, Reuters
Wọn ti dibo yan Netumbo Nandi-Ndaitwah, lati inu ẹgbẹ oṣelu South West Africa People's Organisation (Swapo), gẹgẹ bii aarẹ obinrin akọkọ ni Namibia.
Ileeṣẹ to n ri si eto idibo orilẹede naa sọ pe obinrin ọhun lo ni ida 57% ibo ti wọn di nibẹ, nigba ti ẹni to n tẹle lẹyin, Panduleni Itula, ni ibo 26%.
Amọ lẹyin oniruuru idojukọ to waye lasiko eto idibo naa, eyii to mu ki wọn sun ibo si ọjọ mẹta mii lawọn agbegbe kan, Itula ti sọ pe oun ko faramọ esi ibo ọhun.
Pupọ ninu awọn ọmọ ẹgbẹ alatako lo kọ lati yọju sibi ti wọn ti kede esi ibo naa niluu Windhoek lọjọ Iṣẹgun.
Nigba to n sọrọ lẹyin ti wọn kede esi ibo naa tan, Nandi-Ndaitwah sọ pe “Awọn ọmọ Namibia ti dibo fun alaafia ati itẹsiwaju ijọba.”
Lati ọdun 1990 ti orilẹede Namibia ti gba ominira ni ẹgbẹ Swapo ti wa lori iṣejọba.
Ọmọ ẹgbẹ oṣelu Swapo yii naa ni Aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Nandi-Ndaitwah, wa.
Nandi-Ndaitwah ni igbakeji Aarẹ Namibia lonii, o si ti wa ninu ẹgbẹ oṣelu naa lati nnkan bi ọdun marundinlọgbọn sẹyin.
Lẹyin iburawọle rẹ, Nandi-Ndaitwah yoo darapọ mọ Aarẹ Tanzania, Samia Suluhu Hassan, gẹgẹ bi aarẹ obinrin keji to wa ni iṣakoso nilẹ Africa.
Ẹgbẹ to gbe ipo keji ninu eto idibo naa, Independent Patriots for Change (IPC) ti Itula ti gbe apoti ti sọ pe oun yoo gba ile ẹjọ nitori awọn ko faramọ esi ibo ọhun.















