Kò ṣe á má gbọ̀ ọ́
Kò ṣe á má gbọ̀ ọ́
Bi ẹ ko ba fẹ ki nnkan buru ju bayii lọ, ẹ ma sọ pe ki Tinubu dawọ atunṣe to n ṣe duro o.
Haa, iru ikilọ wo ree.
Emi kọ o, Adari Banki Agbaye ni Naijiria,Ndiame Diop lo kilọ.
O ni bijọba ba fi pada nibi to de yii, nnkan yoo le ju bayii lọ.
Nitori kini?
Ka idi ti yoo fi ri bẹẹ loju opo BBC Yoruba.
Awọn ọkunrin mẹta ti mo gbe lo fipa ba Bamise Ayanwola lo pọ, ti wọn si ju u sita lati inu ọkọ BRT mi
Andrew Nice, dẹrẹba ọkọ BRT ti Bamise padanu ẹmi rẹ lo sọ bẹẹ nile ẹjọ
Lasiko igbẹjọ naa to waye lori iku Bamise to wọ BRT lọ si Osọdi lati Ajah lọdun 2022
Ṣugbọn ti irinajo naa pada ja si iku fun un.
Nibo lo waa de duro bayii?
Yahya Sinwar, olori ogun Hamas ti ku o.
Isreali ni awọn ti pa a l’Ọjọruu ọsẹ yii.
Ṣe ogun ti waa pari bi?
Pari kẹẹ!
Ki lo tun wa ku?
