Ìwà àjẹbánu ló mú ìfàsẹ́yìn bá Naijiria lábẹ́ ìṣàkóso ‘Baba-go-slow' àti Emilokan - Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ tẹlẹ ni Naijiria, Oloye Olusegun Obasanjo, ti so pe iwa ajẹbanu, magomago, èrú ati bẹẹ bẹẹ lọ lo mu ifasẹyin ba orilẹede yii.
Obasanjo sọ pe paapaa labe iṣakoso ‘Emi lo kan ati Baba-go-slow.’
Bẹẹ lo ni awọn olori ni ipilẹ iṣoro Naijiria pata.
Nibi ayẹyẹ iranti agba onkọwe, Chinua Achebe, to waye lorilẹede America ni Obasanjo ti sọrọ yii.
Obasanjo to wa lorilẹede Congo lasiko ti ayẹyẹ naa n waye lopin ọsẹ, ṣalaye ninu fi ranṣẹ, pe bi awọn olori ba ṣe n kuna lorilẹede kan si, ti ajẹbanu wọn n pọ si i, bẹẹ naa ni ilu naa yoo maa jin sinu idaamu, aisi aabo, idarudapọ, iwa ipanle, idaluru ati aini idagbasoke.
“Gẹgẹ bo ṣe han si gbogbo aye, ipo to buru gbaa ni Naijiria wa bayii.
“Bi nnkan ṣe ri lasiko yii ni Naijiria, aigbọra ẹni ye ati aisi iṣọkan pọ nilẹ. Idaamu ọkan, aifarabalẹ awọn ọdọ, aini idagbasoke, gbogbo ẹ lo n ṣẹlẹ
“Bo ṣe ri kari niyẹn ni Naijiria lasiko ijọba Baba-go-slow ati Emi lo kan.”
Ọbasanjọ lo ṣalaye bẹẹ.
‘Kò sí ohun tó ń ṣe Naijiria, àwọn olórí ló kọ̀ láti ṣe ojúṣe wọn’
Nigba to n tẹsiwaju, Oloye Obasanjo sọ pe ko si kinni kan to n ṣe Naijiria, bo tilẹ jẹ pe o wa ninu iṣoro.
Aarẹ tẹlẹ naa sọ pe oju ọjọ daa lorilẹede yii, o ni awọn olori to kọ lati ji giri si ojuṣe wọn.
“Ohun to n ṣẹlẹ niṣoju wa ni Naijiria yii jẹ imunilẹru, ki ilu wa ninu igbekun, ki ohun gbogbo nira.
“Ofin ilẹ yii ati ti agbaye gbọdọ de awọn oloṣelu to n ko ogún ilu si apo wọn nikan.
Ati bi wọn ṣe n pin ẹtọ orilẹede fun ẹbi ati awọn eeyan wọn lowo pọọku ni gbogbo ẹka.’’
Bẹẹ ni Obasanjo wi.
Ìrètí ṣì wà
Gẹgẹ bi Obasanjo ṣe wi, o ni ireti ṣi wa fun Naijiria lati bọ lọwọ idaamu olori.
Aarẹ tẹlẹ naa sọ pe ìyà ti Naijiria n jẹ yii waye lati ara ajẹbanu to kari, aikunju oṣuwọn, aiṣe ẹtọ, aisi idajọ ododo, ṣiṣe ohun gbogbo radarada ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ṣugbọn pẹlu bi gbogbo rẹ ṣe ri yii naa, Obasanjo ṣalaye pe ireti ṣi wa pe nnkan yoo pada daa.














