Ta ló ṣekú pa apẹja, ju òku rẹ̀ s’ódò nípìnlẹ́ Ogun?

Aworan odo

Oríṣun àwòrán, Getty

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọkunrin kan to yan iṣẹ ẹja pipa laayo, Segun Sikiru, ni o ti di oloogbe bayii ti wọn si ju oku rẹ sodo n’Iwopin, ilu kan to wa nijọba ibilẹ Ijebu-Ode, ipinlẹ Ogun.

Ohun ti Alukoro ọlọpaa Ogun, Omolola Odutola, sọ nipa iṣẹlẹ naa ni pe awọn eeyan marun-un kan ni wọn fi igi ọparun lu Segun, wọn si ju oku rẹ somi lẹyin eyi.

Orukọ awọn afurasi naa ree gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa Ogun ṣe fi sita: Saheed Mureni, Afeez Mureni, Saheed Taidi, Thompson Samuel, ati Ogoji Olorunwa.

Gbogbo wọn ni ọwọ ọlọpaa ti ba bi Alukoro ṣe wi, wọn si ti wa ni igbekun awọn ọlọpaa Abigi.

Báwo ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe ṣẹlẹ̀ gan-an?

Odutọla ninu alaye rẹ, sọ pe oloogbe ati awọn ọmọ rẹ ọkunrin meji lọ sodo lati wo o boya àwọ̀n ti wọn dẹ sodo ti pa ẹja.

O ni bi wọn ṣe debẹ ni wọn ba awọn afurasi marun-un yii ti wọn n gbiyanju lati tu ẹja ti àwọ̀n naa mu lọ .

Eyi ni Oloogbe Segun ri to si pariwo le awọn afurasi ọhun lori.

‘’Nigba ti oloogbe ri i wọn nibi àwọ̀n ẹja rẹ, o gbiyanju lati pariwo le wọn lori, kawon eeyan to wa lagbegbe naa le mọ ohun to n ṣẹlẹ.

‘’Ṣugbọn wọn ni awọn afurasi naa ya bo o, wọn si fi igi ọparun gba a láya.

Nigba ti wọn ri i pe ko mọ ibi to wa mọ ni wọn ju oku rẹ sinu agbami. ‘’

Odutọla lo ṣalaye bẹẹ.

Ṣaa, wọn ti ri oku naa yọ kuro ninu omi, awọn afurasi si ti wa ni ahamọ, bẹẹ ni iwiadii n tẹ siwaju bawọn ọlọpaa ṣe wi.