‘Kò dìgbà tí àwọn ọ̀dọ́ Naijiria bá dé Europe, China tàbí America kií ọjọ́ ọ̀la wọn tóo dáa’

Oríṣun àwòrán, akin_adesina/ X
Aarẹ ileefowopamọ to n ri si idagbasoke ilẹ Africa, AFDB, Akinwunmi Adesina, ti sọ pe ko ṣẹṣẹ digba ti awọn ọdọ orilẹede yii ba de ilu oyinbo ki ọjọ iwaju wọn too daa.
Aarẹ AFDB naa sọrọ yii nibi ayẹyẹ ọjọọbi aadọrun ọdun ti ajagunfẹyinti Yakubu Gowon, lọjọ Ẹti, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2024.
Adesina sọ pe lilọ si Europe, China tabi America kọ ni okunfa oriire awọn ọdọ, bi ko ṣe sisọ Naijiria naa di ilẹ idagbasoke ti wọn ti le ṣe oriire.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘’Awa naa gbọdọ di Naijiria agbaye, to kun fun ẹbun oriṣiiriṣii ati iṣẹ, pẹlu irori okoowo to le ṣatilẹyin fun eto ijọba, ti yoo si jẹ ki awọn ọdọ wa duro nilẹ yii .
“ Ẹ ma ṣi mi gbọ, ṣugbọn emi o gbagbọ pe ọjọ ọla awọn ọdọ Naijiria tabi Africa wa ninu lilọ si Europe, America,China tabi ibomi-in.”
“ Ninu ki Naijiria dagba, ki Africa lapapọ gunke agba, ki wọn le pese iṣẹ fun awọn ọdọ wọn nilẹ yii ni ọjọ ọla wa.”
Bẹẹ ni Adesina wi.
O fi kun un pe banki AFDB n ṣiṣẹ lori ipese ọjọ ọla rere fawọn ọdọ lorilẹede yii.
‘$100m ni AFDB ti f’ọwọ́ sí báyìí fún ìdókoòwò àwọn ọ̀dọ́’
O ni ọgọrun-un miliọnu dọla ($100m) ni awọn alabojuto AFDB ti fọwọ si bayii lati fi da banki ti yoo maa ran awọn ọdọ lọwọ nibi okoowo silẹ ni Naijiria.
“ Banki tuntun yii yoo ran okoowo awọn ọdọ lọwọ ni Naijiria, nipa imọ ẹrọ, idokowo ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Igba ọtun leyi jẹ fun Naijiria’’
Adesina ko ṣai sọrọ lori iṣẹ ati oṣi to n ba awọn eeyan finra ni Naijiria.
O ṣalaye nipa akọsilẹ National Bureau of Statistics, NBS, to n ṣe onka bi nnkan ṣe n lọ lẹka ọrọ aje.
“ O le ni idaji eeyan to n gbe ni Naijiria, ti wọn n fi eedu dana, ti wọn ko le lo ilana igbalode nitori aisi owo.
Ọpọ eeyan ni ko ni anfaani eto ilera pipe, ounjẹ gidi, aabo, imọtoto, ibugbe atawọn nnkan amayedẹrun mi-in, gẹgẹ bo ṣe sọ.














