Òkú 54 la ti yọ, a ṣì ń wá èèyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún - NEMA

Àwọn èèyàn nínú ọkọ̀ ojú omi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní Nàìjíríà,Nigeria Emergency Management Agency (NEMA) ti ní òkú èèyàn mẹ́rìnléláàádọ́ta ni àwọn ti rí yọ ní agbègbè tí ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi tó wáyé lọ́jọ́ Ẹtì.

Ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n ni ọkọ̀ ojú omi kan tó kó èrò tó lé ní igba dànù ní agbègbè Dambo-Ebuchi lásìkò tó ń lọ sí ọjà Katcha tí wọ́n máa ń ná ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Niger.

Ọ̀gá àgbà àjọ NEMA ní ìpínlẹ̀ Kogi, Justin Uche sọ fún BBC ní ọjọ́ Àìkú pé àìsí àkọ́ọ́lẹ̀ tó péye lórí àwọn èrò tó wà nínú ọkọ̀ ojú omi náà jẹ́ kó ṣòro láti mọ iye èèyàn tó wà nínú ọkọ̀ ọ̀hún.

Ẹ̀wẹ̀, èèyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún ni wọ́n ṣì ń wá látàrí ọkọ̀ ojú omi tó dànù sínú odò River-Niger ní ìpínlẹ̀ Kogi.

Àwọn òmùwẹ̀ àtàwọn adóòlà ṣì ń ṣiṣẹ́ láti ṣe àwárí àwọn èèyàn tó rì sínú omi náà.

Àtẹ̀jáde láti iléeṣẹ́ gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi, Usman Ododo ní èèyàn mẹ́rìnlélógún ni wọ́n ti rí dóòlà láàyè, tí wọ́n sì ti ń gba ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn.

Àwọn òṣìṣẹ́ ètò pàjáwìrì ṣàlàyé pé òkú èèyàn mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ni àwọn ti rí káàkiri agbègbè tí ìjàmbá náà ti wáyé.

Títí di àsìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ, a kò lè fìdí ohun tó fa ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi náà múlẹ̀, tó sì jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó wà nínú ọkọ̀ ojú omi náà ni kò wọ àṣọ ìdáàbòbò tó yẹ.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Kogi ti rọ àwọn aláṣẹ tó ń mójútó ètò ìrìnnà orí omi ní Nàìjíríà láti máa ṣe àrídájú rẹ̀ pé àwọn èèyàn ń tẹ̀lé ìlànà tó yẹ, kí wọ́n sì máa wọ aṣọ ààbò tó tọ́ lásìkò tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ìrìnàjò gba orí omi.

Ìgbà kẹta rèé tí irúfẹ́ ìjàmbá yìí yóò wáyé láàárín oṣù méjì síra wọn. Ní oṣù Kẹwàá ọdún ni ọkọ̀ ojú omi onípákó kan tó kó èrò tó lé ní ọ̀ọ́dúnrún dànù láàárín gbùngbùn odò River Niger tí èèyàn tó lé ní igba sì pàdánù ẹ̀mí wọn.

Èèyàn méjìléláàádọ́rùn-ún ló pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi náà.

Bákan náà ni èèyàn márùn-ún tún jáde láyé nígbà tí ọkọ̀ ojú omi méjì fi orí sọ ara wọn ní ìpínlẹ̀ Delta.

Irúfẹ́ ìjàmbá yìí wáyé nínú oṣù Kẹfà ọdún tó kọjá níbi tí èèyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún ti jáde láyé.

Ọkọ̀ ojú omi tó kó èrò bíi 200 dojú dé, ọ̀pọ̀ èèyàn pàdánù ẹ̀mí wọn

Aworan ọkọ oju omi

Oríṣun àwòrán, Others

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iroyin to n tẹ wa lọwọ lo sọ pe ọpọ ẹmi lo tun ti ṣofo lẹyin ti ijamba ọkọ oju omi miranm ṣẹlẹ laarọ ọjọ Ẹti lapa Dambo-Ebuchi odo ‘’River Niger’’ ni ipinlẹ Niger.

Iroyin to tẹ wa lọwọ fidi rẹ mulẹ pe ọkọ oju omi onipako ọhun ti ero to le ni igba wa ninu rẹ tawọn to n lọ si ọja atawọn agbẹ ninu wọn n lọ si ọja Katcha ọsọọsẹ ni ijamba naa fi ṣẹlẹ.

A gbọ pe ṣadeedee ni ọkọ oju omi naa doju de ti gbogbo awọn ero to wa ninu rẹ si bọ sinu omi.

O kere tan, oku eeyan mẹjọ ni wọn ti ri yọ ni ninu odo bayii ṣugbọn igbiyanju lati doola ẹmi awọn eeyan si n lọ lọwọ.

Awọn omuwẹ ti n wọ inu omi lati doola ẹmi awọn eeyan to bọ si omi.

Ijọba ipinlẹ Niger ko tii sọ nkan kan lori iṣẹlẹ naa, amọ, ohun ti a gbọ ni pe o ṣee ṣe ki ọpọ awọn ero inu ọkọ oju omi naa ma wọ aṣọ idaabo bo tawọn oloyinbo n pe ni ‘’life jacket’’ ki ijamba ọhun to ṣẹlẹ.

Nnkan bi oṣu kan sẹyin ni ijamba ọkọ oju omi kan ṣẹlẹ loju odo Muwo Gbajibo to wa laarin ijọba ibilẹ Mokwa ati ipinlẹ Kwara.

Ọkọ oju omi ọhun ti ero to to ọdunrun un wa ninu rẹ ṣadeedee doju de laarin odo ‘’River Niger’’ ti eeyan to din diẹ ni igba si padanu ẹmi wọn.

Eeyan mejilelaadọsan ni ori ko yọ ninu ijamba ọkọ ọhun.

Ijamba ọkọ oju omi wọ pọ loju omi kaakiri orilẹede Naijiria.

Iru ijamba yii naa ṣẹlẹ loṣu Kẹfa ọdun to kọja nibi ti eeyan to le lọgọrun un ti padanu ẹmi wọn.