Ayanyemi Atokowagbowonle, àgbẹ̀ tó di gbajúmọ̀ onílù nílùú Ibadan
Ilumọọka onilu ni Atokowagbowonle ni ilu Ibadan lọpọlọpọ ọdun sẹyin. Ohun ti ọpọ n sọ nipa iku rẹ ni pe wọn ṣeku paa ni lasiko ti oun ati awọn ologun jijọ ni ifanfa kan.
Amọṣa, mọ rẹ, Ayanyẹmi Atokowagbowonle ba BBC sọrọ lori rẹ to si ni ahesọ ọrọ patapata ni ohun ti awọn eeyan n sọ nipa iku baba oun

- “Bí a bá mú ajínigbé, tí a sì mú wọn lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan ni wọn yóò tú u sílẹ̀”
- Wo iléẹ̀kọ́ tó ń pèsè ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún àwọn ọmọ aláìní, ṣùgbọ́n tí ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun ní àwọn kò tíi dá a mọ̀
- Ṣó o Láyà: Tunde Kelani kópa nínú ìdánwò tó dá lórí àṣà àti èdè Yorùbá
- Wo yàrá tí Sango Olukoso gbé ní ìlú Igbeti àti ìwádìí BBC Yorùbá nípa rẹ̀
Baba mi fọwọ rọri ku ni, kii ṣe ologun lo pa a – Ayanyẹmi Atokowagbowonle
Iṣẹlẹ iku Atokowagbowonle ti mu ki oniruuru ọrọ o jade nipa ohun to ṣe okunfa iku rẹ. Amọṣa Ayanyẹmi ọmọ rẹ sọ pe ko si nnkan to jọ bẹẹ. O ni ori ibusun ni ileewosan ni baba oun ku si.
“Nigba ti asiko Ọlọrun to fun baba mi, ti wọn maa ku, ọjọ mẹta ni wọn fi ṣe aisan.
“Emi ni mo gbe wọn wa si ile iwosan nla UCH.”
O ni asiko ti wọn n ṣe ayipada owo naira lorilẹede Naijiria ni asiko ti iṣẹlẹ aisan rẹ yii waye.

O ni gẹgẹ bi ẹni to lorukọ lawujọ nigba naa, onirruru nnkan lawọn eeyan n sọ, lati ori pe awọn ṣọja lo la idi ibọn mọ ọ lori.
“Ọlọrun lo mọ iku to pa baba temi. Ori ibusun ti wọn wa ni ile iwosan UCH ni wọn dakẹ si.”
Agbẹ ni Baba mi, oko lo ti n wa sile wa ṣe ere - Ayanyẹmi Atokowagbowonle
“Baba to bi mi ni Atokowagbowonle, agbẹ ni wọn. Ti wọn ko ba ti ni are, wọn n lọ si oko niyẹn. Oko ni wọn yoo ti wa pe wọn.”
Ayanyẹmi Atokowagbowonle ni iṣẹ agbẹ ni oloogbe Atokowagbowonle yan laayo. Nigbakigba ti are ba yọ fun un ni wọn maa n wa sile ti wọn yoo si tun pada.






