Tọkọtaya sọ ìrírí wọn lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí wọ́n ṣe ìgbéyàwó Awonga Shao
Àjọdun 'Àwọ́nga Shao' ni wọn n pe eto igbeyawo ajumọṣe yii ni ìlú Shao ni ipinlẹ Kwara ni eyi ti wọn maa n ṣe lọdọọdun lati fi sin ọpọlọpọ ọmọbinrin wọn lọ sile ọkọ lọjọ kan naa.
Gbogbo ìlú lọ máa sin iyawo ọ̀sìngín ni Shao ni Kwara lọ sile ọkọ tìlù tìfọn pẹlu ijo àti ayọ láìyọ yínyin ìbọn àwọn ọdẹ akọni sílẹ̀.
Ni ọdun mẹwaa sẹyin ni tọkọtaya Abioye ati Taiwo Ọladunni wa lara awọn to kopa ninu igbeyawo Awọnga Shao yii.
Nigba ti BBC ṣe alabapade wọn lasiko ọdun Shao ti ọdun 2024, pẹlu idunnu lawọn mejeeji fi n kaakiri pẹlu awọn olukopa yoku.
Wọn ni inu awọn dun gidigidi pe lẹyin ọdun mẹwaa, igbeyawo awọn ṣi duro deede.
Ọgbẹni Abioye Ọladunni ni igbeyawo naa ko tii sọ iyi ati ẹyẹ to rọ mọọ nu, pẹlupẹlu bi ọlaju ati ẹsin okeere ti ṣe ko ọpọlọpọ ipa ninu eto igbeyawo ọpọ ọdọ lode oni.
Iyawo rẹ, Taiwo Ọladunni pẹlu kin ọkọ rẹ lẹyin: “Igbeyawo Awọnga ti a n ṣe lọdọọdun, dandan ni, dandan si tun kọ. Nitori pe lasiko awọn iya to bi awọn iya wa, bi wọn ba fẹ ṣe iyawo, ọjọ kan ṣoṣo ni wọn maa n ṣe e nigba yẹn.”
O ni ọlaju to de ti mu ki awọn kan ti wọn n lọ ṣọọṣi tabi mọṣalaṣi. ‘ṣgbọn awọn to ba fẹ ṣe igbeyawo abalaye yoo ṣe igbeyawo Awọnga.
Arabinrin Ọladuni ni lodi si ohun ti ọpọ maa n sọ pe aifẹ na owo lo n mu wọn ṣe igbeyawo lọpọ ero ti wọn n pe ni awọnga Shao.
O ni ẹni to ti bimọ ati ẹni ti ko tii bi lo le kopa ninu igbeyawo Awọnga Shao.
Bi Ọdun Awonga ṣe bẹrẹ to si di ayẹyẹ ọdọọdun

Ọdun Awonga jẹ ọdun to ti wa lati gba iwasẹ to si ni itumo kikun si awọn eniyan.
Gẹgẹ bi itan, ọdun yii bẹrẹ pẹlu obinrin kan ti orukọ rẹ njẹ Awọn, ti o gba ọna ara yọ si ọdẹ kan ti wọn n pe ni, Omo Olarele.
O si sọ fun un pe oun ni o ni odo ti ọdẹ naa ti ma n mu omi ni gbogbo igba to ba lọ sọdẹ.
Awọn jẹ obìnrin ọlọmu kan, o si beere fun ohun kan pere lọwọ ọdẹ naa.
O ni ki o gbe oun lọ si aafin Ọhọrọ iluu Shao akọkọ, Oba Olanibo, o si gba sii lẹnu.
Lẹyin ọpọlọpọ ipade ti Awon se pẹlu Ọhọrọ ati awon ijoye rẹ, o poora pada.
Sugbọn ki o to lọ, o fun wọn ni oogun kan, o si pa a lasẹ wi pe ki wọn sọ ilu naa ni orukọ oun.
Bakan naa, o ni ki wọn ya ọjọ kan sọtọ ninu ọdun fun iranti oun ati lati se igbeyawo fun gbogbo awon ọmọ obinrin to ti to ile ọkọ lọ ni ọjọ kan naa.
Itan tun fi kun un pe, Awon ṣe ileri ibukun fun gbogbo ọmọ ilu ati alejo ti wọn ba tẹle awon ilanaa rẹ.
O sọ wi pe ki wọn maa beere ohun gbogbo ti wọn ba n fẹ ni igbakuugba, papaa julọ, bi ọjọ bayii ti wọn se ọdun Awon.
Lati igba naa ni fífi awọn ọmọbìnrin fun ọkọ lọjọ Ọdun Awonga o si ti di etutu ati ara asa ati ise iluu Shao, ti wọn si n pe ilu naa ni Shao Awonga






