"Mo gbìyànjú láti dá ọmọ mi dúrò kó má gbọ́n epo lásìkò tí ọkọ̀ agbépo dànù àmọ́ kò gbọ́, ìjàmbá iná dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò"

Najib

Oríṣun àwòrán, FAMILY

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

“Najib, jẹ́ ka lọ.”

Èyí ni ọ̀rọ̀ ìkẹyìn tó wáyé láàárín Sani Kansila Majia àti ọmọ rẹ̀, ọmọ ọdún mẹ́tàlá.

Najib pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sínú ìbúgbàmù ìjàmbá iná ọkọ̀ agbépo tó gbiná ní ìpínlẹ̀ Jigawa lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.

Ìjàmbá iná ọkọ̀ agbépo tó bú gbàmù náà wáyé ní ìlú Majia, ìjọba ìbílẹ̀ Taura ní ìpínlẹ̀ Jigawa ṣokùnfà ikú èèyàn 153 lásìkò tí BBC ń ṣe àkójọ ìròyìn yìí, táwọn tó lè ní ọgọ́rùn-ún ṣì wà ní ilé ìwòsàn níbi tí wọ́n ti ń gba ìtọ́jú.

Báwọn èèyàn ṣe ń kọminú, tí wọ́n sì ń ṣọ̀fọ̀ àwọn èèyàn tó jáde láyé, BBC kàn sí àwọn ẹbí àwọn tó pàdánù èèyàn wọn nínú ìkọlù náà tó fi mọ́ bàbá Najib.

Bàbá Najib sọ fún BBC pé òun kàn ń gbọ́ táwọn èèyàn ń kan ilẹ̀kùn òun lẹ́yìn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, tí wọ́n sì ń pariwo.

Ìgbà náà ló ṣílẹ̀kùn láti wo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀, tó sì ṣàlàyé pé òun rí àwọn èèyàn tí wọ́n ń sáré lọ síbi tí ọkọ̀ agbépo kan ṣubú sí, tí epo inú rẹ̀ sì ti dànù sí gbogbo ilẹ̀.

“Mo pààrà ibi ìjàmbá iná náà tó ẹ̀ẹmẹta, mi ò rí Najib, ọkàn mi kò balẹ̀, mo lọ sí àwọn ilé ìwòsàn tí wọ́n gbé àwọn tó farapa lọ, mi ò ri níbẹ̀"

“Ẹ jẹ́ ká lọ, ká lọ bù lára epo tó ń dànù.” Nǹkan tí Alhaji Sani Kansila ń gbọ́ táwọn èèyàn tó ń kọjá ń sọ rèé.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ó ní lásìkò náà ni ọmọ òun, Najib gbé ike pé òun náà fẹ́ lọ bù lára epo tó ń dànù náà.

Alhaji Sani Kansila ṣàlàyé pé nígbà tí òun rí ike lọ́wọ́ ọmọ òun láti lọ fi gbọ́ epo tó ń dànù náà, òun gbìyànjú láti da dúró àmọ́ kò dá òun lóhùn, tó sì sọ fún òun pé òun ń bọ̀.

Ó sọ pé nígbà tí Najib kọ̀ láti dá òun lóhùn, òun padà sílé àmọ́ kò pẹ́ púpọ̀ ni òun gbọ́ ariwo ńlá kan, tí òun sì ri tí iná ti gba gbogbo ilẹ̀.

Ó fi kun pé òun sáré jáde láti wá ọmọ òun lọ bóyá kò ní sí lára àwọn tí ìjàmbá iná náà ṣe lọ́ṣẹ́ àmọ́ òun kò ri.

O ni òun padà sílé láti bèèrè lọ́wọ́ ìyá rẹ̀ bóyá ó ti gbúròó rẹ̀ àmọ́ kò sí ẹnikẹ́ni tó fojú kàn-án.

“Mo pààrà ibi ìjàmbá iná náà tó ẹ̀ẹmẹta, mi ò rí Najib, ọkàn mi kò balẹ̀, mo lọ sí àwọn ilé ìwòsàn tí wọ́n gbé àwọn tó farapa lọ, mi ò ri níbẹ̀.

“Èyí ló jẹ́ kí n gbà fún Ọlọ́run pé bóyá Najib wà lára àwọn tó dágbére fáyé ni.”

Bàbá Najib ní nǹkan tó fún òun ní ìrètí ni pé ọ̀rẹ́ Najib tí wọ́n jọ lọ síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni ó ṣì wà láàyè, bí ọmọ náà ṣe ṣàlàyé fún òun pé bàbá òun ló pe òun padà nígbà tí òun àti Najib jọ ń lọ síbẹ̀.

Ó tẹ̀síwájú pé láti ìgbà tí iná náà ti jó lọ sílẹ̀, ni òun ti padà lọ síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà àmọ́ òun kò rí òkú tàbí ààyè ọmọ òun.

Àmọ́ o ni òun rí èèyàn méjì tí òun dámọ̀ níbẹ̀ -ọ̀rẹ́ òun, Kasimu Dansanda àti àná rẹ̀ kan tí wọ́n ti jáde láyé.

"Ọmọ tó ń gbọ́ràn ni Najib, kìí fa wàhálà tàbí hùwà jàgídíjàgan rárá, n kò sì rí oorun sùn mọ́ láti ìgbà tí ọmọ náà ti jáde láyé"

Sani Kansila Majia ní àdánù ńlá ni ikú Najib jẹ́ fún òun àtàwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ yòókù nítorí ọmọ tó máa ń gbọ́ràn ni.

Ó ní kìí ṣe ọmọ tó máa ń fa wàhálà tàbí hùwà jàgídíjàgan rárá, tí òun kò sì rí oorun sùn mọ́ láti ìgbà tí ọmọ náà ti jáde láyé.

“Ọmọ mi kò gbe rárá, mo ṣì ní ìgbàgbọ́ pé ọmọ mi kò ì tíì kú, wọ́n máa mu wá bá mi nílé láti ìlú mìíràn.”

Táńkà tó gbiná

"Mo lọ lé àwọn àbúrò mi tó fẹ́ bu epo tó dànù, ni ìbúgbàmù náà ṣẹlẹ̀ nígbà tí òkúta àti àwọn abọ ayọ́ táwọn èèyàn fẹ́ fi bu epo kan ara wọn"

Sadisu Yahaya Majia jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí orí kó yọ nínú ìjàmbá iná náà tó sì ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn.

Ó sọ fún BBC pé òun lọ le àwọn àbúrò òun tó wà níbi tí wọ́n ti fẹ́ bu epo tó ń dànù náà ni ìbúgbàmù náà ṣẹlẹ̀.

Ó ní òun ìbúgbàmù náà wáyé nígbà tí òkúta àti àwọn abọ ayọ́ táwọn èèyàn fẹ́ fi bu epo kan ara wọn.

Ó fi kun àwọn tó wà níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò lè móríbọ́ nítorí epo náà ti ṣàn dé ibi tó pọ̀ àti pé iná náà búrẹ́kẹ́ gidi tí òun kò sì rí irú rẹ̀ rí.

Ó ṣàlàyé èèyàn márùn-ún ló fara kásá ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún ní ìdílé òun, àwọn méjì sì jáde láyé nínú wọn.

“Èèyàn méjì ti kú, yàtọ̀ sí èm, àwọn méjì míì ló tún wà nílé ìwòsàn tí wọ́n ń gba ìtọ́jú.”

Àwọn tó jáde láyé

"Àbúró mi méjì kú, òmíràn tó ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ nílé ìwòsàn kò lè sọ̀rọ̀, torí ìlera rẹ̀ wà nínú ewu"

Umar Salisu ní tirẹ̀ sọ fún BBC pé àbúrò òun ọkunrin méjì, tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ méjìdínlógún àti mẹ́rìndínlógún ni ó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ.

Bákan náà ló ní ẹni ọdún méjìlélógún míì wà ní ilé ìwòsàn, tó ń gba ìtọ́jú.

Ó ní àbúrò tó ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ náà kò lè sọ̀rọ̀ rárá nítorí ìlera rẹ̀ wà nínú ewu.

Ó sọ pé àwọn àbúrò òun tó pàdánù ẹ̀mí wọn náà ni wọ́n ń gbèrò láti di òṣìṣẹ́ ìlera àti onímọ̀ nípa ilé kíkọ́ kí ikú tó jáwọn gbà.