Jigawa: ‘Àádọ́ta èèyàn ni mo pàdánù nínú ẹbí mi sínú táńkà epo tó gbiná’

Bi ọjọ ṣe n gori ọjọ lẹyin ijamba tanka epo to gbina ni Jigawa, bẹẹ ni awọn eeyan ipinlẹ naa n ṣalaye apa ibi ti ajalu naa ti kan kaluku wọn ati bo ṣe lagbara to.
Ọkan ninu wọn ni ọkunrin agbẹ kan,Mustapha Majiya, ẹni to ni o fẹrẹ to aadọta eeyan ninu ẹbi oun ti wọn ku sinu ina naa.
Mustapha sọ pe ki i ṣe gbogbo wọn naa ni wọn lọọ gbọn epo to danu, o ni awọn mi-in n le awọn to fẹẹ gbọn epo ni, ki wọn too gbabẹ fara k’ona.
" Awọn ọmọ ẹgbọn mi meji, Nuradeen Rabiu, ọmọ ọdun mẹrindinlogun, ati Dini Babalo, ọmọ ọdun mẹtadinlogun, wa lara awọn to ku.
‘’Wọn n gbiyanju lati le awọn eeyan kuro nibi tanka naa ni, ko too gbina. Bo ṣe gbina ni ina jo wọn pa.
Mustapha, ẹni aadọta ọdun lo ṣalaye bẹẹ fun BBC.
O ni oun ṣẹṣẹ ra aṣọ ileewe tuntun ati iwe fun awọn ọmọdekunrin meji ti wọn wa nileewe girama naa ni, ṣugbọn o ṣeni laaanu pe wọn ku lojiji nibi ina naa.
Ijamba ina to ṣẹlẹ ni Jigawa lalẹ ọjọ Iṣẹgun ọsẹ to kọja yii ni wọn ti ṣapejuwe rẹ bii ọkan lara awọn ijamba ina to buru ju lọ ni Naijiria.
O kere tan, eeyan ti ko din ni mẹtalelaadoje (153) la gbọ pe wọn jona ku kọja idanimọ.
Eeyan bii ọgọrun-un to tun fara ko ina ọhun ṣi wa nileewosan, nibi ti wọn ti n gbatọju nipo boya wọn yoo ku tabi wọn yoo ye.
‘Ìran wíwò àti àìmọ̀ pé ó léwu láti dúró níbi tí wọ́n ti ń gbọ́n epo ló kó bá àwọn míràn’
Gẹgẹ bi Mustapha Majiya ṣe wi, o ni oun tun padanu ọrẹ oun kan, Jamilu Maigaji, to ni iyawo meji ati ọmọ mẹtala.
Ki i ṣe pe Maigaji lọọ ba wọn gbọn epo ọfẹ gẹgẹ bo ṣe wi, ṣugbọn oloogbe naa pẹlu awọn mi-in duro nibudo iṣẹlẹ naa, wọn n woran.
Ibi iran wiwo naa ni tanka ọhun ti gbina lẹyin wakati kan to ṣubu, ti awọn eeyan si ti n gbọn epo nibẹ.
Asiko naa ni ina mu Maigaji ati awọn miran ti wọn n woran .
Ìṣẹ́ àti òṣì ló mú káwọn èèyàn máa gbọ́n epo ni tàbí táńkà kọ́ ló yẹ kó gbé epo náà?

Oríṣun àwòrán, AFP
Ero araalu ṣọtọtọ lori ijamba yii, nitori bawọn kan ṣe n sọ pe iṣẹ ati oṣi lo fa a ti awọn to gbọn epo naa fi bẹrẹ si I gbọn ọn, bẹẹ ni awọn mi-in n sọ pe tanka kọ lo yẹ ko maa gbe epo kiri ilu.
Awọn kan n sọ pe yoo ṣori lati gboju kuro nibi ti epo bẹntiroolu ti danu, pẹlu bi ijọba ṣe ti fowo le e.
Wọn ni ṣaṣa eeyan ni yoo ri anfaani epo to danu ti ko si ni i gbọn ọn ni Naijiria yii.
Ninu ọrọ awọn onimọ nipa ọrọ epo rọbi, wọn ni ọpọlọpọ ọna lo wa ti wọn le fi gbe epo rọbi de ibi to ba yẹ, lai lo tanka kaakiri ilu.
Onimọ nipa idagboke agbegbe, Kola Ashiru-Balogun, ṣalaye fun BBC pe ijamba yii ṣee dena.
Ni ọdun 2020 nikan, ijamba epo tanka ẹgbẹrun kan aabọ ni akọsilẹ sọ pe o waye, eeyan ẹẹdẹgbẹta o le marundinlogoji (535) ni wọn si di oloogbe, gẹgẹ bi ajọ FRSC ṣe sọ.
Loṣu to kọja yii, eeyan mọkandinlogota ku ni Aarin-Gbungbun ipinlẹ Niger, nigba ti tanka epo fori sọ ọkọ to gbe ero ati maaluu.
Bakan naa lo ṣẹlẹ n’Ibafo, ipinlẹ Ogun, bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan ko ku, awọn ile ati ọkọ ba a lọ.
Kí ni àwọn onímọ̀ sọ?

Oríṣun àwòrán, AFP
Awọn amoye nipa iṣẹlẹ yii sọ pe ki i ṣe pe ko si eto nilẹ lati dena ijamba tanka epo yii, bi ko ṣe pe a ko tẹle e.
Timothy Iwuagwu to jẹ aarẹ ẹka ẹkọ nipa aabo ni Naijiria, (Institute of Safety Professionals of Nigeria,)sọ fun BBC pe ijọba ko tẹle awọn alakalẹ aabo.
O ni awọn ohun to n fa iṣubu tanka ni ọna ti ko daa, awọn ọkọ to nilo ayẹwo ti wọn ko yẹwo, ati awọn awakọ ti ko ni ẹkọ nipa mọto wiwa.
"Bi tanka ba ṣubu lasan, iṣubu yẹn ko lagbara debi ti ina yoo fi sọ. Ai lo awọn paanu gidi lati fi ṣe tanka naa daadaa lo n fa wahala,"Iwuagwu lo ṣalaye bẹẹ.
O ni bi tanka ba gbe kọja epo to yẹ naa n fa ijamba, awọn to yẹ ki wọn yẹ ẹ wo lọna ti ko si da ọkọ epo naa duro n da kun un bo ṣe sọ.
O ni ṣugbọn opin gbogbo ẹ ni pe awọn eeyan ti ko kọ ijamba yoo ṣaa ri i pe awọn lọọ gbọn epo to ba danu ni, nigba ti afikun ko yee ba owo epo.
Lati oṣu karun-un ti Bola Tinubu ti di aarẹ Naijiria, iṣakoso yii ti fi kun owo epo kọja ida ẹẹdẹgbẹta, wọn si ti yọ owo iranwọ ori ina pẹlu kuro.
Eyi to mu ki alekun owo ba ẹka agbara, ati inira fun awọn araalu.
Ẹwẹ, owo naira ti ja walẹ ni ida irinwo (400%) lodi si dọla, eyi to mu ọrọ aje Naijiria dojude si i.
Ni ti ijamba tanka epo to gbina ni Jigawa, bawọn eeyan ṣe n ba wọn kẹdun, ni wọn n bẹ ijọba pe ki wọn ṣeto aabo fun araalu, ki ijamba to ṣee dena ma baa maa pa awọn eeyan kiri.














