Kókó nípa Lucky Aiyedatiwa tó wọlé ìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo

Oríṣun àwòrán, Lucky Aiyedatiwa/Facebook
Ninu gbogbo oludije mejidinlogun to dupo gomina ipinlẹ Ondo ni 2024, Lucky Orimisan Aiyedatiwa, ti jawe olubori.
Aiyedatiwa to dije ninu ẹgbẹ oṣelu APC, ni yoo maa tukọ ipinlẹ Ondo lọ gẹgẹ bo ṣe n ba a bọ lẹyin iku gomina tẹlẹ, Oloogbe Rotimi Akeredolu ni ọdun 2023.
Lati ọjọ Satide, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla ti idibo naa ti waye ni oye ti n foju han, pe Aiyedatiwa ni ipo naa yoo ja mọ lọwọ.
Eyi ri bẹẹ pẹlu bi gomina naa ṣe n fi ẹyin alatako rẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, Agboola Ajayi, lulẹ pẹlu awọn oludije yooku.
Lẹyin ti ajọ eleto idibo, INEC, ka gbogbo ibo ijọba ibilẹ mejidinlogun to wa l’Ondo tan ni wọn kede pe Lucky Orimisan Aiyedatiwa ni gomina Ondo tuntun.
Lapapọ ibo 366,781 ni Aiyedatiwa ni, nigba ti Agboola, oludije PDP to ṣe ipo keji ninu eto idibo naa ni 117,845.
Ta a ni Lucky Orimisan Aiyedatiwa?

Oríṣun àwòrán, LUCKYAIYEDATIWA/X
Wọn bi Lucky Orimisan Aiyedatiwa ni ọjọ kejila, oṣu Kin-in-ni ọdun 1965.
Alagba Titus Akande ati Abilekọ Rosanah Moyebi Aiyedatiwa ni awọn obi rẹ.
Ilu Obe-Nla, nijọba ibilẹ Ilaje, nipinlẹ Ondo ni wọn ti bi i.
Laarin ọdun 1970 si 1976, Aiyedatiwa lọ si ile ẹkọ Saints Peter, niluu Obe-Nla/Obe Adun, niluu Ilaje, fun ẹkọ alakọọbẹrẹ.
Bakan naa lo lọ sile ẹkọ Girama Ikosi, ni Ketu, nipinlẹ Eko.
Aiyedatiwa tun morile ile ẹkọ giga Adeniran Ogunsanya, Ijanikin, nipinlẹ Eko, ni ọdun 1986, nibi to gba oye ninu imọ iṣiro ati iṣejọba.
Lucky Aiyedatiwa figba kan ṣe tiṣa ri, ko too bẹrẹ okoowo ara rẹ ni 1996.
Ni 2001 ni Aiyedatiwa lọ si Yunifasiti ilu ibadan, fun ẹkọ si i nipa okoowo. Ko too lọ si Lagos Business School – Pan Atlantic University, nibi to ti gba oye Chief Executive Education (CEP) ninu imọ okoowo.
2013 lo gboye agba,(Masters) ninu ẹkọ nipa okoowo. Yunifasiti Liverpool, ni United Kingdom, lo ti gba a .
Ọdun 2011 lo darapọ mọ oṣelu, nigba to di ọmọ ẹgbẹ Action Congress, (ACN) to pada waa di APC ni 2014.
Ni 2015, Lucky Aiyedatiwa ni aṣoju Ilaje/Ese-odo fun ile igbimọ aṣoju l’Abuja.
Lati 2004 titi di 2010, Lucky ni alukoro apapọ fun ẹgbẹ awọn abaniṣẹwo(Association of Bureau De Change Operators of Nigeria (ABCON).
Oun naa si ni alaga ẹkun Guusu-Iwọ-Oorun ABCON lati 2010 si 2011.
Aarẹ tẹlẹ ni Naijiria, Muhammadu Buhari, yan Aiyedatiwa gẹgẹ bii kọmiṣanna to n ri si idagbasoke agbegbe Niger Delta( NDDC) laaarin 2018 si 2019.
Ninu oṣu keji ọdun 2021, wọn bura fun Akeredolu ati Aiyedatiwa gẹgẹ bii gomina ati igbakeji l’Ondo, lẹyin ti wọn yege ninu ibo ọdun 2020.
Nigba to di 2023, ẹẹmeji ni Aiyedatiwa di adele gomina Ondo.
Akọkọ ninu oṣu Keje, nigba ti Oloogbe Akeredolu n ṣe aisan. Ikeji si ni oṣu Kejila ọdun naa, nigba ti Akeredolu dagbere faye latari aisan jẹjẹrẹ.
Ni bayii, Aiyedatiwa ti di ojulowo gomina to lẹtọọ si ọdun mẹrin lori aleefa gẹgẹ bii gomina adiboyan nipinlẹ Ondo.
Gomina Aiyedatiwa ni iyawo ati awọn ọmọ.












