Wo akọrin ẹ̀mí tó jẹ́ ẹ̀yà Ibo, Chigozie Wisdom, tó ń fi orin dárà lédè Yorùbá
Ẹya Igbo ni Chigozie Wisdom to jẹ akọrin ẹmi, ṣugbọn ede Yoruba lo fi n kọrin.
Wisdom lo kọ orin ti ọpọ eeyan mọ bi ẹni m’owo pẹlu akọle – ‘’ẹ ṣe gan an ni, ẹ ku itọju mi, mo moore.’’
Wisdom sọ ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu BBC Yoruba wi pe ipinlẹ Eko ni wọn bi oun si, koda, agbegbe Obalende loun dagba si.
O ni oun maa n gbọ orin Yoruba tawọn ọrẹ oun maa n kọ ọ nigba ti oun n dagba, eyi to si maa n dun mọ oun nigba naa.
"Mo pinnu pe maa kọ orin Yoruba lọjọ kan, ti gbogbo agbaye si maa tẹwọ gba a, inu mi dun pe ero ọkan mi wa si imuṣẹ"
Chigozie Wisdom tẹ siwaju pe ‘’Ni ọpọ igba ti mo ba n kọja lọ lagbegbe Obalende ni mo maa n gbọ orin Yoruba.
Bakan naa ni mo tun maa n gbọ orin Yoruba nigba ti mo ba lọ sile ijọsin tawọn ẹgbẹ akọrin ba n kọrin.
Eyi lo mu mi pinnu wi pe emi naa maa kọ orin Yoruba lọjọ kan ti gbogbo agbaye si maa tẹwọ gba a.
Inu mi dun lonii pe ero ọkan mi nigba naa lọhun ti wa si imuṣẹ,’’ Wisdom ṣalaye.

‘’Nigba ti mo bẹrẹ si ni kọrin ni ede Yoruba, ni mo ri pe orin jẹ ede ti gbogbo ẹya gbọ''
Akọrin ẹmi Wisdom tun sọrọ lori awọn eeyan to maa n sọ pe awọn olorin ẹmi maa n gba owo ki wọn to le ṣere.
O ni oun maa n gbowo toun ba lọ ṣere nibi ayẹyẹ ọjọ ibi tabi iṣile, amọ, oun kii gbowo ti wọn ba pe oun lati wa kọrin ni ṣọọṣi.
Ọgbẹni Wisdom ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe awọn ijọ Ọlọrun maa n ṣe imọyi fawọn lẹyin tawọn ba kọrin tan, ṣugbọn oun kii beere owo lọwọ wọn.
Akọrin ẹmi naa sọ pe ọpọ awọn ọmọlẹyin oun lo ni iyawo ati ọmọ nile ti wọn ko si gbọdọ mọwọ ofo pada lọ sile.
‘’Nigba ti mo bẹrẹ si ni kọrin ni ede Yoruba ni mo ri pe orin jẹ ede ti gbogbo ẹya gbọ.
Igba naa ni mo tun mọ pe orin jẹ nnkan to ṣo oriṣiiriṣii ẹya ati ede papọ, gbogbo eeyan lorin maa n ṣo pọ,’’ Wisdom lo sọ bẹẹ.
Ọgbẹni Wisdom wa rọ awọn akọrin ẹmi bi tiẹ wi pe ki wọn ma sọ ipe wọn nu, bo tilẹ jẹ pe ohun to n lọ lọwọ lọpọ fi n kọrin bayii.






