Orísun wàhálà mi bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tí mo gba àmì ẹ̀yẹ obìnrin tó múra dáadáa jùlọ - Bobrisky

Aworan Bobrisky

Oríṣun àwòrán, Bobrisky/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Idris Okuneye ti ọpọ mọ si Bobrisky ọkunrin to maa n ṣe bi obinrin ti sọ pe lati igba toun ti gba ami ẹyẹ obinrin to mura daadaa julọ ni oun ti n koju iṣoro lọkan o jọkan.

Bobrisky fi ọrọ yii lede loju opo ayelujara rẹ lọjọ Ẹti.

Gbajumọ ori ayelujara naa ni oun ko ni bawọn debi ti wọn ti n fawọn eeyan ni ami ẹyẹ obinrin to mura daadaa julọ mọ laye oun.

Laipẹ yii ni awọn oṣiṣẹ ajọ NIS to n ri si iwọle-wọde arinrinajo lorilẹede Naijiria mu Bobrisky ni ẹnu ibode Seme lasiko to fẹẹ sa kuro ni Naijiria lọ si oke okun.

Ninu atẹjade kan ti ajọ NIS fi sita ni ajọ ọhun ti sọ pe awọn fi ọrọ wa Bobrisky lẹnu wo lo jẹ kawọn mu un.

Lẹyin o rẹyin, ajọ NIS pada fi Bobsriky silẹ, o si tẹsiwaju irinajo rẹ lọ si oke okun nibi to wa lati igba naa.

Nigba to n sọrọ loju opo Facebook rẹ, Bobrisky ni gbogbo eeyan lo mọ pe oun gbafẹ gan an, ati pe ko sẹni to le ba oun ṣe orogun.

Amọ, o ni nigba ti wahala fẹẹ pọju foun lo jẹ fi ilu silẹ.

Skip Facebook post
Allow Facebook content?

This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Facebook post

Ki lo mu Bobrisky sa kuro ni Naijiria?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iroyin ọlọkan-o-jọkan lo n jade nipa Bobrisky lati igba ti ile ẹjọ ti dajọ ẹwọn oṣu mẹfa fun un.

Akọkọ ni ẹwọn rẹ naa ti wọn ni ko ṣe rara, bẹẹ ni awuyewuye tun jade pe inu ile adagbe kan ni Bobrisky wa, to n ṣe faaji rẹ fun oṣu mẹfa gbako.

Fọnran ohun ti wọn tun ni ti Bobrisky ni, eyi to n kede pe oun san miliọnu mẹẹeẹdogun naira koun maa ba ṣẹwọn, naa tun jẹ idi kan ti ọkan Okuneye Idris ko fi balẹ rara.

Ninu fidio kan ti Bobrisky funra rẹ fi sori ayelujara lo ti n bẹ awọn eeyan, pe ki wọn fi oun lọrun silẹ.

O ni ''ṣe oun nikan ni gbajumọ to wa ni Naijiria ni, to fi jẹ pe ọrọ gbogbo ki i se lori alabahun oun.''

Bakan naa ni abọ iwadii igbimọ ti Minisitra fun ọrọ abẹle, Olubunmi-Tunji Ojo gbe kalẹ, fihan pe Bobrisky ni anfaani si tẹlifiṣan ati awọn eeyan to n ran niṣe lọgba ẹwon to wa.

Wọn lo jẹ anfaani ounjẹ to wu u, o si tun ri ẹrọ firiiji lo ninu ẹwọn rẹ.

Gbogbo eyi ni awọn eeyan n sọrọ nipa rẹ, ti wọn si n bu ẹnu atẹ lu Idris ati ijọba paapaa.

Eyi ni a gbọ pe o ṣee ṣe ko ka Bobrisky laya soke, to fi yẹra fun Naijria fun igba diẹ na.