'Níse ni ẹ̀yà ara èèyàn fọ́n káàkiri, àpò lá fi kó wọn jọ fún ìsìnkú àpapọ̀'

Oríṣun àwòrán, Gift Ufuoma / BBC
- Author, Azeezat Olaoluwa
- Role, BBC News, Tudunbiri
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9
Olukọ ẹkọ Musulumi kan, Masud Abdulrasheed, lo ṣi n la kaka lati gbagbe ironu lori iku to pa ọmọ rẹ, ọmọ ọdun meje nibi idungbamu ti ileeṣẹ ologun ilẹ Naijiria ju lasiko ayẹyẹ ẹsin ti wọn ṣe, ṣugbọn to jẹ pe abule elero pupọ kan lo ti balẹ lọdun kan sẹyin.
Ileeṣẹ ologun sọ pe aṣita ni idungbamu ọhun jẹ latari ‘aikiyesara’, leyi to fa aṣiṣe fun ikọ ọmọ ogun nibi ayẹyẹ ita gbangba to waye ni Tudunbiri fun ikọ ọmọ ogun Jihad.
“Iṣẹlẹ ọjọ kẹta, oṣu Kejila, ọdun 2023 naa jẹ ajalu nla ti ko yẹ ko ṣẹlẹ rara,” agbẹnusọ ileeṣẹ ologun, Ọgagun Edward Buba sọ fun BBC. “Ileeṣẹ ologun kabamọ iṣẹlẹ ọhun. Ati pe bi a ba le mu ẹmi awọn ti a padanu pada, a o mu wọn pada.”
Ikilọ: Iroyin yii ni awọn aworan to le ba ọkan jẹ ninu, fun awọn ti ko ba ni ọkan lati wo o
Awọn to to ẹgbẹrun marundinlaadọrun-un ni wọn ku, to fi mọ ọmọ Abdulrasheed ti orukọ rẹ n jẹ Habeebah, nigba ti idungbamu meji ọhun balẹ si abule kan ni ẹkun ariwa Kaduna.
“Ibugbamu akọkọ lo jabọ le wa lori ni nnkan bi agogo mẹwaa, nitosi abẹ igi kan ti awọn obinrin kan ati awọn ọmọ wọn jokoo si,” Ọgbẹni Abdulrasheed ṣe iranti. “A sa asala fun ẹmi ara wa, ṣugbọn lẹyin bi iṣẹju diẹ, a pada lati lọ ran awọn to farapa lọwọ, ti a si n pe fun iranlọwọ, ṣugbọn ibugbamu keji tun jabọ, to si pa ọpọ eeyan.”
Ọgbẹni Abdulrasheed ṣapejuwe Habeebah gẹgẹ bi “ọmọ to mọ itọju ṣe julọ laarin awọn ọmọ mi.”
“Gbogbo ẹbun ti wọn ba ti fun un, lo maa n fun mi, koda bi n ko ba tiẹ nilo ẹbun naa,” o sọ fun BBC.
Baale ile, ẹni ọdun mẹrindinlogoji naa wa lara awọn to ṣagbatẹru ayẹyẹ ọlọdọọdun naa ti a mọ si Maulud, eyi ti wọn n ṣe lati fi ṣayẹyẹ ọjọ ibi Anọbi Muhammad.
Ọpọ awọn ọmọ ile keu rẹ ni wọn ku sinu ajalu naa.
“A ri oku awọn eeyan kaakiri ilẹ bi ẹni pe niṣe ni wọn n sun. Ẹya ara naa tun lọ kaakiri - bi wọn ṣe wa lori igi naa la tun n ri wọn lori orule ile. A ni lati ko wọn jọ sinu apo, ti a si lọ sin wọn sinu saare kan naa.
“Ko si ohun to bani lọkan jẹ ju ki awọn ti a ranṣe pe wa sibi ayẹyẹ lati pade iku ojiji ti yoo jẹ igbẹyin wọn. O bu ọgbẹ si ọkan mi,” Abdulrasheed sọ bẹẹ.
Bi baba ọlọmọ mẹrin naa ṣe n ba BBC sọrọ, o mu ọmọ rẹ obinrin, Zaharau jokoo lẹgbẹ rẹ lori ẹni niwaju ita ile wọn. Niṣe lo rọra ṣi aṣọ ọmọ naa soke lati ṣafihan ọgbẹ to wa ni ikun rẹ.

Oríṣun àwòrán, Gift Ufuoma / BBC
Zaharau, ọmọ ọdun mẹrin ọhun ni nnkan ija oloro ti wọn pe ni ‘shrapnel’ ba. O gba wọn to wakati kan ki wọn to le ri ọkọ gbe oun pẹlu awọn to farapa de ile iwosan to wa nitosi niluu Kaduna.
Bo tilẹ jẹ pe o la iṣẹ abẹ kọja, ọgbẹ rẹ ko tun tii jinna patapata.
“Nigba ti ọmọ mi ati awọn yooku ti wọn farapa de ile iwosan, wọn tọju gbogbo wọn daadaa. A dupẹ lọwọ ijọba fun iyẹn.
“Ṣugbọn nnkan yipada nigba ti wọn fi wọn silẹ, lẹyin oṣu diẹ. Awọn ile iwosan naa dẹkun lati maa tọju wọn lọfẹẹ. Awawi ni wọn n fun wa.”
“Bi ẹ ba n lọ kaakiri Tudunbiri, ko fẹẹ si idile kan ti ko kagbako ajalu ọhun lalẹ ọjọ naa.
Aisha Buhari, ọmọ ogun ọdun naa padanu awọn aburo rẹ ọkunrin mẹta. Oun nikan lo ye, to si n jẹ irora ọgbẹ to wa ni apa rẹ, eyi ti ko tii jinna tan.
Lori aga ijokoo to wa, niṣe lo n sunkun, to si tun n nu omije rẹ nu pẹlu ijaabu to wọ lasiko to n ṣe iranti bo ṣe padanu awọn aburo rẹ mẹta.
“Lalẹ ọjọ yẹn, mo ṣẹṣẹ ba wọn sọrọ tan ni, nko tii rin jinna si ibi ti wọn wa ti ibugbamu akọkọ fi dun, to si jẹ iyalẹnu nigba ti mo bẹrẹ sii ri oku awọn eeyan kaakiri laarin iṣẹju diẹ,” Arabinrin Buhari sọ bẹẹ.
“Nigba ti wọn gbe mi de ile iwosan, nko le ronu ohunkohun kọja awọn aburo mi. Mo sun ẹkun gidi.”
Bi Buhari ṣe n sọrọ, niṣe lo n danu duro lati nu omi to n jade loju ọgbẹ rẹ pẹlu omije loju.
“Ko si iṣẹ ile kan tabi iṣẹ oko kan ti nko le ṣe ki iṣẹlẹ naa too ṣẹlẹ, ṣugbọn ni bayii, nko le ṣe ohunkohun daadaa. Mo ni lati gbe ara le awọn eeyan lati ran mi lọwọ ki n to le ṣe ohunkohun to fi mọ aṣọ tabi abọ fifọ,” o sọ bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, Gift Ufuoma / BBC
Gomina ipinlẹ Kaduna, Uba Sani sọ fun BBC pe oun yoo da si ọrọ awọn ara abule naa, paapaa bi iru awọn eeyan bii Buhari.
"Mo maa pada lọ si Tundunbiri funra mi, bi mo ba si ri awọn to ṣi nilo itọju, mo maa tọju wọn,’ o ṣe ileri.
"Aṣẹ ti mo fi silẹ ni pe ki wọn tọju gbogbo wọn, ati pe wọn ko gbọdọ fi ẹnikẹni silẹ lati maa lọ sile lai jẹ pe ara wọn ti ya daadaa,” o fi kun ọrọ rẹ."
Lai ro ti ajalu to waye lọdun to kọja, awọn Musulumi ṣi tun ṣayẹyẹ naa lọdun yii, ṣugbọn wọn ṣe e l'oṣu meji ṣaaju asiko naa.
Ayẹyẹ naa ni wọn tun lo lati fi ṣi mọṣalaṣi tuntun, lati fi ṣe iranti ajalu to ṣẹlẹ nibi ikọlu ibugbamu, gẹgẹ bi eyi ti wọn ṣe lati fi dun wọn ninu.
Abdulrasheed lo duro gẹgẹ bi imaamu mọṣalaṣi naa, nitori bi imaamu tẹlẹ ṣe ku sinu ibugbamu to waye.
“Inu wa dun nipa mọṣalaṣi tuntun, ṣugbọn a ko le gbagbe ohun to ṣẹlẹ,” Abdulrasheed sọ fun BBC. “Gbogbo igba ti mo ba wa sibi, mo maa n ranti ọjọ naa, o si maa n ba mi lọkan jẹ. Bi a ṣe ṣayẹyẹ Moulud tọdun yii, a ṣi tun ṣe iranti awọn ti a padanu.”
Fun ọpọlọpọ ọdun ni ileeṣẹ ologun Naijiria ti n ni adojukọ awọn ọmọ ogun Jihad ati ọdaran, ti wọn n kogun ja awọn eeyan labule, ti wọn si tun n ji awọn eeyan lati gba owo lẹkun Ariwa.
Eleyi lo si ti fa ki wọn maa ju ado oloro soke lati fi kọlu wọn.
Ileeṣẹ ologun ori afẹfẹ ti gba ọkọ baluu tuntun, olootu Defence Web, Guy Martin, sọ fun BBC.
Lara rẹ ni eyi ti wọn ṣe lati ilẹ China ti wọn pe ni (UAVs), ti wọn n pe ni ‘drones’.
“UAVs ti China ko gbowo pupọ lori, leyi to jẹ ki wọn le tete rii ra. Bii ida mẹta awọn orileede nilẹ Afrika ni wọn le ra awọn ọkọ ofurufu ti wọn fi n jagun yii, UAVs, lati orileede bii Turkey ati China,” Martin sọ bẹẹ, to si tun n tọka sii pe ado oloro ti wọn ju pẹlu UAVs yii lo fa ajalu ni Tudunbiri.
“Aṣiṣe aini imọ, idari to ko koju oṣuwọn, ati ai gba idanilẹkọọ to tọ lo fa ajalu naa. Bi wọn ko ba fun awọn ti yoo lo irinṣẹ UAVs ni idanilẹkọọ to yege, ti wọn ko si gba itọni to tọ, o le fa aṣiṣe iru eyi to ṣẹlẹ naa,” Martin fi kunb ọrọ rẹ.
Ọgagun Buba sọ fun BBC pe ileeṣẹ ologun maa n ni adojukọ to pọ lawọn agbegbe to yẹ ki wọn ti ṣiṣẹ wọn.
“Ṣugbọn a ti ni idagbasoke ninu bi a ṣe le lo awọn irinṣẹ wa, ati pe a ni ọna ti a n gba ran awọn ọmọ ogun jade lọ soju ogun, paapaa awọn adari ti wọn ni iriri,” o sọ bẹẹ.
Gẹgẹ bi ileeṣẹ SBM ṣe sọ, ko din ni aṣiṣe jiju ado oloro mẹtadinlogun ti ileeṣẹ ti ṣe laarin oṣu Kinni, ọdun 2017 si oṣu Kẹsan, ọdun 2024, leyi to ti pa awọn to le ni ẹẹdẹgbẹta danu.

Oríṣun àwòrán, Gift Ufuoma / BBC
“Aṣiṣe kan ṣoṣo ti to; nigba ti a ba ri awọn ọgọrun ti wọn n ku ninu ikọlu, o yẹ ko jẹ wa logun,” oniṣe iwadii Ajafẹtọ ọmọniyan ni Naijiria, Anietie Ewang sọ eyi.
Ni idahun, Ọgagun Buba sọ pe awọn olupolongo fun ẹtọ ni lati maa “fun wa ni oriyin bi a kii ṣe fi ohunkohun pamọ, nipa ṣiṣe iṣẹ papọ pẹlu awọn eeyan, ati gbigba aṣiṣe to ba wa lati ọdọ wa mọra, gẹgẹ bi eyi to ṣẹlẹ ni Tudunbiri.”
“Ohun gbogbo la maa ṣe, lati rii pe iru nnkan bayii ko tun ṣẹlẹ mọ,” Ọgagun Buba fi kun ọrọ rẹ.
O ni ọmọ ogun meji lo ti foju ba ile-ẹjọ lori iṣẹlẹ naa, ati pe lasiko ti igbẹjọ n lọ lọwọ, ileeṣẹ ologun ti gba aṣọ lọrun wọn.
Ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ ni wọn ti gbe iṣẹ akanṣe dide fun abule naa gẹgẹ bi eyi ti wọn ṣe lati fi ẹdun ọkan wọn han lori awọn to ku, pẹlu bi Sani ṣe sọ fun BBC pe iṣẹ akanṣe kikọ ile iwosan ati kikọ gbọngan ẹkọṣẹ ti ṣe fẹẹ pari nibẹ.
“A ti n ṣe iranwọ fun awọn ara Tudunbiri, a si tun maa tẹsiwaju lati maa ṣe bẹẹ,” o sọ eyi.
“Awọn eeyan mi ni wọn,” gomina fi kun ọrọ rẹ.
Ṣugbọn nipa iwa ọdaju, awọn to le ni ogun ninu abule naa ni wọn ti sọ pe ijọba ti gba oko ti wọn n da lati fi kọ awọn ohun ti wọn sọ yii.
Lara wọn ni Hashim Abdullahi, ẹni aadọta ọdun to sọ fun BBC pe “Inu mi ko dun nitori pe ile iwosan yii lo gba ọna atijẹ lọwọ mi, ti wọn ko si fun mi ni ohunkohun gẹgẹ bii gba mabinu. Wọn ti sọ mi di alainiṣẹ lọwọ, ti nko si le wa ounjẹ fun awọn mọlẹbi mi mọ.”
Nigba to n dahun, Sani sọ pe: “Fun awọn to ni ilẹ, ileeṣẹ to n ri sọrọ ilẹ ni Kaduna ti n ṣiṣẹ pẹlu awọn olori agbegbe naa lati rii pe gbogbo awọn to ni ilẹ gba ilẹ wọn pada.”
Igbakeji aarẹ Naijiria, Kashim Shettima naa ṣabẹwo si abule yii lẹyin ikọlu naa, to si ṣeleri ni ibamu pẹlu ti ijọba ipinlẹ wi pe gbogbo awọn ọrọ kan ni wọn maa fun ni ẹtọ wọn.
Wọn sọ fun awọn eeyan pe wọn yoo gba miliọnu meji aabọ lori ẹnikan to ba ku ninu mọlẹbi wọn, nigba ti awọn to farapa yoo gba N750,000 naira.
“Iyatọ wa wi pe ijọba n fun awọn eeyan ni ẹtọ wọn lasiko yii, ṣugbọn o ṣeni laanu pe magomago wa nibẹ,” Ewang sọrọ yii.
“A nilo lati rii pe awọn alakoso n ṣiṣẹ lati jẹ ki idajọ ododo waye, ki wọn si jẹ ki ohun ti wọn n ṣe han sita, ati lati fun awọn to fara kaaṣa ninu ikọlu ibugbamu naa gba ẹtọ wọn, pẹlu bi wọn ti ṣe sọ pe awọn jẹbi,” o fi kun un.
Buhari sọ fun BBC pe awọn mọlẹbi oun gba miliọnu meje aabọ naira lori awọn aburo oun mẹta ti wọn pa, toun naa si gba 750,000 naira fun ifarapa toun ni – bo tilẹ jẹ pe ko to.

Oríṣun àwòrán, Gift Ufuoma / BBC
“Gbogbo igba ni mo maa n ra oogun ni ile itaja oogun lati fi tun oju ọgbẹ mi yii ṣe, nitori pe oun ti agbara ka lasiko yii niyẹn. Wọn ko da wa lohun nile iwosan mọ. Nigba miran, mo maa n jẹ irora fun ọpọlọpọ ọsẹ,” o sọ bẹẹ.
“A n ni ireti wi pe ijọba yoo wa lati ṣe iranwọ fun wa, ki n le maa gba itọju to pe ye pada,” Buhari sọ bẹẹ.
Abdulrasheed sọ fun BBC pe oun ko tii gba iranlọwọ owo kankan lori ọgbẹ ati ipalara ti ọmọ ọdun mẹrin oun n jẹ irora rẹ.
“O ma n kọ mi lominu nigbakugba ti mo ba n wo o, ti mo si n ri ipo to wa,” o sọ bẹẹ.
O loun ti gba gbogbo owo to yẹ lori ọmọ ọdun meje oun ti wọn pa, ati pe ko si iye owo ti wọn le fun oun, to le rọpo rẹ.
“Gbogbo igba ti mo ba ṣabẹwo sibi iboji rẹ, mo maa n ranti awọn ti a jọ maa n gbe papọ, ṣugbọn ti wọn ko si mọ. Mo n ṣafẹri wọn gidi. Mo n ṣafẹri ọmọ mi.”













