Ilé aṣòfin Kenya yọ ìgbàkejì Ààrẹ nípò lásìkò tó wà ní ilé ìwòsàn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Basillioh Rukanga
- Role, BBC News, Nairobi
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3
Awọn ọmọ ilẹ igbimọ aṣofin agba lorilẹede Kenya tí dibo lati yọ igbakeji Aarẹ Rigathi Gachagua kuro nipo lẹyin to kuna lati yọju wa wí ti ẹnu rẹ lori ìyọnipo rẹ lẹyin ti Agbẹjọro sọ pe wọn gbe lọ si ile iwosan.
Gachagua lo yẹ ko wa wi ti ẹnu rẹ niwaju awọn aṣofin lẹyin to ni oun ko jẹbi ẹsun mọkanla tí wọn ka sí lẹsẹ.
Ẹwẹ, Gachagua, ẹni tí ọpọ mọ si Riggy G ni ko yọju si ile igbimọ aṣofin, ti Agbẹjọro si bere pe ki wọn sun ipade naa siwaju nitori onibara rẹ ni isoro aya, to si wa ni ile iwosan Karen.
Awọn aṣofin pinnu lati tẹsiwaju Igbẹjọ naa lai ri igbakeji Aarẹ, ti wọn si le awọn Agbẹjọro rẹ sita.
Igbesẹ awọn aṣofin lati ma sun Igbẹjọ siwaju fihan pe wọn ti pinnu lati yọ Gachagua lẹyin ọpọ oṣu tí awọ tí bẹ silẹ laarin rẹ ati Aarẹ William Ruto.
Lọsẹ to kọja, ọpọ awọn aṣofin lo dibo pe ki wọn yọ Gachagua kuro nipo.
Gachagua, onisowo nla lati aarin gbogbo Mount Kenya tí sapejuwe igbesẹ naa gẹgẹ bí eyi to ni ọwọ oselu ninu.
Igbesẹ yii n waye lẹyin ọdun meji ti Ruto ati Gachagua wọle sipo ijọba.
Ija yii bẹẹ silẹ ninu oṣu kẹfa nigba ti Gachagua bu ẹnu atẹlu bi awọn amugbalẹgbẹ Ruto bi wọn ṣe kuna lati salaye ni Ẹkunrẹrẹ fun Ruto ati ijọba lori owo ori to fa ìwọde.
Eyi ti o da bi abuku si ijọba rẹ, Ruto ni lati yọwọ kuro ninu owo ori naa. O da gbogbo awọn ọmọ ìjọba rẹ duro, to si mu awọn ọmọ ẹgbẹ alatako rẹ sipo ìjọba.
Ni Ibẹrẹ Igbẹjọ naa, ọkan ninu Agbẹjọro Gachagua, Elisha Ongoya ni gbogbo ẹsun ti wọn ka si lẹsẹ lo jẹ irọ to si dojutini.
Saaju kí wọn to yọ nipo, Gachagua ti ni oun yoo morile ile ẹjọ tí wọn ba yọ oun.
Dokita kan to ba Reuters sọrọ pe ẹni ọdun mọkandinlọgọta ti lọ si ile iwosan fun itọju ọkan rẹ sugbọn o ara rẹ tí balẹ.
Awọn oniroyin tí gbe iroyin nípa awọn eeyan mẹrin to ṣeese ko rọpo Gachagua
- Gomina Murang'a Irungu Kang'ata
- Gomina Kirinyaga Anne Waiguru
- Minisita fun ọrọ abẹle Kithure Kindiki
- Minisita fun ọrọ oke okun, Musalia Mudavadi















