Ṣé yánpo-yánrin mìí tún ń rúgbó bọ̀ l'ágboolé Fuji ni?

Wasiu Alabi/Taye Currency

Oríṣun àwòrán, Wasiu Alabi/Taye Currency

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Lati bi ọsẹ kan sẹyin ni awuyewuye ti bẹrẹ ni agboole Fuji, paapaa laarin awọn ololufẹ orin naa.

Eyi waye lẹyin ti gbajumọ olorin to fi ilu Ibadan ṣe ibugbe, Taye Akande Adebisi, ti ọpọ mọ si Taye Currency kọ orin kan, nibi to ti sọ pe ko si olorin Fuji ti ko kọkọ kọrin bi ẹlomii, ko to o di ilumọọka.

Ode ariya kan ni Currency ti sọ ọrọ naa, ti fidio rẹ si da ariyanjiyan silẹ lori ayelujara.

Lara awọn olorin to darukọ ni Pasuma to ni o ṣe awokọṣe agba olorin mii, Alhaji Abass Akande Obesre.

Bakan naa lo tun darukọ Sefiu Alao, to ni o sin Shina Akanni jẹ.

Awọn nnkan yii lo sọ, ni awọn ololufẹ awọn to darukọ ba gba a bi ẹni gba igba ọti, ti wọn si n sọ pe ko tọ si Currency lẹnu lati sọ bẹẹ.

Koda, Sefiu Alao ‘Baba Oko’ sọ ọrọ sita pe, Currency ko mọ ohun to n sọ ni.

Ṣugbọn Taye Currency tun daa lohun pe, oun mọ nnkan ti oun n sọ, ti oun ko si le ko ọrọ oun jẹ botilẹ jẹ pe lati aye alalumọlẹ ni oun ati Paso ti jọ wa, to si wa lara awọn ti oun ma n pọnle.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹlomii naa lagboole Fuji, Tiri Leather, naa binu lori ọrọ yii pe ko tọ si Currency lati maa sọ iru ọrọ bẹẹ.

Awọn ọrọ ti Currency n sọ yii ni ko gba ibi to dara lara awọn ololufẹ Paso, ti ọpọ wọn si n sọ pe igberaga lo n ṣe akọrin naa.

Awọn kan ti ẹ ti wu fidio orin kan jade, nibi ti Wasiu Alabi Pasuma ti bẹ awọn ololufẹ rẹ ni ode orin kan ti wọn jọ lọ pe, ki wọn o gba ti Currency naa bi wọn ṣe gba ti oun naa.

Ninu fidio naa ni Paso ti n ṣe adura fun Taye Currency pe oun naa yoo kọrin de ilu oyinbo bii t’oun naa.

“Tinu-tinu mi ni mo fi gbadra fun ọ.”

Awọn kan ti ẹ sọ pe awọn yoo fi oju rẹ ri nnkan nigbakugba to ba wa a kọrin niluu Eko.

Koda, awọn kan pe Taye Currency ni ọdalẹ si Pasuma nitori pe ipa kekere kọ lo ko ninu idagbasoke rẹ.

Yoruba ni, ibi ti sọrọsọrọ wa, naa ni awọn to mọ ọrọ ọ gbọ wa.

Nigba ti yoo fi di ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹwaa, Taye Currency tun ṣe fidio miran sita lori iṣẹlẹ ọhun.

Ninu fidio tuntun naa lo ti sọ pe wọn ṣi oun gbọ ni.

“Eeyan ma n sọ nnkan mi to jẹ pe ọt ni ibi ti awn eeyan ma n gbe e lọ.”

Ọdun diẹ sẹyin lati bii ọdun 2000 si 2010 ni ija agba da wahala silẹ laarin awọn ilumọọka olorin Fuji, Wasiu Alabi Pasuma ati Saheed Osupa.

Ni asiko naa, niṣe ni awọn ololufẹ wọn ma n fi oko ọrọ ati ija gbangba gbeja ẹni to jẹ ti wọn.

Bẹẹ ni awọn akọrin naa ma n fi orin bu ara wọn nigba naa.

Ọrọ naa kan Wasiu Ayinde K1 nigba naa, ti ariyanjiyan si n waye lori ẹni to da Fuji silẹ ni pato.

Lẹyin ti ija naa ti waye fun ọpọ ọdun, ki awọn agbaagba to ba wọn pari rẹ.

Taa gan an lo da orin Fuji silẹ?

Ọpọ awuyewuye lo ti wa lori ẹni ti o bẹrẹ orin Fuji ni Naijira laarin oloogbe Sikiru Ayinde barrister ati Alhaji Kollington, Kebe n Kwara.

Ni ọdun 2020, BBC ba agba ọjẹ nidi iṣẹ orin Fuji kikọ, Alhaji Kollington Ayinla, to jẹ ọkan lara awọn to bẹrẹ osin Fuji ni kikọ sọrọ.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo naa lo ti sọ pe oloogbe Ayinde Barrister lo da ere Fuji silẹ nigba ti oun tẹ le e ninu iṣẹ orin Fuji.

Skip Facebook post
Allow Facebook content?

This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Facebook post

Ta a ni Taye Currency?

Taye Currency

Oríṣun àwòrán, Taye Currency

Abdulrasheed Tayelolu Akande Adebisi ni wọn bi lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kejila ọdun 1974.

Baba rẹ ni oloogbe Ganiu Amao Adebisi, nigba ti iya rẹ n jẹ Alhaja Mojisola Aduke Adebisi.

Ilu Ibadan ni wọn ti bi Taye to pada waa di gbajugbaja olorin Fuji, ni agboole Oyewole, agbegbe Foko.

Currency lọ sile ẹkọ alakọọbẹrẹ ati ti girama, nibi to ti ṣe awari ẹbu orin to ni.

Eyi naa lo si jẹ ko bẹrẹ si i gberin lẹyin ẹgbọn rẹ, Sulaimon Akanmu Ademola, nigba ti Currency ko ti i ju ọmọ ọdun mọkanla lọ.

Taye ti wọn tun n pe ni Baba ọnarebu, gberin lẹyin olorin mẹrin ọtọọtọ, nigba to kọja si Ijẹbu-Ode nipinlẹ Ogun.

Ọmọ ọdun mẹtadinlogun (17) lo wa nigba to da ẹgbẹ orin tiẹ silẹ pẹlu iranlọwọ Kehinde rẹ, ati Idowu, ati maneja rẹ ti i ṣe oloogbe Rahmon Akilapa.

Igba ti Currency di ẹni ọdun mọkandinlogun (19) lo pade Alhaji Wasiu Alabi Pasuma, ẹni to ran an lọwọ ninu ilakaka rẹ lagboole orin.

Díẹ̀ nípa Alabi Pasuma

Wasiu Alabi Pasuma

Oríṣun àwòrán, Other

Wasiu Alabi Odetola gan-an ni orukọ oṣere tawọn eeyan mọ si Pasuma tabi Baa Waasi yii.

Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kọkanla ọdun 1967 ni wọn bi Pasuma tawọn eeyan tun mọ si Gaosu Fuji.

Musin, nipinlẹ Eko ni wọn bi i si, ṣugbọn ọmọ ilu Oro, nipinlẹ Kwara ni.

Ọmọde ara ni Pasuma fi bẹrẹ Fuji nigboro Musin, ṣugbọn awo orin rẹ, Recgonition’ to ṣe ni 1993 lo sọ ọ di ilu mọ ọ ka titi di oni.

Ẹlẹyinju aanu ni awọn eeyan mọ Ijaya Fuji si, awo orin to ti gbe jade si ti ju ọgbọn (30) lọ.