Akọrin ẹ̀mí míràn, Dorcas Awolumate, jáde láyé

Oríṣun àwòrán, dorcasawolumate/Instagram
Araba miran tun ti wo ninu ẹgbẹ awọn akọrin ẹmi lorilẹede Naijiria.
Oluwa rẹ ni Arabinrin Dorcas Awolumate.
Dorcas ni iroyin ilu rẹ gbalẹ kan pe o jade laye loju awọn opo ayelujara ni owurọ ọjọ Isẹgun, ọjọ Kẹẹdogun osu Kẹwa ọdun 2024.
Lara awọn eeyan to kọkọ kede iku akọrin ẹmi naa ni oju opo ayelujara Facebook rẹ ni Adeyinka Alaseyọri, ti oun naa jẹ agba akọrin ẹmi.
Alaseyori lo kọ ọrọ soju opo Facebook naa pe “Sọja miran tun ti lọ sile, ki ẹ sun re ma, a ko le bi Ọlọrun lẹjọ.”
Bi o tilẹ jẹ pe Alaseyori ko darukọ Sọja Jesu to lọ sile naa, sibẹ ọpọ eeyan lo n daro ẹni rere to lọ labẹ ikede naa.

Oríṣun àwòrán, Adeyinka Alaseyori (Adeyinka Alaseyori)/Facebook
"Nigba ti aisan Dorcas yii fẹju si, ni wọn gbe wa sile lati ilẹ Amẹrika, ko to ku lọjọ Aje"
Idi ree ti BBC Yoruba fi bẹrẹ iwadi lati finmu finlẹ nipa oloogbe to dagbere faye naa.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori foonu lọsan ọjọ Isẹgun, ọkan lara awọn agbẹnusọ fun awọn gbajumọ akọrin ẹmi ti a fi orukọ bo ni asiri, fidi rẹ mulẹ, to si kede Sọja Jesu to jade laye naa.
“Dorcas Awolumate ni akọrin ẹmi ati Ajihinrere to fi aye silẹ naa ni aarọ ọjọ Aje ana lasiko aisan ranpẹ.
Dorcas lo fi orilẹede Amẹrika se ibujoko, nibi to ti n gbe awo orin ẹmi jade, ki Ọlọjọ to de, nibẹ naa si ni aisan rẹ ti bẹrẹ.
Amọ nigba ti aisan yii fẹju si, ni wọn gbe wa sile, ko to jade laye ni ọjọ Aje.
Gbajugbaja akọrin ẹmi ni Dorcas Awolumate, to si ti se ọpọ awo orin lati fọnrere ihinrere Jesu Kristi, mo si gbadura pe ki Ọlọrun tẹ si afẹfẹ rere.

Oríṣun àwòrán, dorcasawolumate/Facebook
Ta ni Dorcas Awolumate?
Ẹtahoro ni iroyin nipa itan aye Dorcas Awolumate to wa lori ayelujara amọ a ri pe ile ẹkọ girama Adenrele High School lo lọ.
Lẹyin naa lo morile ile ẹkọ Gbogbonse Poly nilu Ilaro fun itẹsiwaju ẹkọ rẹ.
Emmanuel Awolumate ni ọkọ Dorcas, ti wọn si dijọ n gbe papọ nilẹ Amẹrika.
Lẹyin eyi lo bẹrẹ si ni kọ orin ẹmi, to si di gbajumọ.
Ọjọ Satide, ọjọ Kejila osu Kẹwa si ni Dorcas fi ikede soju awọn opo ayelujara rẹ kẹyin nibi to ti se ajọyọ ọjọ ibi ọkọ rẹ, ko to jade laye lọjọ Aje.
Awolumate ti gbe awo orin to le ni mẹẹdogun sita, lara rẹ ni Opo to gbe ile aye mi ro, ObaniJesu, Ẹ ba mi ki Eledumare, God of my Journey, Baba Olooreofe, Melomelo, Praise Medley ati bẹẹ bẹẹ lọ.















