Wo orílẹ́èdè tó kéde owó ìfẹ̀yìntì àti àkànṣẹ ètò ìlera fáwọn olówò nàbì

Aworan awọn olowo nabi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Orilẹede Belgium ti buwọlu ofin ti yoo fun awọn ọmọ ọlọja irọlẹ ti ọpọ eeyan mọ si 'Aṣẹwo' ni anfani ti awọn oṣiṣẹ ijọba n ri gba lorilẹede naa.

Aba naa to di ofin lọjọ Aiku lo fi idi rẹ mulẹ wi pe eyii to ba loyun ninu wọn yoo maa ni anfani lati gba isinmi ranpẹ, eyii to ba yọwọ nibi iṣẹ naa yoo maa gba owo ifẹyinti, bẹẹ si ni aabo to ni atilẹyin ofin yoo maa wa fun wọn lati le bọriyọ lọwọ awọn eeyan to ba fẹ ṣi wọn lo.

Igbesẹ yii waye lẹyin iwọde alagbara ti awọn awọn olowo nabi ṣe l'ọdun 2022 nibi ti wọn ti n beere iredi ti ijọba orilẹede naa ṣe ya wọn kuro lara awọn eeyan ti wọn ṣe iranlọwọ fun lasiko itankalẹ ajakalẹ aarun COVID-19.

Labẹ ofin tuntun yii, awọn olowo nabi ni agbara lati yan iru ẹni to wu wọn lati ṣiṣẹ ibalopọ fun, wọn le sọ rara si ẹni ti ko wu wọn, bẹẹ si ni wọn ni agbara lati sọ iru ara ti onibara le fi wọn da.

Bakan naa si ni ofin naa tun kan an nipa fun awọn olowo nabi lati maa wa ni imọtoto ni gbogbo igba, gẹgẹ bi wọn ṣe ni anfani si awọn ohun elo igbalode ti yoo mu ko rọrun lati ke gbajare lasiko idagiri.

Ẹgbẹ awọn olowo nabi lorilẹede Belgium ti gboṣugba kare fun ijọba orilẹede naa lori igbesẹ ofin yii, gẹgẹ bi wọn ṣe pe e ni igbesẹ ti yoo fi opin si iwọsi ti awọn eeyan fi n wọ awọn olowo nabi ni orilẹede naa.

Ọkanojọkan ajọ ajafẹtọmọniyan l'agbaye ti n ṣe ariwisi si igbesẹ naa. Lara wọn ni ajọ 'Human Rights Watch' to n ke si awọn orilẹede to ku ni agbaye lati gbe iru igbesẹ naa.

Bakan naa ni Erin Kilbride ti o jẹ ajafẹtọmọniyan ṣe alaye siwaju si i wi pe gbogbo orilẹede ni agbaye lo yẹ ki o ṣe awokọṣe igbesẹ naa.

O fi kun ọrọ rẹ wi pe igbesẹ naa waye lai fi akoko ṣofo, bẹẹ ni si ni o duro gẹgẹ bi i igbesẹ to dara julọ l'agbaye.

Ọkan lara awọn olowo nabi naa, Sophie ṣe alaye fun BBC pe "igbesẹ naa yoo fun gbogbo eeyan ni anfani lati gbe aye bo ṣe wu wọn."

Ni ode agbaye ni ọpọlọpọ eeyan ti n koro oju awọn olowo nabi, nitori pe oju ọlẹ ati alaini nnkan ṣe ni wọn fi n wo awọn eeyan to n ṣ iru iṣẹ naa.

Ṣugbọn ni bayii ti orilẹede Belgium ti buwọlu ọpọlọpọ anfani fun awọn olowo nabi, o ṣeeṣe ki ayipada ba oju ti awọn eeyan fi n wo wọn ni agbaye.