Ìṣòro tó ń kojú Nàìjíríà báyìí kò ṣẹ̀sẹ̀ bẹ̀rẹ̀, ìjọba Tinubu ń gbìyànjú - Fayose

Oríṣun àwòrán, Ayo Fayose/Instagram
Gomina ipinẹ Ekiti tẹlẹ, Ayodele Fayoṣe, ti sọ pe ijọba Aarẹ Bola Tinubu n gbiyanju agbara rẹ lati jẹ ki orilẹede yii rọrun, ati pe laipẹ ni nnkan yoo daa.
Lori eto ileeṣẹ tẹlifiṣan Channels kan ni Fayoṣe ti sọrọ yii, lọjọ Aiku, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹwaa ọdun 2024.
Gomina tẹlẹ naa sọ pe loootọ ni nnkan le gidi ni Naijiria bayii, o ni ṣugbọn ko le pẹ ti idẹra yoo fi pada de si orilẹede yii.
“Mo gba pe nnkan ko rọgbọ loootọ f’awọn eeyan ni Naijiria, ṣugbọn emi ro pe ijọba yii n sa ipa rẹ gidi lati ri i pe gbogbo ẹ daa. Bo tiẹ jẹ pe o yẹ ki wọn ṣi fi kun ipa wọn si i.
“Ta a ba n sọ pe wọn nilo asiko lati tun nnkan ṣe, awọn eeyan aa maa beere pe asiko wo ni wọn nilo to bẹẹ.
Ṣugbọn emi mọ pe pẹlu akoko diẹ, nnkan maa daa.”
Fayoṣe sọ pe iṣoro to n koju Naijiria bayii ko ṣẹṣe bẹrẹ, o ni ohun to ba ọrọ aje ilu yii jẹ ko ṣee yanju laaarin asiko perete.
Àfi ìdásí Ọlọ́run ló lè gbé PDP dúró lódidi padà
Bakan naa ni Ayodele Fayose ṣalaye nipa ipo ti ẹgbẹ Peoples Democratic Party (PDP), wa lapapọ lorilẹede yii.
Gomina Ekiti tẹlẹ naa sọ pe ipo itiju ni PDP wa bayii, ati pe bi wọn ṣe padanu ninu ibo to kọja n yọ wọn lẹnu gidi.
Fayoṣe sọ pe yoo ṣoro pupọ fun PDP lati duro lodidi pada, lati koju ẹgbẹ oṣelu alatako lorilẹede yii mọ.
‘’ Ai ṣe deede ati iwa igberaga awọn eeyan kan ninu ẹgbẹ n ṣakoba fun ẹgbẹ naa lonii, bi aisan ba si si n ṣe ori, gbogbo ara lo n ṣe. Idasi Ọlọrun ati iṣẹ iyanu lo le gbe ẹgbẹ yii duro pada’’
Ayodele Fayose lo sọ bẹẹ.
''Ìjà Wike àti Fubara ti kọjá ohun tó lè parí''

Oríṣun àwòrán, Sir Siminalayi Fubara/Facebook
Wahala to n koju ẹgbẹ PDP ko ṣai de ipinlẹ Rivers naa, nibi ti Nyesom Wike; minista fun ilu Abuja ati Gomina Rivers, Siminalayi Fubara, ti n koju ara wọn.
Nigba to n sọrọ nipa eyi, Fayose sọ pe ija awọn oloṣelu mejeeji yii ti kọja ohun to ṣee pari.
O ni o ṣeni laaanu pe ọrọ Wike ati Fubara pada ri bayii.
‘’Ti ẹ ba tiẹ ni ẹ fẹẹ yanju ọrọ yii, bawo ni igbagbọ to ti sọnu laaarin wọn yoo ṣe pada mọ.
‘’Emi gbagbọ pe ija yii ti kọja ohun ti eeyan le pari’’
Bẹẹ ni Fayose wi.
''Gomina Oyebanji ti ṣe dáadáa l’Ekiti''
Nigba to n gboriyin fun gomina Ekiti lọwọlọwọ, Biodun Oyebanji, Fayose sọ pe ọkunrin naa ti ṣe ohun ribiribi si Ekiti.
’’Lonii, ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni mi, Oyebanji si jẹ ọmọ ẹgbẹ APC, ṣugbọn ko ni i daa ti mi o ba sọ nipa iṣẹ rẹre to ti ṣe bii gomina.’’
Fayose sọ pe yoo ṣoro ki Gomina Oyebanji too kuna ninu idibo ọdun 2026, nitori iṣẹ rere rẹ ti n fọhun silẹ de e.
Bẹẹ lo ni idarudapọ wa ninu PDP Ekiti, ẹni to ba wu ko ni irọ ni.
''Ẹ jẹ ka gbagbe nipa ẹgbẹ oṣelu to yatọ, Gomina Oyebanji ti ṣe daadaa gan-an l’Ekiti.
O si ti mu irẹpọ ba awọn agbaagba Ekiti lai fi ti ẹgbẹ oṣelu ti wọn wa ṣe.''















