"Agbára wà nínú ìpèníjà ojú tí a ní"

- Author, Agnes Penda and Gem O'Reilly
- Role, BBC News
- Reporting from, in Lake Victoria and London
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Moses Mugabe, ẹni ọdun mẹtalelaadọta kan lati ila-oorun Uganda ti ko mọ ohun ti o fa a ti oju rẹ fi fọ ṣugbọn o ranti ohun iyalẹnu to sẹlẹ kẹhin, eyi ti o dimu.
O sọ pe: “Igbesi aye ìbanujẹ ni mo n gbe lati igba ti mo ti gba iroyin pe mo ti padanu oju mi patapata, pe n ko le ri iran mọ laye.
Moses jẹ ọkan ninu ọpọ eeyan orilẹede Uganda to ni ipenija oju gẹgẹ bii iwadii IAPB, ajọ to n se iwadii nipa fifọju, se ṣalaye.
Ni Iha Iwọ-oorun Afirika, ọgọrun un eeyan lo n gbe pẹlu oju fifọ. Pẹlu bi ọpọ awọn eeyan Uganda se ni anfani si eto ilera, awọn to n gbe ni ẹsẹkuku ti n tiraka lati ri itọju oju gba.
Awọn onimọ oju diẹ lo wa ni orilẹede naa.
Laisi itọju, awọn eniyan bii Moses gbọdọ wa awọn ọna miiran lati koju ipenija oju yii.
Moses n gbe pẹlu iyawo rẹ ati awọn ọmọ mẹta ni abule Luubu, ni apa ariwa ti Adagun Victoria.
Wọn da ile ẹkọ silẹ ni ọdun 2000, ile-ẹkọ awọn afọju fun awọn ọmọde ti ko ni oju, Moses ṣe itọsọna fun agbegbe igberiko ti wọn n pe ni 'Ẹgbẹ Luubu fun awọn afọju'. Agbegbe naa ni awọn eeyan mẹdọgbọn, o fẹrẹ jẹ pe gbogbo wọn n gbe pẹlu ipenija oju.
Wọn da silẹ ni agbaala kan pẹlu ile mẹwaa, agbala ti o pin ati awọn ile-igbọnsẹ meji ti o wọpọ.
Labẹ iboji igi kan, agbegbe naa pade ni gbogbo ọjọ Aje lati jiroro lori awọn ipenija ti wọn n koju.
Moses, ni wọn n tọka si gẹgẹ bi ‘alaga’ , to si n dari ipade naa.
“A beere awọn ohun elo iranlọwọ igbọran lati ṣe alekun agbara igbọran wa,” ọmọ ẹgbẹ kan sọ.
Ẹlomiran sọrọ lori afikun owo ile ẹkọ awọn ọmọ. Moses fesi pẹlu ohun irẹlẹ.
"Ma ṣe jẹ ki awọn eeyan tapa awọn ẹtọ wa nitori a jẹ alaabo, a yoo sọrọ soke ki gbogbo eeyan le mọ iye wa," o dahun.
Awọn ipade ọsẹ wọnyi ṣe iṣẹ pataki , Moses sọ fun BBC.
"A sọrọ nipa bawo ni a ṣe le ṣe atilẹyin fun ara wa ati tọju awọn ọmọ wa ni ile-ẹkọ. Bawo ni a ṣe le fun awọn ọmọ wa ni ounjẹ, wọ aṣọ fun wọn ati bi wọn ṣe le ni anfani si ilera."

Gbigbe gẹgẹ bii afọju ni Uganda
Awọn olugbe Luubu, wọn le ti padanu oju wọn patapata tabi di alailagbara oju fun awọn idi pupọ tabi aisan kan lo ṣokunfa.
Ṣugbọn ọpọlọpọ wọn, bii Moses, ni ti anfani lati ba dokita sọrọ.
Ni ọdun 1990s ati 2000s, afọju jẹ aisan kan to tan kaakiri agbegbe Mayuge ti ila-oorun Uganda.
Arun kokoro arun kan maa n fa arun naa, to si maa n pin kiri fun awọn eeyan nipa jíjẹ awọn eṣinṣin dudu to ni akoran leralera.
Awọn ibugbe adagun-odo, bii Luubu ni o kan paapaa.

Airiran
Dokita Waiswa Julius ni dokita oyinbo nikan to n tọju awọn eeyan awujọ Bukatebe nibi ti abule Luubu wa.
Ọjọ meji ni o maa n fi ṣiṣẹ ni ile iwosan alabọde Mayuge nibi to ti n maa n tọju awọn eeyan Luubu.
Dokita Julius ni iṣẹ ati ainimọtoto wa lara awọn ohun to n ṣokunfa ipenija oju laarin awọn eeyan naa.
Amọ, ọpọ eeyan ti wọn maa n lo oogun ibilẹ naa lati fi ṣe itọju oju wọn dipo ki wọn lọ si ile iwosan naa tun jẹ ọna mii tawọn eeyan awujọ naa fi n padanu oju wọn.
Dokita Julius ṣalaye pe lilo oogun ibilẹ fun itọju oju n ṣakoba lọpọlọpọ fawọn eeyan naa.
O ni ọwọ ti maa n bọ sori nigba ti wọn ba pada lọ ri dokita nile iwosan.
Dokita Aldred Mubangizi to n ṣiṣẹ pọ pẹlu ileeṣẹ ijọba to n ri si eto ilera ni Uganda sọ pe ijọba ti n ṣe eto koriya fawọn akẹkọọ ìmọ iṣegun lati yan itọju oju laayo.

'Airiran wa ni agbara wa'
Moses at'awọn eeyan lawujọ wọn yoo fi maa fi ẹmi ara wọn mi titi t'awọn dokita onimọ nipa itọju oju yoo fi wa daadaa l'awọn igberiko lorilẹede Uganda.
Moses ṣalaye pe "ohun ti a kọkọ fi kọ ara wa ni ibaṣepọ to dan mọran.
A jọ nilo ara wa ni, ninu ipenija ara wa ni agbara wa wa."
O ni mẹta lara awọn iṣoro to n koju awọn eeyan to ni ipenija oju ni titabuku wọn lawujọ, riri dukia to tọ sí wọn gba gẹgẹ bi ẹtọ wọn ati iṣoro riri ẹni ti yoo fẹ wọn gẹgẹ bi ọkọ tabi iyawo.
Awọn eeyan awujọ Mose n gbiyanju lati ri pe wọn fi awọn ọmọde to ni ipenija oju sile ẹkọ t'awọn to ni ipenija ara maa n lọ.
Koda, Mose ti pinnu lati ran awọn rẹ nile ẹkọ giga fasiti debi ti wọn yoo fi gboye Ọmọwe.
O ni awọn ọmọ yii ni yoo mu ẹgan awujọ naa kuro lọjọ iwaju.
Mose ni "ti wọn ba ti kẹkọọ gboye, ko sẹni to ṣakiyesi pe wọn ni ipenija oju.
Àṣeyọrí l'awọn eeyan yoo maa wo nigba naa.
A o ni kaarẹ nipa jija fun ẹtọ wa nibi kibi, bo ti wu ko ri."















