Ìjọba àpapọ̀ ẹ gbá wá lórí ọ̀ná Ogbomoso tó ń fi ẹ̀mí àti dúkìá ṣòfò, Soun, aráàlú àtàwọn oníṣòwò ké gbàjarè

Àkọlé fídíò, Súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ l'Ogbomoso látàrí ọ̀nà tó ti bàjẹ́
Ìjọba àpapọ̀ ẹ gbá wá lórí ọ̀ná Ogbomoso tó ń fi ẹ̀mí àti dúkìá ṣòfò, Soun, aráàlú àtàwọn oníṣòwò ké gbàjarè

Kabiyesi Soun ilu Ogbomoso, Ọba Ghandi Afolabi Olaoye, Kọmiṣọna eto iroyin ni ipinlẹ Oyo, Ọmọba Dotun Oyelade, awọn araalu Ogbomoso atawọn oniṣowo ti kepe ijọba apapọ lati wa nkan ṣe si ọna aarin ilu Ogbomoso to ti bajẹ tan eyi ti wọn lo n fi ọpọ ẹmi ati dukia ṣofo.

Ọna yii ni iṣẹ ti bẹrẹ lori rẹ lati bii ọdun mẹẹdọgbọn sẹyin ti ijọba apapọ ko si tii pari rẹ titi di akoko yii.

Kabiyesi Soun ilu Ogbomoso sọ pe o yẹ ki ijọba apapọ ṣe awọn ọna kan to ni sẹ pẹlu idagbasoke ilu ninu eyi ti ọna to wa lati ilu Oyo si Ogbomoso wa ninu rẹ.

Kabiyesi ni ọna ilu Sagamu si Ọrẹ ṣe pataki fawọn to n rinrin ajo lati ilẹ Yoruba lọ si ilẹ awọn Igbo ni ọna Ibadan si Ogbomoso naa ṣe pataki fawọn to n lọ si Oke Oya lati ilẹ Yoruba.

Soun ni ọna Ogbomoso si Oyo n fiya to pọ jẹ awọn oniṣowo to n ko ounjẹ ati ẹran maalu lọ wa si ipinlẹ Oyo ati ilu Eko lati Oke Oya.

Oriade naa sọ pe ọpọ maalu ati ewrurẹ awọn oniṣowo yii lo n ku lọna ti wọn ba ti ha sinu sunkẹrẹ fakẹrẹ loju ọna yii.

Ọba Ghandi ni irinajo to yẹ kawọn oniṣowo fi ọjọ meji rin ti di nkan ti wọn n fi ọjọ mẹwaa rin bayii latari ọna tọ ti bajẹ laarin ilu Ogbomoso.

Ijọba apapọ ko ṣe ẹtọ rẹ lori ọna aarin ilu Ogbomoso - Ijọba ipinlẹ Oyo

Ninu ọrọ tiẹ, Kọmiṣọna eto iroyin ni ipinlẹ Oyo, Ọmọba Dotun Oyelade sọ fun BBC Yoruba wi pe ọna ijọba apapọ to wa si ilu Ogbomoso lati Oyo ṣe pataki gan an.

O ni ‘’ti a bo wo ọna yii lati agbegbe Caretaker lọ si Seminary to fi de Takie, aarin igboro ilu Ogbomoso lawọn agbegbe yii jẹ.

Ọna yii lawọn tirela akẹru to ba n ko ẹru lati Oke Ọya maa n gba yala ti wọn ba n kẹru lati ilẹ Hausa lọ ilu Ibadan tabi ilu Eko, abi ti wọn ba n kọja lati ilu Eko lọ si ilẹ Hausa pada.

Ijọba apapọ ko ṣe lamẹtọ lori ọna yii lati ibẹrẹ pẹpẹ, nitori rẹ lo fi wa di ẹgẹrẹmiti sawa lọrun.''

Kọmiṣọna eto iroyin nipinlẹ Oyo ni lọpọ igba ti ijanu tirela ba ti ja loju ọna yii ni iru awọn ọkọ bẹẹ maa n ṣe awọn eeyan ilu Ogbomoso leṣe.

Ọmọba Oyelade tun fidi rẹ mulẹ pe owo gọbọi ni ijọba apapọ n jẹ ipinlẹ Oyo tori lọpọ igba ni ijọba ipinlẹ naa ti ṣe lara awọn ọna yii to jẹ ti ijọba apapọ amọ ti wọn ko tii da owo naa pada.

Kọmiṣọna eto iroyin nipinlẹ Oyo sọ pe lati igba ti Obasanjo ti jẹ aarẹ orilẹede Naijiria ni ijọba apapọ ti n ṣe ọna Ibadan si Ogbomoso yii ti ko si tii pari titi di akoko yii.

Ọmọba Oyelade ni Gomina Seyi Makinde ko dakẹ lori ọrọ naa tori lọpọ igba lo ti sọ nipa ọna yii fun David Umahi to jẹ minisita iṣẹ ode lorilẹede Naijiria.

''Ọpọ ẹmi lo ti run soju ọna yii''

Ọgbẹni Rafiu Tijani, oniṣowo to jẹ ọmọbibi ilu Ogbomoso ṣalaye pe ọpọ ẹmi lo ti ru soju ọna yii.

Bakan naa lo sọ pe ọna yii tun ti jẹ ki ọpọ awọn oniṣowo jẹ gbese.

Tijani ṣalaye pe o maa n to ọjọ mẹta nigba mii ki ọkọ toun ba fi ko ọja toun n ta lati ilu Ogbomoso to rọna jade kuro laarin ilu eyi to maa n jẹ ki ọja naa bajẹ nigba mii.

O ni ọna yii da oun ni gbese ẹgbẹrun lọna irinwo naira, N400,000 ri lẹẹkan ṣoṣo.

Awakọ nla, Kareem Babatunde, ni tiẹ sọ pe ọna yii n ṣe akoba nla fun iṣẹ awọn naa gẹgẹ awakọ.

O ni nigba mii ọna naa maa n di patapata debi wi pe ẹnikẹni ko ni ribi gba mọ.