Ó ti tó oṣù méjì tí Bobo B ti ń sàìsàn, mo wà lára àwọn tó sáré láti du ẹ̀mí rẹ̀, àmọ́ ó lọ sinmi ni - Toyin Adegbola

Aworan Mudashiru Olabiyi Bobo B

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn agbaagba oṣere n ṣedaro akẹgbẹ wọn, Ayobami Olabiyi, ti ọpọ eeyan mọ si Bobo B, ẹni to jade laye lana Ọjọru ọjọ kẹrindinlogun oṣu Kẹwaa ọdun yii.

Nigba ti o n ba BBC Yoruba sọrọ, agba oṣere n ni, Toyin Adegbola, tawọn eeyan mọ si Aṣẹwo to re London sọ pe oloogbe naa lọ sinmi ni tori o ti to bi oṣu meji to ti n ṣaisan.

Arabinrin Adegbola ṣalaye pe Ọgbẹni Olabiyi to doloogbe naa ni arun itọ ṣuga, ṣugbọn ko tete fura.

O ni ‘’awọn ọmọ rẹ gan an ko mọ pe o ni arun itọ ṣuga, amọ, wọn jẹwọ fun mi nile iwosan UCH wi pe o ni arun naa.

Wọn sọ fun mi tori emi ni mo tẹle e lọ si UCH ti wọn fi gba wa si wọọdu, ki wọn to bẹrẹ si ni tọju rẹ.

Awọn oṣere n ṣedaro Bobo B to jade laye

Aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere TAMPAN, Bolaji Amusan ti ọpọ mọ si Mr Latin ṣapejuwe iku Bobo B gẹgẹ bi adanu nla lagbo awọn oṣere tiata.

Mr Latin ni Ọgbẹni Olabiyi jẹ ẹni to maa n fọkan ṣiṣẹ to si tun lẹbun idari eeyan lawujọ.

Aarẹ TAMPAN ni awọn ko ni gbagbe iṣẹ ribi ribi ti o ti ṣe silẹ ki ọlọjọ to de.

Mr Latin wa rọ gbogbo eeyan lati ranti ẹbi ti oloogbe naa fi silẹ ninu adura wọn papaa julọ lasiko ti wọn ṣọfọ.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 1

Ọmọba Jide Kosoko naa n ṣedaro Bobo B to di oloogbe.

Agba oṣere yii sọ loju opo Instagram rẹ pe ‘’o daarọ o, sun re Bobo B.’’

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 2

Àkọlé fídíò, Ikiso River: Odò yìí kìí gbẹ lásìkò ẹ̀ẹ̀rùn, kìí gbé èèyàn lọ, ó ń fa òjò, bí ọ̀dá bá wà

Òṣèré tíátà, Ayobami Olabiyi jáde láyé

Ayoabami Olabiyi

Oríṣun àwòrán, Others

Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà, Ayobami Mudashir Olabiyi tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Bobo B ti jáde láyé.

Àgbà òṣèré náà jáde láyé lẹ́yìn àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́.

Nígbà tó ń fìdí ikú náà múlẹ̀ fún BBC News Yorùbá, òṣèré, Toyin Adegbola ṣàlàyé pé láti bíi oṣù méjì sẹ́yìn ni Bobo B ti ń ṣe àárẹ̀ tó sì wà ní ilé ìwòsàn.

Toyin Adegbola ní oṣù méjì sẹ́yìn ni Bobo B ti kọ́kọ́ wà ní ilé ìwòsàn University College Hospital, UCH, Ibadan kí wọ́n tó gbé kúrò níbẹ̀ nígbà tí ara rẹ̀ kò balẹ̀ tó.

“Ẹ̀ka àwọn tí àárẹ̀ wọn bá le púpọ̀, ICU ni Bobo B kọ́kọ́ wà kó tó di pé wọ́n gbe kúrò níbẹ̀.”

Ó sọ pé lẹ́yìn tí wọn kò rí ìyàtọ̀ lára rẹ̀ ni wọ́n gbe lọ sí ilé ìwòsàn mìíràn tó wà ní agbègbè Amuloko ní ìlú Ibadan bákan náà.

Ó fi kun pé ọ̀pọ̀ ẹ̀jẹ̀ ni òṣèré náà gbà nígbà tó wà ní UCH.

Ó ṣàlàyé pé wọ́n ti sin òkú rẹ̀ sí ilé rẹ̀ tó wà ní ìlú Ibadan ní ìlànà ẹ̀sìn Islam.

Àtẹ̀jáde tí gómìnà ẹgbẹ́ àwọn òṣèré tíátà ní ìpínlẹ̀ Oyo, Bose Akinola fi léde náà fìdí ikú òṣèré náà múlẹ̀.

Akinola gbàdúrà kí Ọlọ́run tẹ́ Bobo B sáfẹ́fẹ́ rere, kó sì rọ́ àwọn ẹbí rẹ̀ lójú.

Ṣáájú ikú Bobo B, òun ni àkọwé ẹgbẹ́ TAMPAN ní ìpínlẹ̀ Oyo.