Sunday Babatunde, eégún oníná l'Ogbomọṣọ, Danafojura, jáde l'áyé

Aworan eegun Danafojura ati Sunday Babatunde

Oríṣun àwòrán, Ogbomoso Insight/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọjọ Aje, ọjọ kejidinlogun oṣu Kọkanla ọdun yii ni iroyin jade pe Oloye Sunday Babatunde to n gbe eegun Danafojura niluu Ogbomoso ti jade laye.

Gẹgẹ bi ohun ti a gbọ, Babatunde dagbere faye lẹni ọdun mẹrindinlaadọta.

Awọn ẹbi oloogbe naa fidi rẹ mulẹ pe nile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun fasiti Bowen, BUTH, niluu Ogbomoso ni ọkunrin naa dakẹ si.

Ki lo ṣokunfa iku Sunday Babatunde to n gbe eegun Danafojura?

Awọn ẹbi Babatunde sọ fawọn oniroyin pe lọjọ Abamẹta to kọja ni oloogbe naa ṣadeedee yọ ṣubu ni ile iwẹ.

Lati ibẹ ni wọn ti gbe e digba digba lọ si ile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun fasiti Bowen niluu Ogbomoso nibi ti wọn ti bẹrẹ si ni tọju rẹ.

Amọ, gẹgẹ bi ẹbi rẹ sẹ ṣalaye, ana ọjọ Aje ni Babatunde dagbere faye nile iwosan naa.

Ọpọ eeyan lo ti n ṣedaro oloogbe naa lati igba ti iroyin iku rẹ jade.

Babatunde di ẹni to n gbe eegun Danafojura ni nnkan bi ọdun meloo sẹyin lẹyin ti Ifa mu un.

Adari ijọ lo n ṣe ni ṣọọṣi to da silẹ ki o to di ẹni to n gbe egungun Danafojura.

Ọgbẹni Babatunde lo ni ile ọti kan ti orukọ rẹ n jẹ Obureke niluu Ogbomoso nigba aye rẹ.

Ṣaaju, ninu ọdun 2024 yii ni a gbọ wi pe oloogbe naa ṣe oku mama rẹ ni agboole Alakasu niluu Ogbomoso.

Danafojura: Eegun nla to n fi ina wẹ ara

Oniruuru eegun lo wa nilẹ Yoruba, ọtọ leegun ọlọrẹ, bakan naa ni a ni eegun alare.

Ṣugbọn eegun kan to ṣeni ni kayeefi ni eegun Danafojura niluu Ogbomoso.

Pataki lara nnkan kayeefi to n bẹ lara eegun yii ni pe inu ina lo ti n ṣọla.

Eegun yii fẹran ina pupọ, eyi lo si fun lorukọ rẹ, Danafojura.

Agboole Alakasu niluu Ogbomoso ni eegun Danafojura fi sẹ ibuba.

Ẹni to n gbe eegun Danafojura, Oloye Sunday Babatunde, to ti doloogbe bayii sẹ ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba nigba aye rẹ.

Ninu ifọrọwerọ yii ni o ti ṣalaye pe ojubọ Ogun ati Eṣu nibi abẹwo akọkọ ti Danafojura maa n bẹwo to ba n lọ sode.

Oloye Babatunde ni ọjọ meje ni wọn fi n rẹ ẹku Danafojura ko to jade.

Nibo ni eegun Danafojura ti ṣẹ wa?

Oloye Babatunde to ti doloogbe bayii sọ pe ‘’ohun ti a gbọ ninu itan pẹlu Danafojura ni pe lati oju ogun ni wọn ti gbe eegun Danafojura wa.

Ṣugbọn a tun gburo pe Danafojura kan tun wa l’Oyo, amọ, nigba ti a ṣe iwadii lọdọ awọn agbalagba ni wọn sọ fun wa pe awọn baba wa ni wọn ṣẹ eegun naa fun awọn kan l’Oyo, ṣugbọn wọn o fi awọn aṣiri nnkan yoku han wọn.’’

Nigba ti o n sọrọ nipa bi eegun yii ṣe n fi ina wẹ lai jona, Oloye Babatunde ni ‘’aṣiri nla ni ọrọ naa jẹ, awọn baba nla wa nikan lo mọ idi rẹ, awa jogun ba ni.

Ohun ti a kan mọ nibẹ ni pe ẹni ti eegun yii ba mu lati gbe e ko le sọ ohun to pọ lori rẹ ju wi pe ti o ba ti wa ninu ẹku eegun yẹn, otutu a maa mu un, wọn si maa dana si i lara.

Bi wọn ba si ti n dana si i lara ni otutu naa yoo maa dinku.''