Gómìnà tí wọ́n dìbò yàn nípìnlẹ̀ Ondo, Lucky Aiyedatiwa, bá aráàlú sọ ọ̀rọ̀ àkọ́sọ

Àkọlé fídíò, Lucky Aiyedatiwa wọle ibo gomina ipinlẹ Ondo
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gomina Lucky Aiyedatiwa, ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan ni ipinlẹ Onod fun saa ọlọdun mẹrin mii, ti dupẹ lọwọ awọn eniyan ipinlẹ naa to dibo yan an.

Ninu ọrọ to ba BBC sọ, Aiyedatiwa kesi awọn ti wọn jọ dupo, amọ to fidirẹmi lati darapọ mọ iṣakoso rẹ, ki wọm o si jọ ṣiṣẹ ilu.

Ninu gbogbo oludije mejidinlogun to dupo gomina ipinlẹ Ondo ni 2024, Lucky Orimisan Aiyedatiwa, ti jawe olubori.

Aiyedatiwa to dije ninu ẹgbẹ oṣelu APC, ni yoo maa tukọ ipinlẹ Ondo lọ gẹgẹ bo ṣe n ba a bọ lẹyin iku gomina tẹlẹ, Oloogbe Rotimi Akeredolu ni ọdun 2023.

Lati ọjọ Satide, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla ti idibo naa ti waye ni oye ti n foju han, pe Aiyedatiwa ni ipo naa yoo ja mọ lọwọ.

Eyi ri bẹẹ pẹlu bi gomina naa ṣe n fi ẹyin alatako rẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, Agboola Ajayi, lulẹ pẹlu awọn oludije yooku.

Lẹyin ti ajọ eleto idibo, INEC, ka gbogbo ibo ijọba ibilẹ mejidinlogun to wa l’Ondo tan ni wọn kede pe Lucky Orimisan Aiyedatiwa ni gomina Ondo tuntun.

Lapapọ ibo 366,781 ni Aiyedatiwa ni, nigba ti Agboola, oludije PDP to ṣe ipo keji ninu eto idibo naa ni 117,845.