Ìjì líle Hurricane Milton sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ di aláìrílégbé ní Florida

Àkọlé fídíò, Àwọn àwòrán Hurricane Milton táwọn omímọ̀ sáyẹ́ǹsì Nasa yà
Ìjì líle Hurricane Milton sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ di aláìrílégbé ní Florida
Aworan iji lile Hurricane

Oríṣun àwòrán, Reuters Marco Bello

Ìjì líle Hurricane Milton ló ti ń tẹ̀síwájú láti máa jà ní àwọn apá Florida tó sì ń fa kí afẹ́fẹ́ ńlá máa jà àti àgbàrá òjò.

Èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù méjì àtàwọn ilé iṣẹ́ ni wọn kò ní iná mọ̀nàmọ́ná mọ́ báyìí.

Èèyàn mẹ́rin ló ti pàdánù ẹ̀mí wọn ní agbègbè St Lucie tó wà ní ẹkùn ìlà oòrùn Florida.

Gomìnà ìpínlẹ̀ náà, Ron DeSantis ní ilé tó lé ní márùndínláàdóje ni ìjì líle náà ti ṣe àkóbá fún.

Àwọn ilé àti iléeṣẹ́ tó tó mílíọ̀nù méjì ni kò sí iná mọ̀nàmọ́ná níbẹ̀ mọ́. Tó bá máa fi di alẹ́, kò ní èèyàn kankan ní àwọn àdúgbò náà mọ́ nítorí àwọn òṣìṣẹ́ pàjáwìrì ti ṣèkìlọ̀ pé ó léwu láti máa lo ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ lásìkò yìí níbẹ̀ nítorí àrá.

Àwọn aláṣẹ ní ìpínlẹ̀ náà ní àwọn ti da àwọn òṣìṣẹ́ ààbò tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá àti oúnjẹ tó le tó ogún mílíọ̀nù èèyàn jẹ sí agbègbè náà.

Bákan náà ni wọ́n ní àwọn ti pèsè omi ogójì mílíọ̀nù lítà fún àwọn tí ìjì náà ń dà láàmú.

Àwọn ìpínlẹ́ mìíràn tí ìjì líle náà kò jẹ́ kí àwọn náà ní iná mọ̀nàmọ́ná ní North Carolina àti Georgia.

Pápá ìṣeré baseball tó gbà tó èèyàn 42,000 ni ìjì líle Hurricane Milton ti fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ báyìí.

Bí atẹ́gùn tó lágbára ní ìwọ̀n kìlómítà 205 ṣe wọ St Petersburg ni òrùlé pápá ìṣeré Tropicana Field ṣí dànù.

Àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ní pápá ìṣeré náà ni àwọn èèyàn tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ń lò àmọ́ kò sí ẹni tó ṣèṣe nínú wọn.

Àwọn èèyàn St Petersburg àti Florida ni kò rí omi lò báyìí látàrí bí àwọn aláṣẹ ṣe ti omi wọn pa nítorí ìjàm̀bá tí ìjì líle náà ń dá sílẹ̀.

Wọ́n rọ àwọn ará ìlú láti máa ṣe ọmọ wọn dáadáa kí wọ́n tó mu ún, fi dáná tàbí fọ ẹnu wọn.

Àjọ National Hurricane Center ní ìjì líle Hurricane Milton ti ń lọ sí gúúsù ìlà oòrùn Florida báyìí.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí àjọ náà fi sórí X, wọ́n ní ìjì náà ti ń lọ sílẹ̀ àmọ́ ó ṣì ń fa afẹ́fẹ́ tó lágbára àti àgbàrá òjò.

Awọn obìnrin meji ninu ojo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àwọn àwòrán àti fídíò tó ṣàfihàn ìjì líle Hurricane Milton láti inú sánmọ̀

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣe àgbékalẹ̀ àwọn àwòrán ìjì líle Hurricane Milton láti ojú òfurufú bí ó ṣe ń yí lọ sí Florida.

Onímọ̀ nípa ojú òfurufú Mathew Dominick ya fídíò bí ìjì líle náà ṣe tóbi tó.

Àwọn òṣìṣẹ́ tó dọdẹ ìjì líle náà tún fò lọ sí ojú òfurufú sójú ìjì líle Hurricane Milton náà láti rí àkọ́ọ́lẹ̀ fún àjọ National Hurricane Center.

Maxwell Alejandro Frost láti ààrin gbùngbùn Florida náà wà lára àwọn tó rin ìrìnàjò náà. Ó júwe àwọn ìlà kàkà wọn lójú òfurufú fún wákàtí mẹ́jọ náà bí èyí tó Lágbára púpọ̀.

Àkọlé fídíò, Àkókó tí ìjì ṣèkọlù sí ọkọ̀ òfurufú àwọn tó ń dọdẹ ìjì líle

Iléeṣẹ́ ìròyìn kan tó fi ìlú London ṣe ibùjókòó Sen ṣe àgbéjáde àwọn àwòrán ìjì líle Hurricane Milton bí ó ṣe gba Mexico.

Àkọlé fídíò,