Ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ nínú ẹbí obìnrin aṣerunlóge tí àwọn onífàyàwọ́ jù sínú òkun

Oríṣun àwòrán, Hussein family
Inu ibanujẹ nla ni mọlẹbi arabinrin aṣerunloge kan, Fathi Hussein, wa bayii lẹyin ti ọmọbinrin naa ku iku oro sinu okun lasiko to n ba awọn onifayawọ rinrinajo lọ si Erekusu Mayonette.
Aburo oloogbe, Samira, sọ fun BBC pe awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn, ti ori si ko yọ, s fun ẹbi wọn pe, ebi lo pa Fathi ku.
Ẹbi Fathi gbọ pe inu ọkan ninu awọn ọkọ oju omi kekere meji lo ku si, lẹyin bi ọjọ mẹrinla ti awọn ọkọ naa ti n koju idaamu lori agbami India Ocena, lẹyin ti awọn onifayawọ pa wọn ti.
“Ẹja tutu ni awọn eeyan n jẹ, ti wọn si n mu omi okun, ṣugbọn ti oun kọ lati ṣe bẹẹ. Awọn ti ori ko yọ ninu ijamba naa sọ pe nigba to ya, Fathi bẹrẹ si ni sọ kantan-kantan, ti ọrọ rẹ ko si jọ ti ara aye ṣaaju ko to o ku. Lẹyin to ku ni wọn ju oku rẹ sinu okun.”
Ẹnu awọn ọmọ orilẹ-ede Somali bi ti ẹ ni ẹbi Fathi ti gbọ iroyin iku rẹ, lẹyin ti awọn apẹja doola wọn ni bebe okun ni Madagascar ni bi ọsẹ kan sẹyin.
Ajọ to n mojuto ọrọ awọn arinrinajo, International Migration Organization (IMO), sọ pe o le ni aadọrin eeyan to wa ninu awọn ọkọ oju omi mejeeji lasiko to danu sinu okun, nibi ti eeyan mẹrinlelogun ti ku, ti mejidinlaadọta si la.
Ogunlọgọ awọn arinrinajo ni igbagbọ wa pe o n ku lọdọdun lasiko ti wọn ba n gbiyanju lati re kọja lọ si French Island, to to 300km si Madagascar, fun igbe aye rere.
Ọjọ kinni, oṣu Kejila, ni Fathi wọ baalu lati Mogadishu lọ si Mombasa ni Kenya, lẹyin ọjọ diẹ si lo wọ ọkọ oju omi to n lọ si Mayotte – irinajo to lewu fun 1,100km, lori okun Indian Ocean.
Fathi ko sọ ipinnu rẹ fun ẹbi rẹ rara, ayaafi aburo rẹ kan to sọ fun pe gbogbo owo ti oun ko jọ nidi iṣẹ aṣerunloge, ni oun san fun awọn onifayawọ naa.
Diẹ lara awọn ti ori ko yọ ninu iṣẹlẹ naa gbagbọ pe awọn onifayawọ naa mọọmọ fi wọn silẹ lori agbami ni, nitori pe wọn ti gba owo iṣẹ wọn, ti wọn ko si ni erongba kankan lati ko wọn lọ si Mayotte – bẹẹbi Samira sọ fun BBc.
Oludari ajọ IMO ni ẹkun naa, Frantz Celestin, sọ fun BBC pe laipẹ yii ni eeyan mẹẹdgbọn ki ninu iru irinajo bẹẹ laarin Comoros ati Madagascar.
Iwadii BBC fihan pe awọn eniyan naa n rin irinajo ewu ọhun pẹlu ireti pe awọn yoo ri iwe igbelu gba ni France, ati anfaani lati gbe ni ilẹ Yuroopu.
Koda, awọn ipolowo irinajo yii n lọ lori awọn ayelujara bii Tiktok, ti awọn to n bọ si ọwọ awọn onifayọ ọhun si n san to $6,000 fun irinajo ori omi lati Mombasa si Mayotte.
Ninu awọn ipolowo naa, ọk oju omi nal ni wọn ma n sọ pe awọn yoo fi ko awọn arinrinajo, ṣugbọn awọn ẹbi ti eeyan wọn ti kagbako sọ pe, kọ oju pmi kekere ti awọn apẹja n lo, ni wọn fi n ko wọn lọ.
Ẹbi Fathi sọ pe awọn fi ọrọ naa to ijọba leti nipa onifayawọ kan ti wọn fura si pe oun ni ọmọ wọn ba sọrọ niluu Mogadishu.
Awọn agbofinro mu, amọ wọn ti gba beeli rẹ.












