Bí Chdinma Adetshina, ọmọ Naijiria ṣe ṣe ipò Kejì ní ìdíje Miss Universe 2024

Chidinma Adetshina

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Chidinma Adetshina nikan ni ọmọ Africa to wa laarin awọn marun un to de aṣekagba
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Kii ṣe wahala ati idaamu kekere ni arẹwa obinrin arinrin oge, Chidinma Adetshina, ko to ṣe ipo krji ninu idije Miss Universe 2024.

Idije Miss Universe ni wọn ti n yan omidan to rẹwa julọ ni agbaye.

Ṣaaju ikede rẹ gẹgẹ bi ẹni to ṣe ipo keji, Chidinma wa laarin awọn marun-un to tayọ julọ ninu idije naa to waye ni orilẹ-ede Mexico. Bakan naa, oun nikan ni ọmọ Africa to wa laarin wọn.

Miss Universe 2024 ni ikẹtalelaadọrin iru idije naa ti yoo waye, nibi ti awọn omidan lati aadoje orilẹ-ede ti kopa.

Lootọ ni Chidinma Adetshina ṣe daadaa ni gbogbo ipele ti wọn la kọja, ṣugbọn Omidan Victoria Kjaer lati Denmark lo gba ade.

Ẹni to gba ade lọdun to kọja, Sheynnis Palacious lati Nicaragua si lo gbe ade le omidan tuntun lori.

Awọn omidan to wa ni ipo marun-un akọkọ

  • Victoria Kjaer- Denmark (Ẹni to gba ade)
  • Chidinma Adetshina- Nigeria (Ipo Kinni)
  • Maria Fernanda Beltran- Mexico (Ipo Keji)
  • Suchata Chuangsri- Thailand (Ipo Kẹta)
  • Ileana Marquez- Venezuela (Ipo Kẹrin)
Victoria Kjaer lati Denmark lo gba ade

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Victoria Kjaer lati Denmark lo gba ade

Tẹ o ba gbagbe, ẹ o ranti pe Chdinma yọwọ kuro ninu idije omidan to rẹwa julọ ni orilẹ-ede south Africa, nitori awọn wahala kan to koju lori boya ọmọ ilu ni tabi bẹẹ kọ.

Eyi ko ṣẹyin bi orirun rẹ ṣe jẹ orilẹ-ede Naijiria, botilẹ jẹ pe South Africa ni wọn bi i si.

Iṣẹlẹ yii mi ori ayelujara, ti ọrọ naa si fẹ ẹ da ija ẹlẹyamẹya silẹ laarin awọn ọmọ Naijiria ati South Africa.

Awọn to n ṣe amojuto idije Miss Naijiria gba Chidinma mọra, to si bori ninu idije naa.

Eyi lo fun ni anfaani lati ṣoju Naijiria ni agbaye.

Lẹyin ti Chdinma kuro ninu idije naa, ni Mia Le Roux gba ade gẹgẹ bii Miss South Africa 2024.

Le Roux si lo ṣoju orilẹ-ede ọhun ni idije Miss Universe 2024.

Amọ o ni oun ko kopa mọ ṣaaju ki idije naa to wọ aṣekagba.

Eyi ni awọn alaṣẹ Miss Universe South Africa sọ pe ko ṣẹyin eto ilera rẹ.

Bi wọn ṣe ma n yan olubori

Oludije bi aadoje lo kopa ni Miss Universe 2024 to waye ni Mexico.

Lati ipari oṣu Kẹwaa si ni wọn ti bẹrẹ, ti wọn si n kopa ninu oriṣiriṣi ayẹyẹ, idanwo, irinajo afẹ ati awọn nnkan mii lati ọjọ kinni, oṣu Kọkanla.

Awọn omidan idije Miss Universe 2024

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọjọ kẹrinla, oṣu Kọkanla ni wọn ṣe ipele to kangun si aṣekagba, ọjọ naa si ni wọn ṣe afihan aṣọ ibilẹ orilẹ-ede ẹnikọọkan.

Lara awọn ọna ti wọn n gba yan olubori ni idibo bọ si awọn ipele to kẹyin.

Bakan naa, idije aṣọ to gbayi julọ ma n waye, nibi ti awọn oluworan naa ti ma n ni anfaani lati dibo.

Lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kejila, aṣ ti eeyan le fi luwẹẹ ninu omi ni awọn olukopa wọ fi rin irin oge. Ipele si ni mejidinlogun lara wọn ti ja danu.

Awn mejila to ṣẹku ni ipele yii pada wọ aṣọ oge , nibi ti meje miran tun ti fidirẹmi.

Omidan marun-un to ṣẹ ku lo kopa ni aṣekagba, nibi ti wọn ti dahun oriṣiriṣi ibeere lọwọ awọn ọmọ igbimọ oluṣakoso.

Lẹyin awọn ibeere yii ni wọn kede olubori ati awọn to tẹle e.