Awuyewuye lórí ẹni tí Ìmáàmú Àgbà fi jẹ Aṣíwájú Mùsùlùmú l'Osogbo, àwọn Alasaro ní Ìmáàmù ti tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀

Aworan aṣoju awọn alasaro, Imaamu Agba ati Alhaji Raji Muniru
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Igbimọ to n ri si fífi Imaamu ati awọn asiwaju ẹṣin musulumi jẹ oyè niluu Osogbo ti wọn n pe ni Alasaro tí fariga lori bi Imaamu agba ilu Osogbo, Alhaji Musa Animasaun ṣe fi Alhaji Raji Muniru jẹ Asiwaju Musulumi ilu Osogbo.

Yoruba bọ wọn ni idalu ni iselu, Amitolu Shittu to jẹ agbenuso fun awọn Alasaro sọ fun BBC Yoruba wi pe asiwaju Musulumi kii ṣe oye idile tabi oye ti wọn eeyan le jẹ ni aafin ọba.

Bakan naa lo sọ pe oye asiwaju musulumi kii se ohun ti wọn le fi oselu ṣe.

Ọgbẹni Shittu ṣalaye pe oye naa eyi to ni ṣe pẹlu oye musulumi gbọdọ wa lati ọdọ awọn Alasaro.

O ni kii se ohun ti Imaamu Agba ilu Osogbo le mu ẹnikẹni lati fi jẹ oye rara.

Ọgbẹni Shittu fikun ọrọ rẹ pe igbimọ Alasaro lo fi Imaamu Agba ti ilu Osogbo funra rẹ jẹ oye.

O ni imaamu ko ni asẹ kankan lati fi ẹnikẹni jẹ oye musulumi bo ti wu ko ri.

''Bi a ba fi eeyan joye ẹṣin kii se bi oloselu to wa ni ìjọba lọwọ lọwọ to le maa ṣe nnkan to wu u.

Imaamu Agba ilu Osogbo fesi sọrọ awọn Alasaro

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba ti BBC Yoruba kan si Imaamu Agba ilu Osogbo, Alhaji Animasaun, o ṣalaye idi ti o fi gbe gbese ati fi Alhaji Raji Muniru jẹ Asiwaju Musulumi ti ilu Osogbo.

''Tunde Badmus ẹni ti gbogbo eeyan mọ si Twins lo sọ fun mi pe, ki n fi Basir Ajibola jẹ Asiwaju Musulumi ti ipinlẹ Osun, ti mo si ṣalaye fun un wi pe, emi naa ni in lọkan lati fun un ni oye tẹlẹ.

Lẹyin naa ni mo fi Alhaji Raji Muniru jẹ Asiwaju Musulumi ti ilu Osogbo.''

Imaamu Agba tun fi kun ọrọ wi pe, ''ki n to gbe igbesẹ yii ni mo ti fi to awọn Alasaro ati gbogbo ẹgbẹ musulumi leti ero ọkan mi lati fi Alhaji Muniru jẹ Asiwaju Musulumi ti iluu Osogbo.

Alhaji Animasaun tun fi kun ọrọ rẹ wi pe, Imaam Agba ni aṣẹ lati fi ẹnikẹni jẹ oye ẹṣin musulumi lai gbaṣẹ lọwọ ẹnikẹni rara.

Imaamu Agba pari ọrọ wi pe, oun ti fun Alhaji Raji Muniru niwe oye asiwaju Musulumi ilu Osogbo o si ti gba lati jẹ oye naa.

Ti ẹ o ba gbagbe, ni nnkan bi ọjọ meloo sẹyin lawọn eeyan ilu Osogbo kan ṣe iwọde tako bi Imaamu Agba ilu naa ṣe fi Alhaji Muniru jẹ oye Aṣiwaju Musulumi ilu Osogbo.