Bí ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ ṣe da ìgbéyàwó mi rú - Ronke Odunsanya

Ronke Odusanya

Oríṣun àwòrán, Ronke Odusanya/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Gbajugbaja oṣerebinrin , Ronke Odunsanya ti sọrọ sita nipa ohun to da igbeyawo rẹ ru, to si ni gbogbo igba ti oun ba n ranti iṣẹlẹ naa ni omije maa n jabọ loju oun.

Ronke Odunsanya tọpọ awọn eeyan mọ si Flakky Ididowo lo sọrọ naa laipẹ nibi ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu akẹgbẹ rẹ lagbo oṣere, Bimpe Akintunde tọpọ mọ si Wasila Coded.

Odusanya sọ pe ọrẹ oun timọtimọ kan ti oun ti pa ti sẹgbẹ kan, lo duro gẹgẹ bi eṣu lati da igbeyawo oun pẹlu Saheed Ọlarewaju ti awọn eeyan mọ si Jago ru.

Bo tilẹ jẹ pe Flakky Ididowo jẹ ko di mimọ pe gbogbo ọrọ naa ti yanju, sibẹ o ni oun ko le gbagbe titi lai, nitori pe ibanujẹ lo maa n jẹ fun oun ni gbogbo igba.

Iya ọlọmọ kan naa ni oun ko le sọ pato nnkan to wa lọkan ọrẹ oun naa, ẹni to kọ lati darukọ rẹ, to fi di pe o bẹrẹ sii tako oun niwaju ọkọ oun.

O ni pẹlu gbogbo igbiyanju rẹ lati fẹ obinrin miran fun ọkọ oun, sibẹ, o ni ọkọ oun ko gba, to si loun mọ pe Ọlọrun yoo ṣe idajọ.

“Ọrọ ọkọ atiyawo lọpọ igba ko ṣee da si, nitori pe ko sẹni to le sọ ohun ti wọn fi pilẹ igbeyawo wọn. Bibeli si sọ pe ti ipilẹ ba bajẹ, ki ni olododo yoo ṣe.

“Ti mo ba ni anfaani lati sọrọ, paapaa ninu ijọ ti mo n lọ, mo maa n fi ọrọ ara mi ṣe apẹẹrẹ lori akori ọrọ ti mo ba fẹẹ sọrọ le lori, nitori pe mo jẹ alabapin ninu ọrọ igbeyawo.

“Mo fẹẹ bẹ awọn to kere si wa wi pe ti wọn ba ti fẹẹ yan awọn alabaarin wọn, ki wọn ṣọra wọn gidi, ki wọn si farabalẹ daadaa. Ko tiẹ si bi a ṣe le maa kiyesara to, ẹlomiran le maa dibọn, ko fi iwa rẹ pamọ, nitori nnkan to fẹẹ ri gba.

“Ọkunrin miran maa fi iwa rẹ pamọ fun obinrin nitori owo to fẹ maa ri gba lọwọ rẹ, gbogbo ohun ti obinrin naa ba n ṣe lo ma maa farada, ṣugbọn to ba di wi pe o fẹ obinrin naa sile tan, lilu ni lojoojumọ.

“Ẹni to maa ku ko tii mọ iru iku to maa pa oun, a ni lati maa ṣe suuru fun ara wa.”

O ṣe pataki keeyan ni mọlẹbi gidi

Ronke Odusanya

Oríṣun àwòrán, Ronke Odusanya/Facebook

Nigba to n sọrọ nipa bo ṣe la iṣoro naa kọja, Flakky sọ pe “lotitọ ko sẹni ti mimi aye ko le mi, mo dupẹ lọwọ mọlẹbi ti Ọlọrun fun mi.”

O ni o ṣe pataki keeyan ni mọlẹbi gidi. Iya mi, aburo mi, mọnija mi ati agbẹjọro ti Ọlọrun lo fun mi. Ọlọrun lo awọn eeyan to dara fun mi. Nigba ti gbogbo ọrọ yẹn ṣẹlẹ...mo lero wi pe o yẹ ki n maa ṣe idanilẹkọọ paapaa fun awọn to ba n fẹ awa ti oju ba mọ bayii,” Flakky jẹ ko di mimọ.

Ronke Odusanya sọ pe ẹnikẹni to ba fẹẹ fẹ oṣere tabi gbajumọ, gbọdọ jẹ awọn ti kii gbọ ọrọ rara, tabi ki wọn fi gbigbọ ṣe alaigbọ, wọn si gbọdọ jẹ agbọmabiwọn.

O ni ọkọ oun nigba naa, pada kabamọ wi pe ko yẹ ki oun gbọ nnkan tawọn eeyan sọ fun nigba yẹn.

Ile Sẹnetọ kan ni ọrẹ mi sọ pe mo lọ sun mọju

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

“Ọrẹ mi kan lo lọ sọ fun ọkọ mi wi pe emi ti fẹẹ fi silẹ tipẹ, wi pe mo fẹ lọ ṣe iranu. O ni bi mo ṣe kuro nibẹ lalẹ ọjọ yẹn, ile Sẹnetọ kan ni mo lọ sun, wi pe nko si pẹlu Fifẹ.

“Niṣe ni mo la ẹnu silẹ ti nko si le paa de nigba to n sọ fun mi. Ọlọrun fun mi ni oore ọfẹ, mo ya fọnran ibi ti a lọ sun lọjọ yẹn.

Ronke sọ pe oun ko ni owo kankan lọwọ lọjọ ti ọkọ oun le oun jade nile, ati pe gbogbo nnkan ti oun ni lọjọ naa ko ju mọto ti oun fi owo ara oun ra lọ.

O sọ pe aburo oun lẹni toun ranṣẹ pe lalẹ ọjọ naa, to si ni ile aburo oun loun pẹlu ọmọ oun Fifẹ lọ sun mọju.

“Nko ni owo kankan ti mo le fi gba ile lasiko naa, mo kan ṣa n ronu loriṣiriṣi. Pẹlu gbogbo nnkan ti mo n la kọja nigba yẹn, ọrẹ mi kan duro digbi gẹgẹ bii ‘apurọ-mọ-ni tako-ẹni’ nigba yẹn.

“Nkan mo mọ ni pe Ọlọrun a ṣe idajọ to ba yẹ. Ni gbogbo igba ti mo n sọ yii, emi pẹlu ẹni naa kii ṣe ọlọrọ mọ, nitori pe mo ti tete yẹra fun un nigba ti mo ti ri iru eeyan to jẹ.

“Ko mọ ile awọn ẹbi ọkọ mi, ṣugbọn o tun mu ọrẹ rẹ kan lọ fun ọkọ mi nibẹ wi pe ọkọ mi gbọdọ fẹ ẹ. Ṣugbọn mo dupẹ lọjọ oni.

“Ipo ti mo wa loni jẹ ki n mọ wi pe ko sẹni ti ko le ṣubu, bẹẹ si ni ko sẹni ti ko le dide. Ẹ ma ṣe jẹ ka ro ara wa pin. Nko ba Baba Fifẹ ja, gbogbo igba la maa n sọrọ lori ọrọ ọmọ to pa wa pọ.

“Oun naa si ti kọ ọgbọn ninu gbogbo nnkan to ṣẹlẹ naa, to si maa n sọ fun mi.”

O wa rawọ ẹbẹ si gbogbo awọn to n fẹ oṣere tiata lati maa ṣe suuru, ati pe ki wọn dẹkun lati “maa tọpinpin awọn nnkan ti a kọ mọ lapọju, o maa n ṣakoba fun ibaṣepọ.”