'Àwọn ọ̀gá mi tì mi mọ́lé làsìkò ogun, wọ́n sá lọ ní tiwọn'

- Author, Manal Khalil and Ethar Shalaby
- Role, BBC News Arabic
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Nigba ti ado oloro Israel bugbamu ni ile eeyan to gba si iṣẹ ni guusu Lebanon, Andaku(ki ṣe orukọ rẹ gan gan) ba ara rẹ nikan ni ile rẹ, ti wọn ti ilẹkun mọ, ti ẹru si n ba.
Ẹni ọdun mẹrinlelogun lati orilẹede Kenya n siṣẹ ni Lebanon gẹgẹ bii ọmọ ọdọ lati ibi oṣu mẹjọ sugbọn ni oṣu to kẹyin lo le ju fun ọdọmọbinrin naa nigba ti ado oloro n bu gbamu ni guusu orilẹede naa.
“Ọpọ ibugbamu lo waye ti n pọju. Awọn to gba mi siṣẹ ti mọle, ti wọn salọ lati dola ẹmi ara wọn.
Ariwo ibugbamu da ọlọpọ Andaku laamu. Ko ti ẹ ranti iye ọjọ ti o wa niluu ile ti wọn ti mọ saaju ki awọn to gba siṣẹ to salọ.
“Nigba ti wọn pada de, wọn ti mi sita. Wọn ko san owo mi, ti n ko si ni ibi ti mo fẹ lọ,”o ṣalaye, to si tun fikun pe ori lo yọ pe o ni owo diẹ lọwọ lati wọ ọkọ lọ si olu ilu, Beirut.
Itan Andaku kọ ni akọkọ tabi igba akọkọ ti irufẹ iṣẹlẹ naa yoo waye.
Gẹgẹ bii IOM se ṣalaye, o din ni ọgọrun un eeyan to wa lati ilu mii to n siṣẹ ni Lebanon, ọpọ wọn lo jẹ obinrin lati orilẹede Kenya, Ethiopia, Sudan, Sri Lanka ati Bangladesh.
“A n gba iroyin nipa ipo ti awọn ọmọ oke okun yii wa, ti wọn n ja wọn kunlẹ, ti wọn si n fi wọn silẹ ni oju titi tabi ti wọn mọle.
Ọpọ awọn eeyan to wa lati oke okun ti wọn se ọmọ ọdọ rin irinajo lati wa sisẹ ni Labanon la ti le ri owo fi ransẹ pada sile.
Owo oṣu ti wọn gba gẹgẹ bii ẹya dudu ni o jẹ $250, ti awọn akẹgbẹ wọn lati ilẹ Asia n gba $450.
Ko si ibi ti a fẹ lọ

Mina(Ki se ọrukọ rẹ gan gan) wa lati Uganda, to si ti siṣẹ ọmọ ọdọ ni Lebanon fun ọdun kan ati oṣu mẹrin.
O sọ fun BBC pe idile to gba siṣẹ n lo bi ẹru, ti o si ni lati salọ, pẹlu erongba pe yoo ri iranlọwọ gba. Mina ni o ya oun lẹnu lati gbọ pe o ni lati sisẹ fun idile nitori o wa lori adehun ọdun meji nki o to le pada sile.
“Nigba ti mo pada si ọfisi, mo sọ fun wọn pe mo sisẹ to lati le san owo tikẹti mi pada lọ si ile. Wọn gba owo mi, ti wọn si sọ fun mi pe ki lọ siṣẹ ni ile mii fun ọdun meji ki n to le rin irinajo.
“Awọn idile yii ma lu mi, ti mi sita -Ado oloro n bu gbamu mi asiko naa. Nigba ti mo sa kuro, ko si ibi ti mo fẹ lọ.” O ṣalaye.
Ọmọ ọdọ mii lati Kenya naa sọ itan rẹ fun BBC
Fanaka, ẹni ọdun mẹrinlelogun, sọ pe ni awọn ileeṣẹ to n ba sisẹ ni ko lọ siṣẹ ni miiran laaarin oṣu meji, ti o si n la ọpọ ori fifọ kọja.
“Mo maa n gbiyanju agbara mi nibi iṣẹ sugbọn ko si ẹni to pe tan.”
Awọn obinrin yii ni n la ọpọ ipenija kọja nigba ti wọn n gbe loju titi, ti ọpọ si kọ lati gba wọn sile.
Awọn mẹtẹẹta yii gbiyanju lati de Caritas Lebanese- ileeṣẹ kan ti ki nse ti ijọba to n pese iranlọwọ fun awọn ara oke okun lati ọdun 1994.
Nibi ohun ti wọn fi ransẹ si BBC, awọn eeyan yii lati Sierra Leone ni ọpọ eeyan ni ko ni ile lori ni igboro Beirut, ti wọn ko si ri ounjẹ.

Oríṣun àwòrán, Reuters















