Peller, gbajúmọ̀ Tiktok ṣàlàyé àṣírí àjọṣepọ̀ 'ọ̀rọ̀ ìfẹ́' tó wà láàrín òun àti Jarvis

Àkọlé fídíò, Peller, gbajúmọ̀ orí ayélujára ṣàlàyé àṣírí àjọṣepọ̀ tó wà láàrín òun àti
Peller, gbajúmọ̀ Tiktok ṣàlàyé àṣírí àjọṣepọ̀ 'ọ̀rọ̀ ìfẹ́' tó wà láàrín òun àti Jarvis

Oniruuru iroyin lo ti n jade kaakiri ṣaaju asiku yii nipa Eekan ori ayelujara Tiktok atawọn oju opo ayelujara miran, Habeeb Hazmat ti ọpọ mọ si Peller, ati Elizabeth Amaduo ti ọpọ mọ si Jarvis nipa ajọṣepọ to n waye laarin wọn.

Ohun ti ọpọ iroyin yii n sọ ni pe ọrọ sunukun ifẹ n lọ laarin awọn gbajumọ ọdọ mejeeji yii.

“Mo nifẹ Jarvis, amọ...”

Aworan Peller ati Jarvis

Oríṣun àwòrán, Peller

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba, Peller ṣalaye pe kini ọun jọ gate o si jọ gate o fi ẹsẹ mejeeji tiro lọdọ oun nitori ti a ba ni ki a wo iha ti oun kọ si ọdọmọbinrin naa, oun ‘nifẹ rẹ’.

Peller ṣalaye pe, nigba ti oun kọkọ bẹrẹ si ni fi ifẹ oun han an, o kọkọ ro wi pe ere loun n ṣe ni ati pe, o n wo ọjọ ori awọn mejeeji nitori pe Jarvis ju oun lọ lọjọ ori.

“O maa n dun un lọkan pe ọmọ kekere leleyii, emi o dẹ ki n ṣe ọmọde rara. Ọmọ ogun ọdun ni mi, idi niyi ti ko fi gba.”

Mi o lo Jarvis, Jarvis naa o dẹ lo mi – Peller

Aworan Jarvis ati Peller

Oríṣun àwòrán, screenshot

Nigba to n fesi si awọn ọrọ abẹle kan ti awọn kan n sọ kiri pe, o n lo gbajumọ Jarvis lati fi mu ki okiki rẹ ru gọgọ sii lori ayelujara, Peller ni ko si nnkan to jọ ọ rara.

O ni bi oun o ṣe lo irawọ rẹ ni Jarvis pẹlu o fi igba kankan lo irawọ toun naa.

“Mi o lo ẹnikẹni, eeyan kankan o dẹ lo mi, a o lo ara wa.”

O ni ko tii bẹrẹ si ni ṣe bii ẹrọ igbalode AI nigba ti oun ati ẹ ti mọra ti awọn si ti jọ n ṣe pọ.

Ki lo wa ba ifẹnukoraẹnilẹni de nibi eto igbami ẹyẹ?

Peller ati Jarvis fi ẹnu ko ara wọn lẹnu.

Oríṣun àwòrán, screenshot

Ni ọsẹ kan sẹyin ni Peller gba ami ẹyẹ meji kan gẹgẹ bii ilumọọka to ta lẹnu jul lori Tiktok nibi ti awọn mejeeji ti fi ẹnu ko ara wọn lẹnu.

Amọṣa, nigba to n ba BBC sọrọ lori ohun to ṣẹlẹ gan, Peller ṣalaye pe, kii ṣe wi pe Jarvis fẹ fi ẹnu ko oun lẹnu nitootọ nigba naa.

“Ṣe ifẹnukonu niyẹn ni. O fẹ fi ẹnu ko mi lẹrẹkẹ ni, emi kan ṣe bayii ni ete rẹ kan ba mi ni ete diẹ.”

O ni ifẹnukonu maa n gbona ju eyi ti awọn ṣe loju agbo lọjọ naa lọ.