Yọkọlú yọkọlú, gbajúmọ̀ orí YouTube, Jake Paul fẹ̀ṣẹ́ àlùwó la Mike Tyson mọ́lẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Alagbara ṣubu, ohun ija ṣegbe bi gbajumọ ori itakun ayelujara YouTube, Jake Paul ṣe fi ẹṣẹ gbe Mike Tyson lulẹ ninu ija to waye laarin awọn mejeeji lalẹ ọjọ Ẹti ni Texas lorilẹede Amẹrika.
Abajade ija naa jẹ iyalẹnu fun ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu awọn eeyan to wo ija ọhun kaakiri agbaaye.
Nnkan o rọrun rara fun Tyson, ẹni ọdun mejidinlọgọta ti ko tii ja ija kankan pẹlu awọn to n fi ẹṣẹ kikan ṣe iṣẹ fun ọdun mọkandinlogun.
Amọ, Paul ni tiẹ to jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn fakọyọ ninu ija ọhun tori eegun ọdọ si wa lara rẹ.
Niṣe ni o n fi ẹṣẹ ranṣẹ si Tyson lati ọọkan ti ko si jẹ ki o sun mọ oun.
Tyson ko yara mọ bi igba to fi wa ni Sango- Ode tori ọjọ ori rẹ.
Amọ, awọn ololufẹ rẹ n ki i ni mẹsan an mẹwaa bi o ti fẹ wọ inu ibi ti wọn ti fẹ ja lọ.
Ṣugbọn ariwo huu-huu lo sọ laarin awọn oluworan nigba ti ija naa n pari lọ.
Lẹyin ti wọn ja ija naa tan lawọn adajọ sọ pe Paul lo gbegba oroke pẹlu ami ayo 80-72, 79-73 ati 79-73.
Lẹyin ti ija naa pari ni Tyson pe buọda Logan to jẹ Paul wi pe oun si tun le ba Paul ja lẹẹkan sii.
Ẹṣẹ mejidinlogun pere ni Tyson ri gba alatako rẹ ninu ija ọhun nigba ti Paul si gba Tyson ẹṣẹ mejidinlọgọrin.
Nipa fifi fidio to le pani lẹrin-in sori ayelujara ni Paul ti di ilumọọka debi tawọn aadọrin miliọnu fi n tẹle e ki o to bẹrẹ ẹṣẹ kikan.















