Ipa wo ni bí NNPCL ṣe yọwọ́ gẹ́gẹ́ bí alárinà kárà-kátà epo yóò ní lára rẹ?

Ajo NNPCL ti kede sita pe oun ti yọwọ kuro ninu ileeṣẹ ifọpo Dangote lori epo tita.
nikan nileeṣẹ NNPCL fidi rẹ mulẹ fun BBC pe, ileeṣẹ naa ti yọwọ gẹgẹ bii alarina laarin awọn alagbata epo ati Dangote lẹyin ipade kan to waye ninu oṣu Kẹjọ nibi ti wọn ti tọwọ bọ iwe adehun.
Adehun naa lo ni NNPCL yoo tẹsiwaju lati ma ra epo lọwọ Dangote, ti awọn ileeṣe yooku naa yoo si le ra lai ni idasi NNPCL ninu.
Awọn onimọ nipa eporọbi sọ pe wọn gbe igbesẹ yii lati ma jẹ ki iye owo epo ma le yatọ si ara wọn, eyi to n ba ọpọ lẹru.
Ninu oṣu Kẹsan an, NNPCL fi owo kun lita epo lati N617 si N897 saaju ki wọn to bẹrẹ si ni ma ra epo lati ọwọ Dangote.
Aarẹ Naijiria, Bola Tinubu se atilẹyin fun igbesẹ naa pe o se koko botilẹ jẹ pe o ni igbesẹ naa ti fa ọwọngogo lorilẹede Naijiria.
Awọn alaye kan fihan pe NNPCL ti sọ fun ijọba apapọ pe wọn ko ni anfaani lati maa san owo iranwọ lori epo mọ fun idẹrun araalu.

Oríṣun àwòrán, NNPCL
Se igbesẹ yii le fa ọwọngogo epo?
Ọkan ninu nnkan to n ba ọpọ ọmọ Naijiria lẹru bayii ni ọwọngogo epo nitori kete ti epo bẹntiroolu ba ti lọ soke ni gbogbo nnkan mii yo lọ soke.
Awọn onimọ lori ọrọ epo ṣalaye pe ijọba Bola Tinubu n sa gbogbo agbara rẹ lati jina si sisan owo iranwọ 'subsidy' lori epo bẹtiroolu.
“Ijọba ti ri pe NNPCL n tẹsiwaju lati jẹ alarina laaarin awọn alagbata epo ati ileeṣẹ ifọpo Dangote, ti wọn si n se atilẹyin ” Yabagi Sani - onimọ nipa epo rọbi ṣalaye.
O fikun pe igbesẹ yii ko ni fa ọwọgogo epo sugbọn gbogbo nnkan ni yoo gbe owo lori.
“Owo epo bẹtiroolu yoo lọ soke, ti awọn nnkan mii bi ounjẹ yoo tubọ gbe owo sori, eyi to n se akoba fun awọn araalu.
Gẹgẹ bii o ṣe ṣalaye, o ni Dangote ni lati ta epo yii nitori wọn ni lati jere. Ni kukuru, ti epo ba wọn lagbaye, Dangote naa ma fowo kun owo epo rẹ.
Ṣe tita eporọbi ni Naira le se anfaani?
Ni opin oṣu Keje, Aarẹ Bola Tinubu paṣẹ pe ti karakata laarin NNPCL ati awọn ileeṣẹ ifọpo maa waye pẹlu owo Naira fun rira ọja, bẹrẹ pẹlu Dangote.
Ninu atẹjade kan ti Bayo Onanuga, agbẹnusọ Aarẹ fi sita fun awọn akọroyin, o ni Dangote nilo ọkọ oju omi mẹẹdogun ti owo rẹ to biliọnu mẹtala lọdọọdun sugbọn NNPCL yoo fun wọn ni mẹrin.
O fikun pe karakata yoo maa waye pẹlu owo Naira dipo owo Dọla.
Yabagi Saani ni ti ẹyi ba tẹsiwaju, dandan ni ko mu adikun ba iye owo epo fun tita.















