‘Ó sàn kí n kú sí Lebanon ju kí n padà sí Naijiria’

Oríṣun àwòrán, Akinbobola
- Author, Foluke Ogunbayo
- Role, BBC News, Lagos
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3
Ti ijọba Naijiria ba fi ọkọ baalu ransẹ lati wa gbe eeyan wọn kuro ni Lebanon lonii, ọpọ ọmọ Naijiria ni ko ni wọ baalu naa.
Awọn ọmọ Naijiria ni Lebanon sọ fun BBC pe o tẹ awọn lọrun pe ki awọn duro, ki awọn sí ku si Lebabon ju kí awọn pada si orilẹede Naijiria.
Bẹẹ ba gbagbe, Ikọlu n lọ lọwọ ni apa ariwa orilẹede Lebanon.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ìjọba to n risi ọrọ oke okun ni Naijiria sọ fun BBC ni ọjọ kọkanla oṣu kẹwaa pe aadọrin eeyan lo ti forukọ silẹ nínu eeyan ẹgbẹrun meji to wa ni Lebanon pe wọn fẹ pada si ile.
O ni o di igba ti wọn ba ri eeyan ti baalu le gbe, kí wọn to gbera kuro Lebanon.
"Mo ní iya to n ṣe airẹ ati Baba ni ile (Naijiria), taa ni yoo tọju wọn fun mi, taa ni yoo ba mi san gbese mi ni Naijiria? O pe mi ki n ku síbi ju kí pada si Naijiria." Adeola to n ṣiṣẹ ile ni Beirut salaye.
Ẹni ọdun mẹdọgbọn naa lo ti n gbe ni Lebanon fun ọdun marun-un, to si n sisẹ fun idile kan Lebanon sugbọn o sa kuro nigba Ikọlu Israel n pọ sí. Awọn to gba sisẹ ja ju silẹ nigba ti eefin bolẹ ni Beirut lasiko ìbúgbàmù.
Wọn ṣe ileri lati ma tẹsiwaju lati san owo oṣu rẹ fún, eyi ti o jẹ $300 ti o ba le duro lati mojuto ile wọn.
Bí Ikọlu Israel ṣe n gboro si ni Lebanon lati le ikọ Hezbollah síta, ọpọ awọn orilẹede lagbaye ni wọn ti n ko awọn eeyan wọn kuro.
Ijọba Naijiria naa darapọ mọ wọn, ti wọn si kede lati ko awọn eeyan Naijiria kuropada si Naijiria.
Ọpọ awọn ọmọ Naijiria to n gbe ni Lebanon lo n gbọ bukata awọn eeyan wa ni ile, Rowland Aigbovbiosa, alaga awọn Naijiria ni Lebanon sọ fun BBC.
"Agbegbe Naijiria ko pe ni rara "
Aigbovbiosa ni ọpọ gbagbọ pe alaafia yoo jọba laipẹ laarin orilẹede mejeeji ati pe ọpọ awọn Naijiria n ṣe iṣẹ gidi to n san owo ni Lebanon.
O ni ẹru n ba ọpọ pe tí wọn ba pada si Naijiria, wọn ko ni rí iru anfani bẹẹ mọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Joy, ọmọ Naijiria to n sisẹ fun idile kan ni Lebanon sọ fun BBC pe oun ko le pada si Naijiria.
O ni oun ko ro pe oun yoo ri isẹ gidi ni Naijiria ti yoo san owo fun.
"Ko si ẹnikẹni to fẹ wa ninu ipo yii pe ko mu ọkan ninu pe ko wa nibi oogun tabi ko pada wa si ile. Sugbọn n ko le pada si Naijiria níbi tí ìjọba ko ni okunkun ti wọn fẹ fun wa.
Gẹgẹ bí ajọ to n risi ọrọ ọmọ Naijiria lo ke okun NIDCOM ṣe gbe sita, ko ti sì ọmọ Naijiria kankan to ti wa se salabapade aburu Lebanon.
Ajọ naa ti rọ àwọn ọmọ Naijiria to wa ni awọn agbegbe ti ibugbamu naa ti n waye pe ki wọn ní ibẹ lọ sí ibo miiran ti alaafia wa

Oríṣun àwòrán, Getty Images











