Mo bá Salawa Abeni f'ọṣọ rí, mo bá a pọnmọ, kí n tó di ìlúmọ̀ọ́ká - Aweni Waka
Gbajumọ olorin Waka, Alhaja Amudalat Aweni, ti ọpọ mọ si Aweni Waka, ti sọrọ lori bo ṣe bẹrẹ orin kikọ.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu BBC, Aweni sọ pe ọdọ agba olorin Waka, Salawa Abeni, ni oun ti kọ iṣẹ orin kikọ.
O ni ijinlẹ orin waka, to jẹ ti awọn eniyan ilẹ Ijẹbu, ni oun n kọ.
Nigba ti Aweni Waka wa ni ọmọde, lo ti bẹrẹ orin kikọ.
Nipasẹ awọn ẹgbọn rẹ kan to ma n gbọ bo ṣe n kọ orin, si lo fi ni anfaani lati de ọdọ Salawa Abeni.
Lori awọn ahesọ ọrọ kan to n lọ lori ibaṣepọ rẹ pẹlu Salawa Abeni, Alhaja Amudalat sọ pe lootọ ni ko rọrun ki ọmọ’ṣẹ kuro lọdọ ọga rẹ, ko si da duro, o ni amọ ko si ija laarin awọn.
“Mo ba Alhaja ṣa owo, mo ba wọn fọṣọ, mo ba wọn pọn ọmọ, nigba ti mo fi wa lọdọ wọn.”
Amudalat ni gbogbo nnkan ti awọn eeyan n sọ yii, kii ṣe ohun ti oju ko ri ri.
Alhaja Aweni Waka sọ pe igbalode to ti wọ inu orin Waka kikọ, ko tumọ si pe orin naa ti ku.



