Wo bí o ṣe lè mọ ayédèrú oògùn ibà COMBIART tí àjọ NAFDAC ní ó ti wà lórí igbá káàkiri

Aworan

Oríṣun àwòrán, X/NAFDAC

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ajọ to n mojuto ounjẹ ati oogun lorilẹede Naijiria NAFDAC ti kesi gbogbo ọmọ Naijiria pe ayederu oogun to le ṣe akoba nla fun ilera ti wa lọja.

Oogun ọhun ni wọn pe orukọ rẹ Combiart Dispersible Tablet 20/120mg ni ileeṣẹ Strides Arcolab to wa ni India gbe sita.

NAFDAC ni awọn ri oogun naa niluu Abuja ati ipinlẹ Rivers, ti igbagbọ si wa pe o ti wa kaakiri orilẹede Naijiria.

“Iwadii ti a se lori oogun fihan pe ko ni eroja APIs raa. Bakan naa lo ami meji lara ati akọsilẹ wa fihan pe oogun naa ti bajẹ tipẹ.”

Awọn ewu to rọ mọ lilo oogun Combiart Dispersible Tablet 20/120mg

NAFDAC ni oogun naa lewu fun ẹmi awọn eeyan nitori awọn to sẹda rẹ kọ lati tẹle ofin ati ilana.

Wọn ṣapejuwe gẹgẹ bii eyi ti ko wo aisan kankan, to si tun dakun aisan eyi to le ja si iku.

Awọn nnkan to yẹ ko mọ nipa oogun naa

Orukọ: Combiart Dispersible Tablet 20/120mg

Orukọ ara rẹ: Artemether + Lumefantrine 20/120mg Dispersible Tablet

Nọmba ara rẹ: 7225119

Nọmba NAFDAC: A11-0299

Ọjọ ti wọn sẹda rẹ: Osu kẹfa ati oṣu keji ọdun 2023

Ọjọ ti yoo bajẹ: Oṣu karun un ati oṣu kẹfa ọdun 2026.

Ibi ti wọn se oogun naa Strides Arcolab Limited, 36/7, Suragajakkanahalli, Indlavadi Cross, Anekal Taluk, Bangalore- 562 106, India.

NAFDAC wa rọ awọn araalu ati awọn dokita lati yago fun oogun naa.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Àjọ NAFDAC ayédèrú òògùn tó lé ní ọ̀ọ́dúnrún mílíọ̀nù náírà l’Ékòó

Aworan awọn ogun naa.

Oríṣun àwòrán, NAFDAC NIGERIA/X

Àkọlé àwòrán, Aworan awon oogun naa

Ajọ to n mojuto ounjẹ ati ayẹwo oogun lorileede Naijiria, NAFDAC ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ awọn kan to n ta ayederu oogun fawọn araalu.

Ipinlẹ Eko ni ajọ NAFDAC sọ pe ọwọ awọn ti tẹ awọn eeyan naa, ati pe ayederu oogun ti owo rẹ ko din ni miliọnu lọna ọọdunrun naira ni wọn gba lọwọ wọn lati dana sun.

NAFDAC sọ pe ninu iwadii ti wọn ṣe ni aṣiri naa ti tu si wọn lọwọ, ko to di pe wọn lọ si agbegbe ti wọn n pe ni Tyre Village to wa ninu ọgba Trade Fair Complex, ipinlẹ Eko lati kogun ja wọn.

Ninu atẹjade ti NAFDAC kọ soju opo ‘X’ wọn l’Ọjọbọ, ọsẹ yii, wọn ni oriṣiriṣi oogun ti ọjọ ti lọ lori wọn ni awọn eeyan naa n ta fawọn araalu ti ko da nnkan mọ, leyi ti wọn lo lewu fun ilera.

Lara awọn oogun naa ni wọn pe ni Amoxicillin 500mg, Ampicloxa capsules 500mg, Augmentin capsules 625mg, ati awọn miran.

NAFDAC sọ siwaju pe awọn ti ṣọọbu naa pa, bẹẹ si lawọn ti ko gbogbo oogun ati oniruuru ọja to wa nibẹ kuro.

“Awọn ayederu oogun yii ni owo rẹ to ọọdunrun miliọnu naira, leyi to le ṣakoba fun ilera, ipalara fun itọju, biba ẹya ara jẹ, ati ṣiṣe ilodi si agọ ara.

“Awọn afurasi naa la ti pe fun ibeere ati iwadii, ti iwadii ṣi n lọ lọwọ.”

“Ẹwẹ, ajọ NAFDAC gba awọn araalu lamọran lati maa wa ni ojufo ati ikiyesara, ati pe ki wọn tete fi to ileeṣẹ NAFDAC to ba wa nitosi wọn leti nigba ti wọn ba kofiri ayederu oogun lagbegbe wọn.”