Báwo ni ìjọba àpapọ̀ yóò ṣe mọ ọmọ Nàíjíríà tí ìṣẹ̀ ń bá fínra julọ, èyí tó fẹ́ pín ogún mílíọ́nù ọmọ Naijiria fún?

Aworan Minisita fun eto iṣuna;Wale Edun ati Aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Àkọlé àwòrán, Aworan Minisita fun eto iṣuna;Wale Edun ati Aarẹ Bola Tinubu
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ninu alekun owo ti ijọba apapọ Naijiria pa wọle ni 2024 yii, wọn ti ṣetan lati fun ogun miliọnu ọmọ Naijiria ti nnkan ko rọgbọ fun ninu rẹ, ki wọn le fi gbọ bukaata ara wọn.

Wale Edun; minisita fun etọ iṣuna lorilẹede yii, lo fi ọrọ naa lede l’Abuja, lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2024.

Ẹdun sọ pe ida ọgọta (60%) awọn eeyan ti ìṣẹ́ n ṣẹ gidi ni owo naa wa fun, wọn si to ogun miliọnu niye.

O ni ijọba tun n gbero awọn eto kan ti yoo tun ọrọ aje ṣe,mu adinku ba ọwọngogo ọja, pese iṣẹ ati eyi ti yoo mu idagbasoke ba ọrọ aje lapapọ.

Ṣe lọjọ kin-in-ni oṣu kẹwaa yii, Aarẹ Bola Tinubu kede owo to wọle fun Naijiria laaarin oṣu kin-in-ni si ikẹfa ọdun 2024, o ni o le ni N9.1tn.

Eyi kọja ilọpo meji N4.06, ti wọn pa wọle lasiko kan naa ni n 2023.

Ọnà wo ni owó yìí máa gbà dé ọ̀dọ̀ àwọn tó yẹ?

Wale Edun tẹsiwaju pe “ A maa sanwo yii taara si apo ikowosi awọn ida ọgọta eeyan ti iṣẹ n ṣẹ ni.

Lọwọlọwọ yii, a ti ṣeto fun idile to to ogun miliọnu, yoo si maa lekun si i ni.

Ijọba yoo maa sanwo naa fun wọn lai si alagbasan kankan.

“ Ọna ti ijọba Aarẹ Tinubu n gba na owo to n wọle lati ara epo niyẹn’’

Wale Edun, minisita eto iṣuna lorilẹede yii lo ṣalaye bẹẹ.

O fi kun un pe ijọba yii dojukọ iṣẹ ọgbin pupọ ati ipese nnkan elo.

“Afojusun wa ni lati maa pese nnkan lọpọlọpọ, ki ọwọngogo ọja le dinku.

“A n gbero pe ki ounjẹ pọ si i, ki araalu le ra a, ki igbesi aye si rọrun fun awọn ọmọ Naijiria.’’

Bẹẹ ni minisita naa ṣalaye.

Gẹgẹ bo ṣe wi, miliọnu mẹrin idile ni wọn ti jẹ anfaani owo tijọba apapọ fi n ranṣẹ yii .