Kí ló ṣokùnfà ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi méjì tó gbẹ̀mí èèyàn 21 lójú agbami l’Eko?

Ọkọ oju omi kan ri

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ko din ni eeyan mọkanlelogun ti o ti ri sinu omi nigba ti ọkọ oju omi meji kọlu ara wọn loju agbami lọjọ Aje ni ilu Imore to wa lagbegbe ijọba ibilẹ ni ipinlẹ Eko.

Ọkọ oju omi meji ti ọkọọkan wọn ko ero mẹrindinlogun forigbari, wọn si ri sinu agbami.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Iṣẹgun pe nnkan bii agogo meje alẹ ni wọn fi iroyin ijamba ọkọ oju omi naa lọ lagọ ọlọpaa Ilashe.

Gẹgẹbi o ṣe sọ, awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi titi kan awọn ọlọpaa ori omi atawọn omuwẹ ni wọn sare si ibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹ ti wọn si doola ẹmi eeyan mọkanla.

O fi kun un pe wọn ti ko awọn ti wọn fara ṣeṣe ninu iṣẹlẹ ijamba naa lọ si ileewosan awọn ọmọogun oju omi to wa ni Navy town Alakija fun itọju.

Nibayii, ko tii si ẹni le sọ ibi ti awọn ero ọkọ oju omi mejeeji to ku yii wa bayii, amọṣa alukoro ileeṣẹ ọlọpaa naa ni akitiyan ṣi n lọ lati ṣe awari oku awọn to ri sinu omi naa.

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe iwadii ti bẹrẹ lori ohun to ṣe okunfa ijamba ọkọ oju omi naa.