A kò mọ ohunkóhun nípa àfikún owó epo - Ìjọba àpapọ̀

Aworan Aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Tinubu/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti ni oun ko mọ nipa afikun owo epo, eyi to waye ni ana Ọjọru lorilẹede Naijiria.

Bẹẹ ba gbagbe, ileeṣẹ to n ri epo rọbi, NNPCL se afikun owo epo kaakiri gbogbo awọn ile epo lorilẹede Naijiria.

Nigba to n ba Daily Trust sọrọ, minisita fun eto iroyin lorilẹede Naijiria, Mohammed Idris ni ijọba o lọwọ ninu afikun owo epo rara.

“Idi ti wọn fi fowo kun owo epo lo da lori ija to waye ni ekun Middle East, eyi to si jẹ o waye kaakiri ileeṣẹ itaja epo kaakiri agbaye.”

Minisita naa wa rọ awọn araalu lati tubọ sisẹ pẹlu ileeṣẹ NNPCL ati ijọba apapọ.

Lana Ọjọru ni awọn ẹka ileepo kan to jẹ ti ajọ NNPCL ti ṣe atunsẹ si iye ti wọn n ta lita epo bẹtiroolu.

NNPCL funra rẹ ko tii sọ ohunkohun lori afikun owo epo, ṣugbọn igba keji niyii ti wọn fi owo kun iye ti wọn n ta lita kan laarin oṣu kan.

Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC sọ̀rọ̀ lórí àfikún owó epo bẹntiróòlù tí NNPCL ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe

Aworan ile epo NNPC

Ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ti bu ẹnu atẹ lu afikun owo epo bẹntiroolu ti ajọ NNPC ṣẹṣẹ ṣe lọsan an Ọjọru, ọjọ kẹsan an oṣu Kẹwaa ti a wa yii.

Ninu atẹjade kan to fi lede loju opo X ẹgbẹ NLC, aarẹ ẹgbẹ naa, Joe Ajaero, sọ pe o dabi ẹni pe ijọba to wa lode ko mọ nnkan mii ṣe mọ yatọ si ko maa ṣe afikun owo epo lai na an ni ipa ti yoo ni lara awọn ọmọ Naijiria.

Ajaero sọ ninu atẹjade naa wi pe ko bojumu rara wi pe NNPCL lo n sọ iye tawọn araalu yoo maa ra epo eleyii to yẹ ki bi nnkan ṣe n lọ lọja epo rọbi lagbaaye maa ṣe.

Ẹgbẹ NLC wa kepe ijọba lati jokoo, ko si ronu lori eto ọrọ aje ti yoo mu idagbasoke ba Naijiria dipo awọn eto ti ko ni ipa gidi lori araalu.

‘’Afikun owo epo ti NNPCL ṣẹṣẹ ṣe yii tun ti dakun iṣoro awọn ọmọ Naijiria.

Eleyii yoo si tun jẹ ki oṣi ati iṣẹ pọ si, ọpọ eeyan ni iṣẹ yoo tun bọ lọwọ wọn bayii.

A fi asiko yii kepe ijọba lati da owo epo bẹntiroolu pada si iye to wa tẹlẹ tori gbogbo igba ti ijọba ti ṣe afikun owo epo sẹyin, ko si eyi to so eso rere.

Awọn araalu tun di akuṣẹẹ sii ni, ati pe o yẹ ki ijọba le ni igboya lati sọ f'araalu ibi to n gbe orilẹede yii lọ gan an,'' Ajaero lo sọ bẹẹ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

NNPCL fi owó kún lítà epo bẹtiróòlù

NNPCL

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ẹka ileepo kan to jẹ ti ajọ NNPCL ti ṣe atunsẹ si iye ti wọn n ta lita epo bẹtiroolu.

Ko so o di ọsan Ọjọru, 897 Naira ni NNPCL n ta epo, bẹrẹ lati igba to bẹrẹ si ni ra epo ni ileeṣẹ epo Dangote.

Akiyesi akọroyin BBC ni awọn ẹka ileepo naa fihan pe NNPCL ti n ta lita epo bẹtiroolu kan ni 998 Naira no awọn ibi kan bayii.

NNPCL funra rẹ ko tii sọ ohunkohun lori afikun owo epo, ṣugbọn igba keji niyii ti wọn fi owo kun iye ti wọn n ta lita kan laarin oṣu meji.

Ti ẹ o ba gbagbe, loṣu Kẹsan an to kọja ni NNPC fi atẹjade kan sita ninu eyi to ti kede iye ti araalu yoo maa ra lita epo bẹntiroolu kan kaakiri orilẹede Naijiria.

Atẹjade naa fihan pe awọn eeyan yoo maa ra epo ni N950 lawọn ipinlẹ kan, nigba ti awọn mii yoo maa ri ra ni N1,200.

Amọ, lẹyin oṣu kan si ikede yii ni alekun mii tun ti ba owo epo bẹntiroolu bayii.

Iye ti NNPC kede pe araalu yoo maa ra epo bẹntiroolu loṣu Kẹsan an to kọja

  • Ipinlẹ Eko - N950. 22
  • Ipinlẹ Oyo - N960.22
  • Ipinlẹ Imo - N980.22
  • Ipinlẹ Rivers - N980.22
  • Abuja - N992.22
  • Ipinlẹ Kaduna - N999.22
  • Ipinlẹ Kano - N999.22
  • Ipinlẹ Sokoto - N999.22
  • Ipinlẹ Borno - N1,019.22