Wo iye ìbò tí olùdíje kọ̀ọ̀kan ní láwọn ìjọba ìbílẹ̀ nínú ìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo

Oríṣun àwòrán, Lucky Aiyedatiwa/Agboola Ajayi/Facebook
Bi idibo si ipo gomina ṣe waye nipinlẹ Ondo ni Satide, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla ọdun 2024, bẹẹ naa ni awọn esi kan ti n jade.
Ibudo idibo to din diẹ lẹgbẹrun mẹrin (3,933) ni idibo ti waye kaakiri ijọba ibilẹ mejidinlogun to wa nipinlẹ Ondo.
Lapapọ, eeyan to le ni miliọnu meji (2,053,061) lo fi orukọ silẹ ṣaaju idibo, ṣugbọn ẹgbẹrun mẹrinlelọgọta ati diẹ (64,273) lo gba kaadi idibo lati dibo, ninu kaadi 89,777 to wa fun ipinlẹ naa.
Bo si tilẹ jẹ pe oludije mejidinlogun lo kopa kaakiri awọn ẹgbẹ oṣelu to wa, esi to n jade fi han pe laaarin APC ati PDP nikan ni onka to lapẹẹẹrẹ ti n waye.
Gomina Lucky Aiyedatiwa to n tukọ Ondo lọwọlọwọ, jẹ ọmọ ẹgbẹ APC, nigba ti Agboola Ajayi n dije lati PDP.
Ẹni to wa nidii onka ibo naa, Ọjọgbọn Olayemi Akinwunmi; ọga agba ni Yunifasiti ijọba apapọ to wa ni Lokoja, bẹrẹ akojọpọ naa lalẹ ọjọ Satide ti idibo waye.
Eyi ni alakalẹ awọn esi idibo naa lati ijọba ibilẹ kan si ikeji nipinlẹ Ondo.

Oríṣun àwòrán, Others
Ifedore
Awọn to forukọ silẹ lati dibo: 83831
Awọn ti wọn ṣe ayẹwo orukọ wọn: 21024
APC 14157
LP 19
PDP 5897
Ila-Oorun Ondo (Ondo East)
Awọn to forukọ silẹ lati dibo : 52274
Awọn ti wọn ṣe ayẹwo orukọ wọn: 11864
APC 8163
LP 31
PDP 2843
Ile Oluji/Oke Igbo
Awọn ti wọn forukọ silẹ lati dibo: 81954
Awọn ti wọn ṣe ayẹwo orukọ wọn: 22256
APC 16600
LP 23
PDP 4442
Idanre LGA
Awọn ti wọn ṣe ayẹwo orukọ wọn: 19712
APC 9114
LP 24
PDP 8940
Irele
Awọn to forukọ silẹ: 78982
Awọn ti wọn ṣe ayẹwo orukọ wọn: 24772
APC 17117
LP 15
PDP 6601
Guusu-Iwọ-Oorun Akoko (Akoko Southwest)
Awọn to forukọ silẹ: 116368
Awọn ti wọn ṣe ayẹwo orukọ wọn: 36300
APC 29700
LP 16
PDP 5517
Ìjọba ibilẹ Owo
Awọn to forukọ silẹ: 143751
Awọn ti wọn ṣe ayẹwo orukọ wọn: 38340
APC 31914
LP 42
PDP 4740
Ìwọ̀-Oorun Ondo (Ondo West)
Awọn to forukọ silẹ: 190666
Awọn ti wọn ṣe ayẹwo orukọ wọn: 31418
APC 20755
LP 181
PDP 6387
Guusu-Ila-Oorun Akoko (Akoko Southeast)
Awọn to forukọ silẹ: 41978
Awọn ti wọn ṣe ayẹwo orukọ wọn: 15150
APC 12140
LP 10
PDP 2692
Ariwa Iwọ-Oorun Akoko (AkokoNorthwest)
Awọn to forukọ silẹ: 84908
Awọn ti wọn ṣe ayẹwo orukọ wọn: 31263
APC 25010
LP 23
PDP 5502
Ijọba ibilẹ Ose
Awọn to forukọ silẹ: 78307
Awọn ti wọn ṣe ayẹwo orukọ wọn: 21661
APC 16555
LP 06
PDP 4472
Guusu Akure (Akure South)
Awọn to forukọ silẹ: 314709
Awọn ti wọn ṣe ayẹwo orukọ wọn: 54670
APC 32969
LP 238
PDP 17926
Ariwa-Ila-Oorun Akoko ( Akoko Northeast)
Awọn to forukọ silẹ: 93285
Awọn ti wọn ṣe ayẹwo orukọ wọn: 31734
APC 25657
LP 14
PDP 5072
Ijọba ibilẹ Okitipupa
Awọn to forukọ silẹ: 126021
Awọn ti wọn ṣe ayẹwo orukọ wọn: 38814
APC 26811
LP 27
PDP 10233
Ariwa Akure (Akure North)
Awọn to forukọ silẹ:
Awọn ti wọn ṣe ayẹwo orukọ wọn: 21608
APC 14451
LP 238
PDP 5787














